Nínú fọ́nrán kan ni a ti rí ọkùnrin tó nà gbalaja sínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ pẹ̀lú aṣọ iṣẹ́ àwọn elétò gbá’lúmọ́ ti ìlú Èkó tó wà lọ́run rẹ̀, àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ sì ń wòó láì mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe.
Ariwo! Wọ́n ti pá o ! Kò mí mọ́ o, ní ìkan nínú àwọn òṣìṣẹ́ gbálùmọ́ náà sáà ń ké. Kí ló ṣẹlẹ̀? Kò sí àlàyé nínú fọ́nrán náà ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn Sójà àti òṣìṣẹ́ KÁÌ yí. A mọ̀ wípé láìsí iná èéfín kìí rú. Ó le jẹ́ èdèàìyedè ló ṣẹlẹ̀ láàárín wọn.
Èyí tó fi kan àwa ọmọ Ìbílẹ̀ (Yorùbá Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ni pé, irú ìwà asekúpani yíì wáyé ní Èkó tíí ṣe ìkan nínú àwọn Ìpínlẹ̀ wa ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y).
jọba agbésùnmọ̀mí nàìjíríà,kúrò lórí ilẹ̀ wa. Àwọn álálẹ̀ Yorùbá ti dìde síi yín báyìí. Fúnra yín lẹ ó máa pa ara yín, tí ẹ ó sì máa fúnra yín lóògùn jẹ.
Níwọ̀n ìgbà tí ẹ sì ṣe àfojúdi àti oríkunkun tí ẹ ò kúrò lórí ilẹ̀ wa,tí ẹ sì mọ̀ pé, a ti kéde òmìnira wa ní ogúnjọ́ oṣù Bélú, ẹgbàá ọdún, ó lè méjìlélógún, tí a sì ti ṣe ìbúra fún olórí adelé wa, ẹni ọ̀wọ̀, Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ ni ọjọ́ kejìlá oṣù Igbe ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rìnlélógún. Tí ìjọba Adelé sì ti bẹ̀rẹ̀ isẹ ni wàrà-wàrà-ǹ-sesà.
Ìjọba aríremáse nàìjíríà ti dáràn látàrí ohun tí ẹ ṣe yí. Àti Sójà,pẹ̀lú ẹ̀yin òṣìṣẹ́ gbá’lúmọ́, ìjọba D. R. Y kò bẹ̀ yín ní iṣẹ́ rárá. Ìfẹ́ ti àwọn ọ̀gá yín apanilẹ́kún jayé naijiria ni ẹ̀ ńṣe, Ẹ sì máa jẹ́’jọ́ ìpànìyàn níwájú àjọ àgbáyé.
Wàyí o, a ti wá rí ìdí ọpẹ́ wa fún Olódùmarè tó gbé màmá ìrọ̀rùn lóbádé, Ìyà Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla dìde ní déédéé ìgbà yí àti ní déédéé àsìkò yí fún ìran Yorùbá. Màmá MOA, gbogbo àwa ọmọ Yorùbá dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún àṣeyọrí isẹ ìtúsílẹ̀ wa.
Kí ló kù fún wa báyìí, bí kò ṣe ká fọwọ́sọwọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Adelé wa lábẹ́ ìdarí bàbá wa, Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ, fún ìgbéga orílẹ̀ èdè tó tuntun jùlọ ní àgbáyé. À kò ní rí àwọn ìwà búburú wọ̀nyí ní orílẹ̀ èdè D.R.Y, nítorí àlàáfíà àti ìgbọ́raẹniyé yóò wà láàárín àwọn òṣìṣẹ́ àti ará ìlú.