Ó màṣe o, àwọn ọ̀dọ́’bìnrin ní ìlú aríremáse Nàìjíríà tí di gbàǹjo tí wọ́n tún wà ń ṣe ìpolongo rẹ̀ lórí ayélujára.
Nínú fọ́nrán kan tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni a ti rí ìpolongo tí àwọn ilé iṣẹ́ kan ṣe nípa ohun tí ilé iṣẹ́ náà dá lé lórí, ǹjẹ́ kíni wọn ń ṣe o? Ètò fífi obìnrin ṣe àlejò fún àwọn arìnrìn-àjò, tàbí ọkùnrin tó bá nílò ọmọbìnrin láti fi ṣe aya. Pabanbarì rẹ̀ wá ni wípé bí wọ́n ti ń ṣe àfihàn àwọn ọ̀dọ́bìnrin náà lorísìírísìí pẹ̀lú aṣọ tí kò bo ìdodo.
Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ pe’ra yín ní olóṣèlú ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, bí ẹ ṣe sọ ayé àwọn ọmọọlọ́mọ di rádaràda yìí, bẹ́ẹ̀ náà ni ayé ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín ṣe máa rí. Àwọn ọmọ ológo tí ẹ ti fi ìwà ojúkòkòrò àti àìní’tẹ̀lọ́rùn yín ba ayé wọn jẹ́.
Èyí tó kàwé kò rí iṣẹ́, àwọn ọkùnrin wọn ti di yàhúù, ọ̀dọ́’bìnrin ọmọ ọdún mẹ́tàlá ti di olóshó, nígbà tí àwọn ọmọ tiyín lọ ń kà’wé lókè òkun.
Tí Kò bá ṣe Olódùmarè tó gba àwa ìran Yorùbá, ṣé bí à bá ṣe máa bàa lọ nìyí? Ṣùgbọ́n a dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá wa tó rán màmá wa, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla láti bá wa f’òpin sí ìyà àti òṣì yí.
Ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, jáde kúrò lórí ilẹ̀ wa, lójoojúmọ́ ni ìjẹgàba yín yìí ń ṣe ìpalára fún àwa ọmọ Yorùbá. A ti kúrò lára ìlú apanilẹ́kún jayé Nàìjíríà láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún tí a sì ti ṣe ìbúra fún olórí adelé wá bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún.
A ti ńlo ẹ̀tọ́ wa láti ṣe ìjọba wa, orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) kìí ṣe ìkan náà pẹ̀lú ìlù agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà. Olódùmarè ti gba agbára lọ́wọ́ yín, ìran Yorùbá ti di òmìnira.