Ọ̀dọ́mọdé olórin, Habeeb Òkìkíolá, tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Portable fi àwòrán kan s’íta lórí ayélujára ní inú ọ̀sẹ̀ tí ó kọjá yí pé òun bá Ọ̀gbẹ́ni Dàpọ̀ Abíọ́dún s’ọ̀rọ̀ nípa bí gbogbo ọ̀nà ṣe ti di kòtò ikú yíká orígunmẹ́rin Ìpínlẹ̀ Ògùn.
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on XKò jọ wá lójú bí wọ́n ṣe ń ná owó ìjọba ní ìnákúna. Ṣé million méjì tí Portable sọ pé o gbé fún òun, ṣé kò ní ohun tí o le fi ṣe fún ará ìlú tí ebi ń pa, àbí ṣé Portable ni ebi ń pa ni? ohun tí ẹ máa ń ṣe náà ni kí ẹ máa fi síbí gbọ́n omi sí’nú òkun.
Ìgbà tí Dàpọ̀ Abíọ́dún ti ń lo ọdún kẹfà lọ, tí gbogbo àwọn ará ìlú ń pariwo pe gbogbo ọ̀nà ni kò dára, ìjọba yín kò lè ṣ’àánú ará ìlú láti máa ṣe àwọn ọ̀nà ìlú díẹ̀ díẹ̀, títí tí gbogbo ọ̀nà kò fi ṣeé rìn mọ́ yíká Ìpínlẹ̀ Ògùn.
Dàpọ̀ Abíọ́dún, ibo ni ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ wa? tí o wá ń tọrọ pé kí àwọn ará ìlú ṣe sùúrù fún yín, di ìgbà wo? o tún sọ ọ́ síwájú pé, ọdún mẹ́jọ le má tó láti fi ṣe ọ̀nà, ó ga! ṣe ìwọ lo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìṣe ìjọba ọdún mẹ́rin oní ipele mẹ́ta ni?, ó lè ṣe é ṣe sá tí o bá ti kọjá sí orílẹ̀ one Nàìjíríà yín, ibẹ̀ ni àyè ti gba gbogbo ìwà pálapàla yín.
Àwa I.Y.P. ń kilọ̀ fún yín pé ohun gbogbo tí kìí ṣe tiyín, tí ẹ ti jí kó lọ, ni ẹ máa pọ̀ nígbà tí ẹ bá ti dìde lórí àga wa ni Sekiriteriati ti àwa ọmọ Olómìnira D.R.Y., ki àwa I.Y.P le gbé olórí Adelé àti àwọn adelé yókù wọ’lé láti le bẹ̀rẹ̀ gbogbo ètò tí wọ́n ti pèsè sí’lẹ̀ láti oṣù kẹrin ọdún yìí , fun ìgb’áyé ìgbádùn àwa I.Y.P lórí ilẹ̀ D.R.Y. Lẹ́yìn Olódùmarè, Yorùbá ni àkọ́kọ́.