Àwọn afẹ́nifẹ́bi, tí wọ́n npe ara wọn ní afẹ́nifẹ́re, tún ti bẹ̀rẹ̀ ẹkún tí wọ́n ti ń sun láti ayébáyé, lórí bí ń kan ṣe bàjẹ́ tó ní ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà wọn.

Ṣé kò tilẹ̀ sí ẹnikẹ́ni nínú ẹgbẹ́ òṣì wọn náà ni, tí ọpọlọ rẹ̀ á ti ẹ̀ pé díẹ̀, láti mọ̀ pé òmìnira Yorùbá, èyí tí a ti gbà láti ogúnjọ́ oṣù Bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, ni ó yẹ kí wọ́n gbárùkù tì ni?

Ó tí ẹ̀ dáa bẹ́ẹ̀; tí irú àwọn rádaràdà, àwọn tí ìrònú wọn kọ orí sísàlẹ̀ yẹn bá sọ pé òmìnira l’awọn wà fún, àfàìmọ̀ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ aburú má ti ṣẹlẹ̀. Nítorí náà, ó dára kí wọ́n máa ṣe orí-burúkú tiwọn lọ.

Ṣùgbọ́n, kí ìròyìn ó máa gbé wọn síta gẹ́gẹ́bí “ẹgbẹ́” Yorùbá, ìyẹn ni wàhálà wà nínú ẹ̀ o!

Lọ́nà kíní, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi, kò sí ẹgbẹ́ kankan ní ilẹ̀ Yorùbá. Ìlẹ̀ Yorùbá ní ìjọba tiwa, tí wọ́n sì ti wà lórí ipò láti ọjọ́-kéjìlá, oṣù Igbe, ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún tí a wà nínú rẹ̀ yí!

Ohunkóhun kò sì leè yìi padà láílaí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà sì ń jẹ gàba, ṣùgbọ́n wọ́n máa kúrò láìpẹ́. Ijọba Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) sì ti sọ pé gbogbo ẹgbẹ́ tí ó wà tẹ́lẹ̀ ni òfin D.R.Y ti gbẹ́sẹ̀ lé báyi; kí ẹnikẹ́ni máṣe sọ pé àwọn ń ṣe ẹgbẹ́ kan-kan ní Ilẹ̀ Yorùbá báyi: kò sí ohun tí ó ń jẹ́ ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re rárá.

Yàtọ̀ sí èyí; Orílẹ̀-Èdè Yorùbá (D.R.Y) ti di orílẹ̀-èdè Aṣèjọba-Ara-Ẹni; nítorí náà, ẹnikẹ́ni, ẹgbẹ́-k’ẹgbẹ́, tí ó bá pe ara rẹ̀ ní “Yorùbá,” tí ó dẹ̀ ń sọ̀rọ̀ bíi pé Yorùbá ṣì wà nínú ìlú aríremáse Nàìjíríà, ọ̀ràn ńlá ni wọ́n ń dá o!Nítorí náà, kí àwọn tó pe’ra wọn ní afẹ́nifẹ́re yí, lọ ṣọ́ra dáadáa o!

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates 02/09/2024

Orílẹ̀-Èdè D.R.Y kò fi òfin wa ṣeré rárá! Nítorí èyí, Ayọ̀ Adébánjọ, ṣọ́ra gidi! Ọládipọ̀ Ọláitán, ṣọ́’ra rẹ! Alade Rótìmí-John, ṣọ́ra! Àwọn mẹ́ta wọ̀nyí ni a rí orúkọ àti àwòrán wọn nínú ìròyìn náà, lórí ẹ̀rọ ayélujára, tí ìròyìn ọ̀hún sọ pé wọ́n ń ké gbàjarè lórí bí ajẹgàba Nàìjíríà ti fẹ́rẹ̀ wó tán, láti ìgbà tí Tinubú ti di ààrẹ wọn l’ọhún.

Ẹ kú ẹkún sísun o, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe sọ pé ẹgbẹ́ Yorùbá ni yín o!Kí Olúwa kí ó bùkún Orilẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y).

Kí Olúwa kí ó bùkún Bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́ – olórí-ìjọba-adelé D.R.Y. Kí Olódùmarè, Ọ̀gá-Ògo, kí ó fi ojú àánú rẹ̀ wo Ìyá wa, Olùgbàlà Ìran Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá; kí Ààbò Ẹlẹ́dàá wà lórí wọn ní ohun gbogbo, àti lórí gbogbo ọmọ tó ti ara wọn jáde !