Fọ́nrán kan ni a rí lórí ẹ̀rọ ayélujára níbi tí àwọn ọmọ ológun ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tó ń fipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y ti ń na ọkùnrin kan tí wọ́n wípé ṣe ni ó máa ń dúró sábẹ́ afárá Yábà ní ìpínlẹ̀ Èkó láti fi ipá gba owó lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tó ń kọjá lábẹ́ afárá náà.
Nínú fọ́nrán ọ̀hún a gbọ́ wípé àwọn méjì ni ọ̀rọ̀ náà kàn ṣùgbọ́n, ọkàn ni a rí tí àwọn ọmọ ológun aríremáse nàìjíríà ń lù bí ẹni lu bàrà nínú fọ́nrán yí .
Ǹjẹ́ ẹ̀yin ọmọ ológun agbésùnmọ̀mí nàìjíríà mọ̀ wípé ẹ ò ní ẹ̀tọ́ láti mú ẹnikẹ́ni ní orílẹ̀ èdè D.R.Y lẹ́yìn ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún tí a kéde òmìnira wa tí a sì tún ṣe ìbúra wọlé fún olórí adelé wa, bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún. Nítorí náà, orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) kìí ṣe ara aríremáṣe nàìjíríà mọ́, ìkọlù ni gbogbo yín ń ṣe sí orílẹ̀ èdè aṣẹ̀jọba ara ẹni tí a jẹ́.
Fún ìdí èyí, a tún fi àkókò yí sọ fún gbogbo ẹ̀yin gómìnà agbésùnmọ̀mí nàìjíríà tí ẹ ń jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa wípé kí ẹ kúrò nísinsìnyí, nítorí pé, ibi tí ẹ wà yẹn kìí ṣe ààyè yín rárá bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ ń ṣe lòdì sí òfin àjọ àgbáyé. Ẹ ò ní ẹ̀tọ́ kankan bó tií wù ó mọ láti máa pàṣẹ ní orí ilẹ̀ Yorùbá mọ́.
Ìwà àìb’ọ̀wọ̀ fún òfin àti ìjẹgàba tí ẹ̀yin olórí ìlú agbésùnmọ̀mí nàìjíríà ń hù lórí ilẹ̀ D.R.Y ó tó gẹ́.