Nínú fọ́nrán kan lórí ayélujára la ri àwọn àgbẹ̀ kan tó ńfi ojú ọgbẹ́ ibití Fúlàní daran-daran tí ṣá wọn hàn, ní ìpínlẹ̀ Ògùn tí agbèsùnmọ̀mí naijiria ń lo Dàpọ̀ Abíọ́dún lati jẹ gàba ni Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y).
Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà, ọ̀kan lára àwọn arúfin tó ń pe ara rẹ̀ ní agbófinró agbésùnmọ̀mí nàìjíríà wà níbẹ̀ láti dá sí ọ̀rọ̀ náà, irú ọ̀rọ̀ wo ni irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ fẹ́ sọ, nígbà tí òun fúnra rẹ̀ gan-an jẹ́ arúfin.
Ìwà ìjẹgàba ni kí ọlọ́pàá ìlú agbèsùnmọ̀mí nàìjíríà ṣì wà lórí ilẹ̀ wa, nítorí láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wá-ọdún-óléméjìlélógún ní a ti kúrò lábẹ́ nàìjíríà, tí a sì ti búra wọlé fún bàbá wa Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́ gẹ́gẹ́bíi olórí ìjọba Adelé wa ni ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún, a ti di orílẹ̀ èdè aṣèjọba ara ẹni.
Àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá mọ̀ dájú pé ọlọ́pàá agbésùnmọ̀mí àti Fúlàní daran-daran jẹ́ irin íṣẹ́ ikú lọ́wọ́ apaniṣayọ̀ naìjíría fún ìgbésúmọ̀mí àti ìjẹgàba lórí ilẹ̀ wa.
Ká ní àwa ọmọ Aládé tí jáde síta láti lọ pàdé màmá wá àti àwọn Adelé wa ní ìpínlẹ̀ Ìbàdàn, láàárin ọ̀jọ́ kẹtàlá sí ìkẹrìndínnlógún oṣù Igbe ni, inú ìgbádùn ní à bá wà báyìí, ṣùgbọ́n a dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè pé Ó gba ọ̀nà míràn yọ sí wọn, a sì ti borí ìlú agbésùnmọ̀mí nàìjíríà.