Ọjọ́ tí pẹ́ tí àwọn amúnisìn tí ń huwà búrúkú sì àwa ọmọ aládé. Ọpẹlọpẹ màmá wá Ìyá Ààfin Modupẹ́ọla Onitiri-Abiọ́la tó tú aṣọ kúrò lójú égún.
Wọn ní tí ọmọde ò bá bá ìtàn, a bá àrọ̀bá. Èyí ló bí gbogbo ìtàn pàtàkì tí màmá wa MOA nsọ fún àwa ọmọ aládé. A sì gbọ́dọ̀ mọ̀ kí à lè kọ́ ọgbọ́n nínú rẹ̀ láti mú lò fún ìdúró ṣinṣin ìjọba orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantitwa tí Yorùbá (D.R.Y).
Màmá MOA tí tú àṣírí bí àwọn amúnisìn ṣe ṣe ìpìlẹ̀ àgbékalẹ̀ ètò ikóni lẹ́rú, ìjanilólè àti ìjẹgaba láti ọdún gbọọrọ sẹ́yìn (òjìlé-lẹ́gbẹ̀sán-ọdún, ó-dín-márun), tí wọ́n sì gùn lórí rẹ̀ títí di àsìkò yìí. Ìpinnu wọn ni pé a máa ṣe ẹrú kú ni lójú tiwọn. Òun ló jẹ́ kí wọn da àwọn ènìyàn tiwa lórí rú, tí àwọn yẹn fi pàdí àpò pọ̀ pẹ̀lú amúnisìn láti máa kó ìnilára bá ara ìlú.
Ṣùgbọ́n Olódùmarè tó sẹ̀da àwa ọmọ aládé kò gbà fún wọn. Òun ló fi gbé olùgbàlà dìde fún wá ní déédéé ìgbà yìí àti ní déédéé àsìkò yìí. Ọlọ́run ti ṣẹ́gun fún wa, ati bọ́ lọ́wọ́ amúnisìn àti ariremáṣe Nàìjíríà, láti ogúnjọ oṣù Bélú, ẹgbàá ọdún, ó lè méjìlélógún tí a ṣe ìkéde Òmìnira orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantitwa tí Yorùbá (D.R.Y). Ìṣe ìjọba ara ẹni sì ti bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí a ti ṣe ìbúra-wọlé fún Olórí-Ìjọba-Adelé, bàbá wá Mobọlaji Ọlawale Akinọ́la Ọmọkọrẹ ni ọjọ́ kejìlá oṣù igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rìnlélógún.
Àwọn ọ̀nà alumọ̀kọ́rọ́yi tí wọn fi ṣe iṣẹ́ búrúkú wọn pọ tí a kò lè sọ tán. Ẹ ja ká wó mẹta nínú wọn tó ṣe gbòógì.
* Wọn jẹgaba lórí ìṣè ijọba ara ẹni tí a ní tẹ́lẹ̀ kí àwọn amúnisìn ó tó dé. Wọn kó àwọn ẹ̀yán tiwọn sí ipò adari ìlú káàkiri. Ọ̀bàyèjẹ́ ni àwọn amúnisìn.
Wọn rọ àwọn ọba lóyè, wọ́n gba ipò àṣẹ lọ́wọ́ wọn, lati má ṣe ìdájọ́ òdodo fún ara ìlú, wọn gba àṣẹ tí wọn ní lórí ilẹ̀. Àwọn ọba wá di kòròfo lásán, àgbá òfìfo tó ń dún woroworo. Wọ́n sọ wọn di irinsẹ aninilára fún àwọn amúnisìn. ljọba ìbílẹ̀ ló wà ń pàṣẹ fún wọn bayìí.
* Wọn fi àwọn tó pera wọn ní ọmọwe rọ́pò àwọn ọba, wọn fi wọn joyè àwòdì tí kò lè è gbé ẹdiyẹ, ọ̀jọ̀gbọ́n irọ̀, dókítà tí kò ní àròjìnlẹ̀, olùmẹ̀rọ tí kò lè é rọ ẹ̀rọ tó wù lo, àti bẹẹ bẹẹ lọ. Pali lásán ni wọn gbé dání lai mọ bí wọn ṣe lè tú ìlú ṣe fún ìgbádùn ìran wọn.
Àwọn wọ̀nyí wá di irinsẹ amúnisìn t’ori ẹ̀mí búburú tó ti kó wọnú wọn. Ọdàlẹ ni wọn láwùjọ ìran Yorùbá, kò sì ìfẹ́ ọmọ ẹnì kejì nínú wọn mọ́, afi tí ara wọn nìkan. Ó má ṣe o. Wọn padà di omugọ̀ kalẹ nítorí ikùn wọn nikan.
Ṣùgbọ́n bí irọ́ bá lọ lógún ọdún, ọjọ́ kan ni òtítọ́ a bá. Àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) ti mọ òtítọ́ bayìí, a sì ti gba orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantitwa tí Yorùbá (D.R.Y.) wa padà pẹ̀lú ìran lọ́wọ́ Olódùmarè àti màmá irọrun lóbade, Ìyà Ààfin Modupẹ́ọla Onitiri-Abiọ́la.
Ọpẹ ní kí a máa dá fún Ọlọ́run tó ṣàánú fún wá, tó kó wa kúrò ní oko ẹrú àwọn amúnisìn àti agbesunmọ̀mi Nàìjíríà.
Ọ̀kẹ́rẹ́ gungi irokò ojú ọdẹ dá. Democratic Republic of the Yorùbá ti dúró títí láéláé. Màmá wa MOA àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) ń dúpẹ́ fún iṣẹ́ ribiribi tí ẹ ṣe fún wa.