Ọkùnrin kan ọmọ orílẹ̀ èdè Gambia tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ousman Touray sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ilé iṣẹ́ ìgbóhùns’áfẹ́fẹ́ tó gbajúmọ̀ tó jẹ́ ti àwọn òyìnbó amúnisìn ṣe máa ń ṣe àfihàn ohun aburú nípa ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú. 

Ó ṣàlàyé pé, wọn a máa ṣe àfihàn àwọn orílẹ̀ èdè aláwọ̀ dúdú bí pé kò tilẹ̀ sí ìdàgbàsókè kankan níbẹ̀ àti bí orílẹ̀ èdè tí ìṣẹ́ àti ìyà ń bá fínra gidi. 

A gbọ́dọ̀ fi òpin sí eléyìí nítorí pé, tí gbogbo àgbáyé bá ń rí ilẹ̀ Áfríkà bí ilẹ̀ tí kò ní ìlọsíwájú kánkán kò ní jẹ́ kí àwọn olùdókòwò wọlé.

Àwa aláwọ̀ dúdú gbọ́dọ̀ ṣe àfihàn ohun rere nípa ilẹ̀ wa. Tí a bá sì ń sọ nípa olùdókòwò, kìí ṣe láti ilẹ̀ òkèèrè ṣùgbọ́n láàárín orílẹ̀ èdè aláwọ̀ dúdú ni. 

Ọkùnrin náà tẹ̀síwájú wípé, gbogbo ìgbà ni òun máa ń sọ pé ilẹ̀ Áfríkà ni ibùdó ìdókòwò ní ọjọ́ ọ̀la, ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ ṣíwájú nínú ìdókòwò náà kí àṣeyọrí wa lè ṣe okùnfà ìdókòwò ní gbogbo àgbáyé. 

Ó tún wa tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, ó tó àkókò fún àwa Áfríkà náà láti ní ojúlówó ilé iṣẹ́ ìgbóhùns’áfẹ́fẹ́ tiwa kí a lè máa gbé ìròyìn tí yóò máa sọ rere nípa orílẹ̀ èdè aláwọ̀ dúdú yàtọ̀ sí èyí tí àwọn amúnisìn wọ̀nyí ńṣe.

Lára àwọn ọ̀rọ̀ pataki tí màmá wa Olóyè Ìyá Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítírí-Abíọ́lá ń sọ fún àwa ọmọ Aládé ló tún jẹ jáde yíì, nípa bí àwọn òyìnbó amúnisìn ṣe kó irọ́ jọ, tí wọ́n pèé ní ìtàn àwa aláwọ̀ dúdú, kí wọ́n lè tẹ̀síwájú láti máa mú wa sìn.

Nítorínáà màmá wa ti sọ pé àwa ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) tí Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R Y) níláti tún ìtàn ara wa kọ ní ọ̀nà tó jẹ́ òtítọ́ àti òdodo láti ṣe àfihàn ẹwà àti ogo tí Olódùmarè fún wa àti ohun rere gbogbo tí O fi ṣìkẹ́ ilẹ̀ wa.

Òmìnira wa tí Olódùmarè lo màmá wa MOA láti ṣe aṣepé rẹ̀ jẹ́ àǹfààní láti lè ṣe àtúnṣe irọ́ àti ẹ̀tànjẹ àwọn amúnisìn wọ̀nyí.

Fún ìdí èyí, ká dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè, kí á sì mọ rírì màmá wa Olóyè Ìyá Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítìírí-Abíọ́lá fún iṣẹ́ òmìnira tí Olódùmarè gbé lé wọn lọ́wọ́, kí a sì fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Adelé wa kí ògo wa lè tètè búyọ.

Ominira yoruba daily news | the newest nation in the world 2024