A ti máa ń gbọ́ bí àwọn òyìnbó amúnisìn, tí wọ́n ń pe ara wọn ní “alágbayé” (globalists), ṣe ń ṣe ìkà sí aláwọ̀dúdú bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń ṣe sí ara wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé aláwọ̀dúdú ni wọn kò fẹ́ rí, ní orí ilẹ̀ ayé ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí èyí, wọn ò tilẹ̀ fẹ́ kí ènìyàn ó pọ̀ ní ayé yí, ìdí nìyí tí wọ́n fi ń hu ìwà ìkà láàárín ara wọn pàápàá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun aburú ni wọ́n ń ṣe sí àwọn ènìyàn wọn.
Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi, omi tí ó njáde láti inú ẹ̀rọ ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà, kò dára fún lílò, ṣùgbọ́n àwọn èèyàn kò mọ̀; omi ọ̀hún ló sì ń fa àwọn oríṣiríṣi àìsàn.
Gẹ́gẹ́bí ọkùnrin òyìnbó kan ní Amẹ́ríkà ṣe sọ, èyí tí a rí fọ́nrán rẹ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujára wípé, kẹ́míkà kan wà tí wọ́n ń pè ní “hydrofluorosilicic acid,” tí a tún mọ̀ sí “silicofluoride” tí ìjọba Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà gba àwọn ilé-iṣẹ́ kan láti máa ṣe àdànù rẹ̀ tí ó ti ilé-iṣẹ́ wọn wá sínú omi tí ilé-iṣẹ́ ìjọba olómi nfà lọ sí inú ilé àwọn ará ìlú, bẹ́ẹ̀ sì ni kẹ́míkà yí máa ń ṣe ìpalára bíi àìsàn-ọkàn, àìní-ọpọlọ tó pé dáadáa, àìní-okun tó láti borí àìsàn tó bá kọlu’ni.
Ìjọba wọn ń ṣe èyí bí ìgbàtí a bá sọ pé wọ́n nṣe ìrànwọ́ fún àwọn ilé-iṣẹ́ ọ̀hún láti rí’bi da àwọn ìdọ̀tí tó ń jáde láti ilé-iṣẹ́ wọn sí; ṣùgbọ́n eléyìí wá já sí pé kí ẹni tó bá mu omi tààrà láti ẹ̀rọ-omi tí ó wọnú ilé wọn, a wá máa mu silicofluoride láì mọ̀!
Ìdí tí ọ̀rọ̀ yí fi kàn wá ni pé, àwọn amúnisìn wọ̀nyí máa nwá ọ̀nà láti kó àwọn ohun olóró bẹ́ẹ̀ wá sí ilẹ̀ aláwọ̀dúdú, àwọn alábọ̀dè ààrẹ orílẹ̀-èdè ní Áfríkà ni wọ́n sì máa ń lò fún irúfẹ́ iṣẹ́ bẹ́ẹ̀.
Nítorí náà, a ní láti kíyèsára gidigidi, kí á máṣe gba ohunkóhun tí a kò bá mọ ìwúlò rẹ̀ lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni.
Fún ìdí èyí, a dúpẹ́ pé Olódùmarè fún wa ní Ìránṣẹ́ Rẹ̀, màmá wa, Ìyá-ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, láti la ojú wa sí Ọ̀nà tí a níláti tọ̀, kí Ìran Yorùbá máṣe tún kó sí ìdààmú mọ́ títí ayé.