Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), gbogbo ojúṣe tó yẹ kí àwọn ìjọba ṣe ni wọ́n yóò máa ṣe, tí wọ́n kò sì ní yọ ọ̀kan sílẹ̀ nítorí pé, ìjọba wa yóò nífẹ̀ẹ́ àwọn ará ìlú bẹ́ẹ̀ni wọn kò ní jẹ́ kí ìyà jẹ ẹnikẹ́ni tàbí tẹ ẹ̀tọ́ wọ́n lójú mọ́lẹ̀.

Ojúse ìjọba ni láti dáàbò bo ara ìlú, láti pèsè oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu, iṣẹ́, iná mọ̀nàmọ́ná, ètò ìwòsàn, ètò ẹ̀kọ́ tó yanranntí, omi, àti àwọn ohun am’áyédẹrùn lorísìírísìí.

Gbogbo ìwọ̀nyí ni a óò fi ojú wa rí ní orílẹ̀ èdè D.R.Y, ètò sì ti ń lọ lọ́kàn-ò-jọ̀kan, ọmọ Yorùbá kankan kò tún j’ìyà mọ́, gẹ́gẹ́ bí màmá wa, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe máa ń sọ fún wa wípé, gbogbo àwọn ọ̀dọ́ wa ni yóò rí ògo wọn lò, nítorí náà ayọ̀ ni ti wa.

ỌLỌ́RUN OLÓDÙMARÈ, ÀWÁMÁRIDÍ, NÍSIÌYÍ, BA GBOGBO OHUN-IBI JẸ́, PÁTÁPÁTÁ; GBOGBO MÁJẸ̀MÚ ÌRÁNṢẸ́-ẸNI-IBI, ÀṢÌTÁÁNÌ, GBOGBO ÌLÉRÍ, ÈTÒ, ÈTE, ÀTI ÈRÒ TÍ Ó LÒDÌ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ. NÍ AGBÁRA TÍ ỌLỌ́RUN FI NJẸ́ ÈMI-NI, KÍ ÌPARUN NÁÀ ṢẸLẸ̀ SÍ ÀWỌN Ọ̀TÁ YORÙBÁ WỌ̀NYÍ, LỌ́WỌ́LỌ́WỌ́ BÁYI

OLÓDÙMARÈ, ALÁGBÁRA, TÍ Ó NÍ IPÁ; OLÓDÙMARÈ TÍ Ó NÍ IPÁ LÓJÚ OGUN, ỌLỌ́RUN ÀWỌN ỌMỌ-OGUN, ṢE ÌPARUN PÁTÁPÁTÁ, NÍSIÌYÍ, FÚN ÀṢẸ, AGBÁRA ÀTI IPÒ TÍ WỌ́N NLÒ LÁTI JẸGÀBA LÓRÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ.

ṢE ÌPARUN FÚN GBOGBO ÌWÀ ÌDÚKOKÒ, ÌJẸGÀBA, DÍDẸ́RÙBANI, ÌHÀLẸ̀, ÌGBÓGUN-TINI, TÍ WỌ́N DOJÚKỌ ỌMỌ-ÌBÍLẸ̀-YORÙBÁ, TI ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ