Létò-letò ni ohun gbogbo ní Orílẹ̀-Èdè wa, Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y).
Ní àìpẹ́ yí, Màmá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin) tún bá àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y) sọ̀rọ̀, èyí tí ó sì jẹ́ ọ̀rọ̀ àkọ́sọ wọn sí gbogbo-gbò àwa I.Y.P ti D.R.Y, nínú ọdún yí, ẹgbàá-ọdún ó lé márùndínlọ́gbọ̀n.
Lẹ́yìn tí Màmá ti kí wa fún àlàjá-ọdún, wọ́n tún wá kí àwa I.Y.P ti D.R.Y, lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan, fún ìdúro-ṣinṣin àti iṣẹ́-takuntakun ní àkókò yí.
Màmá wa kí gbogbo àwọn tí ó jẹ́ pé wọ́n ti yọ àwọn ọmọ wọn kúrò ní ilé-ìwé ní orílẹ̀-èdè wa, D.R.Y, níbití àwọn ètò-amúnisìn tí wọ́n ń pè ní Nàìjíríà ti ń jẹgàba ṣùgbọ́n tí wọ́n máa kúrò ní àìpẹ́ yí lágbára Èdùmàrè.
Màmá wá sọ fún gbogbo àwọn òbí bẹ́ẹ̀ pé kí wọ́n jọ̀wọ́,kí wọ́n bá wa mú ojú tó àwọn ọmọ náà dáadáa. Ẹ jẹ́ kí wọ́n lọ máa kọ́ èdè wa èdè Yorùbá ní àkókò tí a ti mú wọn kúrò ní ilé ìwé wọ̀nyẹn báyìí.
Ẹ jẹ́ kí wọ́n máa lọ kọ́ bí wọ́n ṣe ń sọ Èdè Yorùbá, bí wọ́n ṣe ń kọ èdè Yorùbá sílẹ̀, bí wọ́n ṣe ń kàá àti bí wọ́n ṣe ń ṣe ìṣirò ní èdè Yorùbá.
Eléyìí ṣe pàtàkì lọ́pọ̀lọ́pọ̀ torí, gẹ́gẹ́bí Màmá ṣe sọ, wọ́n ní èdè Yorùbá ni a máa fi ṣe Orílẹ̀-Èdè wa.” Àti pé, kò ní dára, nígbàtí ìṣàkóso-adelé D.R.Y bá ti ṣí àwọn ilé-ìwé wa padà, kí àwọn ọmọ yẹn wà nínú kíláàsì wọn, kí wọ́n wá máa wòran, kí ohun tí wọ́n nkọ́ wọn kí ó má yé wọn, kò ní dára bẹ́ẹ̀ o, torí Yorùbá ni wọ́n máa fi kọ́ wọn ò. Màmá tẹnu mọ́ eléyi lọ́pọ̀lọpọ̀.
Màmá sọ pé a fẹ́ kí òye kí ó yé wọn dáadáa, nígbàtí D.R.Y bá ṣí ilé-ìwé padà; nítorí èyí, ó di dandan, báyìí kí a jẹ́ kí wọ́n gbọ́ èdè Yorùbá, kí wọ́n lè sọọ́ lẹ́nu, kí wọ́n sì lè kàá, bẹ́ẹ̀ náà ni kí wọ́n lè kọọ́ sílẹ̀.