Ìròyìn kan g’óri afẹ́fẹ́ lát’orí ayélujára nípa àwọn òṣìṣẹ́ fún ìlú agbèsùnmọ̀mí nàìjíríà afipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa, tó mú àwọn tó gbé òògùn olóró wọlé ní ibùdó ọkọ̀ ojù omi Tincan ní Apapa, wọ́n sì tún rí òògùn olóró nínú àwọn ọkọ̀ akérò tí àwọn míràn kó pamọ́ sí ilè ìkẹ́rù pamọ́ sí ní Ìkòròdú.
Àwọn ìlú méjèèjì yí wá ní ìpínlẹ̀ Èkó ti Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá) tí àwọn apanilẹ́kún jayé nàìjíríà njẹ gàba lé lórí. Ìdí rèé tí a fi níláti pé àkíyèsí awa Indigenous Yoruba People (I.Y.P), sí àtúbọ̀tán ìjẹgàba yìí.
Gbogbo àgbayé ló mọ̀ pé ilẹ̀ Yorùbá tí kúrò lára ìlú agbèsùnmọ̀mí nàìjíríà nípa ìkéde òmìnira wa ní ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wá ọdún ó lé méjìlelogun, ìjọba Adelé wa sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún nígbàtí a búra wọlé fún olórí ìjọba Adelé wa, bàbá wa Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́. Èyí tí ó fìdí rẹ̀ múlẹ pé, orílẹ̀ èdè olómìnira aṣèjọba ara ẹni ní a jẹ́.
Lẹ̀yìn tí Olódùmarè tí ló màmá wa Olóyè Ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla fun àṣepé òmìnira wa, kí wá ni Bọ́lá Ahmed Tinubu tó jẹ́ ààrẹ ìlú búburú nàìjíríà pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ ńwá ní orílè èdè wa? A ò bẹ̀ wọ́n láti bá wa ṣe ìjọba wa, bẹ́ẹ̀ ni a ò rán wọn níṣẹ́ láti mú arúfin fún wa. Ìwà ọ̀daràn àti ìgbésùnmọ̀mí tí ó lòdì sí òfin àgbáyé ni wọ́n nhù yìí.
A wá nfi àsìkò yí kìlọ̀ fún Tinubu pélú àwọn tó pe ara wọn ní gómìnà agbèsùnmọ̀mí nàìjíríà láti fi ilẹ̀ wa sílẹ̀ fún wa, nítorí àwọn ìjọba Adelé wá tí wà lẹ́nu iṣẹ́.
Pẹ̀lú ìdánilójú, ìwọ Tinubu pẹ̀lú àwọn gómìnà rẹ tó ńjẹgàba lórí ilẹ̀ wa kò ní bọ́ nínú ìjìyà ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn yí ní ilé ẹjọ́ ìwà ọ̀daràn àgbáyé.
Ní àfikún, gbogbo ènìyàn ló mọ̀ pé ààrẹ agbèsùnmọ̀mí nàìjíríà ní olórí àwọn tó n ṣòwò òògùn olóró, òun náà ló sọ àwọn ọ̀dọ́ wa di oníṣòwò àti olùfẹ́ lílo òògùn olóró.
Nítorínáà, Bọla Ahmed Tinubu ni kí wọ́n lọ mú, àwọn ìjọba Adelé wa mọ ìgbésẹ tó yẹ láti gbé nípa òfin àti àlàáfíà orílẹ̀ èdè wa.