A gbọ́ ìròyìn nípa ọkùnrin ayédèrú dókítà kan ti ó ṣe iṣẹ́-abẹ fún aláìsàn ní Ìkòròdú, Ìpínlẹ̀ Èkó wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), níbi tí Jide Sanwolu ti ń fipá jẹgàba fún ìjọba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà.
Ṣakirudeen ni orúkọ ọkunrin ọ̀hún, ọmọ Abẹ́òkúta ní orílẹ̀-èdè wa, D.R.Y, ló pera rẹ̀, ile-ìwé girama ni ó ti jáde, gẹ́gẹ́bí ó ṣe sọ nínú fọ́nrán tí a rí lórí ẹ̀rọ ayélujára, ṣùgbọ́n tí ó gbé ayédèrú ìwé-ẹ̀rí akọ́ṣẹ́-mọṣẹ́ láti fásítì sí ilé-ìwòsàn ayédèrú náà, tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní SKYLINK MEDICAL CENTRE ní Ìkòròdú.
Ohun tí ó dun’ni ni wípé ọkùnrin yí jẹ́ ọmọ Yorùbá, bí ó ṣe sọ, àti pé orílẹ̀-èdè wa, D.R.Y, ni ó ti nṣe èyí.
Ṣùgbọ́n ní kété tí àwọn adelé wa bá ti wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìjọba ní àwọn ìpínlẹ̀ wa kọ̀ọ̀kan,àtúnṣe àti ètò tó lóòrìn yóò wà, gẹ́gẹ́bí àlàkalẹ̀ tí Ẹlẹ́dàá wa ti gbé lé ọwọ́ Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, pẹ̀lú àṣẹ Èdùmàrè, kò ní sí ayédèrú ohunkóhun ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.
Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá ti o bá fẹ́ kọ́ èkọ́ láti jẹ́ oníṣègùn tàbí irúfẹ́ ẹ̀kọ́ tí ó bá wù wọ́n, ní ẹ̀tọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀,ọ̀fẹ́ sì ni láti ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ dé àkọ́gboyè kíní ní fásitì.
Ìjọba ajẹgàba Nàìjíríà, ẹ kúrò lórí ilẹ̀ wa. Ayédèrú ìjọba ni yín!