Àwọn ìlú olómìnira Burkina Faso, Niger àti Mali kọ̀ láti padà sí inú àjọ ECOWAS tó nṣojú fún àwọn òyìnbó amúnisìn.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ sì nrawọ́ sí wọn láti padà sínú oko-ẹrú, ṣùgbọ́n, àwọn ìlú mẹ́tẹ̀ta yìí sọ wípé ibití àwọn bá ti ṣe ó dàárọ̀, àwọn kìí tún kí wọn káalẹ́ níbẹ̀.
Ṣèbí ní oṣù Ṣẹ́rẹ́, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rìnlélógún tí a wà nínú rẹ̀ yí ni àwọn ìlú mẹ́ta yí yọ ara wọn kúrò nínú àjọ ECOWAS nígbàtí ìṣesí àjọ náà tako ìṣerere ìlú wọn.
Irú òmìnira wo ni àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà nínú ECOWAS yí wá ní, nígbàtí wọ́n jẹ́ irinṣẹ́ ìhàlẹ̀ fún àwọn apanimáyọ̀dà òyìnbó amúnisìn, èyí tí ìlú agbésùnmọ̀mí nàìjíríà jẹ́ ọ̀kan lára wọn, tí wọ́n sì njẹgàba lórí ilẹ̀ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), ṣùgbọ́n Olódùmarè ti ṣẹ́gun fún wa.
Ìjọba ajẹgàba nàìjíríà, kúrò lórí ilẹ̀ wa. Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) kìí ṣe ilẹ̀ rẹ. D.R.Y ti di orílẹ̀ èdè aṣèjọba-ara-ẹni láti ọjọ́ kéjìlá oṣù Igbe ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rìnlélógún, lẹ́yìn tí a ti kọ́kọ́ kéde òmìnira wa ní ogúnjọ́ oṣù Bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún.
Àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) kò ní fààyè gba ìlúkìlú láti jẹgàba lórí ilẹ̀ wa.
Ìjọba wa ti wà lórí aléfà, lábẹ́ àkóso Olórí Ìjọba Adelé, Bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́.
Aríremáṣe nàìjíríà, kúrò lórí ilẹ̀ wa. Ìjẹgàba rẹ ni ó ṣe okùnfà ìdààmú àtí àwọn ìpèníjà tí ó ń dojúkọ ọmọ Yorùbá lórí ilẹ̀ wa.
Ṣèyí Mákindé, Sanwó-Olú, Adélékè, Dàpọ̀ Abíọ́dún, Abdulrahman Abdulrazaq, Ododo, Oyèbánjí, Ayédatiwa, ẹ ti fi ara yín hàn gégébí ọ̀tá ìran Yorùbá nígbàtí ẹ ti yọ̀nda láti jẹ́ irin iṣẹ́ fún agbésùnmọ̀mí nàìjíríà tó njẹgàba lórí ilẹ̀ wa, ẹ ṣì ma fojú ba ilé ẹjọ́ àgbáyé.
Ẹ kúrò nínú àwọn oríkò ilé iṣẹ́ ìjọba wa gbogbo ní ilẹ̀ olómìnira Yorùbá D.R.Y.