Tani ó wó àgọ́ ọlọ́pàá tó wà ní Fálọmọ ní ìlú Èkó? Àwa ojúlówó Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) fẹ́ mọ̀ ẹni tí ó wo àti ìdí tí wọ́n fi gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ìdí ni pé ìpínlẹ̀ Èkó ni Fálọmọ wà, D.R.Y ló sì ni Ìpínlẹ̀ Èkó. Nítorí náà, ṣé ajẹgàba agbésùnmọ̀mí nàìjíríà tí wọ́n fi ipá dúró sórí ilẹ̀ wa, D.R.Y, ni wọ́n wà ní’dí wíwó tí wọ́n wó àgọ́ ọlọ́pàá yí ni? Àgọ́-ọlọ́pàá ní Orílẹ̀-Èdè D.R.Y ni ẹ wó yí.

Ṣé ẹ ti múra ẹjọ́ orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè, àbí ẹ ti múra owó ìtán’ràn sílẹ̀? Torí àwa I.Y.P ti D.R.Y kò níí gbà kí ẹ lọ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ìwà búburú tí ẹ ń hù lórí ilẹ̀ wa yí.

Nínú fọ́nrán tí a ti gbọ́ ọ̀rọ̀ yí, ọkùnrin tí ó sọ̀rọ̀ níbẹ̀, tí kò sì sí ìdánilójú pé ọmọ Yorùbá ni,sọ ọ̀rọ̀  tí ó sì ń ka Fálọmọ mọ́ ìlú agbésùnmọ̀mí nàìjíríà! Tìẹ ti bá ẹ ìwọ ọkùnrin yí. O ń pe ilẹ̀ Yorùbá ní nàìjíríà? 

Tí Kò bá tíì yé ọ, ilẹ̀ Yorùbá ti dá dúró gẹ́gẹ́ bíi orílẹ̀ èdè, láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún tí a sì ti ṣe ìbúra wọlé fún olórí adelé wá bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún, ìjọba wa sì ti bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀,nítorí náà, ẹ mọ irú ọ̀rọ̀ tó máa ti ẹnu yín jáde kí ẹ má bàa fi ẹnu fẹ́ra bí abẹ̀bẹ̀.

Ominira yoruba daily news | the newest nation in the world 2024