Ìran mi kò ní parun láéláé!” Gbólóhùn yí jẹ́ ọ̀kan gbòógi nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí màmá wa, MOA, ma ń tẹnu mọ́.

Ìdí pàtàkì tí Màmá, Ìyá Ààfin Modúpẹ́ọla Onitiri-Abiọ́la ṣe ń tẹnu mọ ọ̀rọ̀ yi ni, bí àwọn amunisìn ṣe ń hùwà burúkú láti pá àwa ọmọ aládé run kí wọn ba a lè gbà ilẹ̀ wá mọ́ wá lọ́wọ́. Ìwà búburú yí ni wọn ti bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ láti ìgbà ayé àwọn babanla wá. Èdùmàrè ló jogún ilẹ̀ wa fún wá láti ìgbà ìwáṣẹ̀.

Wọn pèrò, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí mu sí ojú ìṣe, láti gbá gbogbo ohun tí a fi ń ṣe ọlá, ọlà, àti ògo. Nítorí pé wọn bá wa gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè, tó lajú jùlọ tó sì gbajú gbajà ni Áfíríkà nígbà náà. Wọn kò rí atọrọjẹ́ kankan, bẹni wọn kò rí olè laarin wá.

Èyí jẹ́ òtítọ́ tí ìkan nínú àwọn amúnisìn sọ fún àwọn tó ran nisẹ. Lẹ́yìn ìgbà ti wọn gbọ́ ìròyìn yí ni àwọn ènìyàn burúkú wọnyi dé pẹ̀lú ọ̀nà arékérékè wọn láti bá wa dòwò pọ. Láì mọ̀ wípé aṣekúpàni ẹ́dà ní wọn.

Wọn bẹ̀rẹ̀ ìwà àgàbàgebè àti kópa nínú ìṣe ìjọba, wọ́n kọ́ ilé ìwé, lai mọ̀ wípé wọn fẹ́ gba èdè àti àṣà wa ni, wọ́n sì ki ọwọ́ bọ àwọn ọrọ̀ajé wá pẹlu ojúkòkòrò àti wọbia, wọn si n jí nkan ọnà wá. Àwọn ètò ìlera ni wọn ti’wọ bọ̀ pẹlu èrò ibi, láti pawa rún, nípa abẹ́rẹ́ àjẹsára. Bẹẹ ni wọn ṣe kú pani pẹlu ògùn tí wọn fi sí àwọn irúgbìn ìgbà lóde. Wọn gbé àwọn òṣèlú kalẹ láti má a ṣe aṣojú fún wọn kí wọn le máa ṣe ìnilára fún àwọn ará ilu. 

Ṣùgbọ́n a dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tó fi àánú rẹ hàn sí wá, tó gbé màmá wa Ìyá Ààfin Modúpẹ́ọla Onitiri-Abiọ́la dídé ni déédéé ìgbà yìí àti ní déédéé àsìkò yìí fún ìgbàlà àwa ọmọ aládé. Màmá dúró gbọn-in gbọn-in lórí ẹsẹ wọn mejeji wípé láyé, ojú kò gbudọ rí ibi lẹ́ẹ̀kẹ́ta. Ìran àwọn kò ní parun. Ó di èèwọ̀.

Democratic Republic of the Yoruba

Òun ló jẹ́ kí wọn máa lo gbogbo ọgbọ́n, òye, ìmọ̀ tí Ọlọ́run fún wọn láti jìjà òmìnira orílẹ̀ èdè àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) tí ó sì yọrí sí rere nipa ìkéde òmìnira orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa tí Yorùbá (D.R.Y.), èyí tó wá yé ni ogúnjọ́ oṣù Bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún. A sì ṣe ìbúra-wọlé fún Ààrẹ wa, bàbá wa Mobọlaji Ọlawalé Akinọlá Ọmọkọrẹ́, ní ọjọ́ kejìlá, oṣù ìgbé, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rìnlélógún. Bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ sì ti bẹ̀rẹ̀ ni orílẹ̀ èdè wa fún ìgbádùn gbogbo àwa ọmọ aládé.

Èyí gangan ló kán ègún ẹyìn àwọn amunisìn àti ìjọba agbesunmọ̀mi Nàìjíríà, tí a ti jáde kúrò nínú rẹ̀. Wọn kò ní gbéri mọ́ láṣẹ Èdùmàrè. Ìpínyà àwa àti àwọn aríremáṣe Nàìjíríà jẹ́ láéláé. Ìbàsépọ wá tí dópin. 

Ní báyìí, màmá wa MOA tí bá wá ṣe àgbékalẹ̀ ètò tí kò níí ṣe-é wó lulẹ títí láé. Gbogbo àwa ọmọ aládé gbudọ mọ àwọn ìṣẹ takuntakun tí Màmá wá ti ṣe, kí à sì gbaruku tí àwọn Adelé ̀láti ṣe iṣẹ́ papọ, fún ìdàgbàsókè orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantitwa tí Yorùbá (D.R.Y).

Ẹ jẹ́ kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè àti Màmá, MOA, fún àṣeyọrí iṣẹ́ náà.