ỌLỌ́RUN OLÓDÙMARÈ, ÀWÁMÁRIDÍ, NÍSIÌYÍ, BA GBOGBO OHUN-IBI JẸ́, PÁTÁPÁTÁ; GBOGBO MÁJẸ̀MÚ ÌRÁNṢẸ́-ẸNI-IBI, ÀṢÌTÁÁNÌ, GBOGBO ÌLÉRÍ, ÈTÒ, ÈTE, ÀTI ÈRÒ TÍ Ó LÒDÌ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ. NÍ AGBÁRA TÍ ỌLỌ́RUN FI NJẸ́ ÈMI-NI, KÍ ÌPARUN NÁÀ ṢẸLẸ̀ SÍ ÀWỌN Ọ̀TÁ YORÙBÁ WỌ̀NYÍ, LỌ́WỌ́LỌ́WỌ́ BÁYI

OLÓDÙMARÈ, ALÁGBÁRA, TÍ Ó NÍ IPÁ; OLÓDÙMARÈ TÍ Ó NÍ IPÁ LÓJÚ OGUN, ỌLỌ́RUN ÀWỌN ỌMỌ-OGUN, ṢE ÌPARUN PÁTÁPÁTÁ, NÍSIÌYÍ, FÚN ÀṢẸ, AGBÁRA ÀTI IPÒ TÍ WỌ́N NLÒ LÁTI JẸGÀBA LÓRÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ.

ṢE ÌPARUN FÚN GBOGBO ÌWÀ ÌDÚKOKÒ, ÌJẸGÀBA, DÍDẸ́RÙBANI, ÌHÀLẸ̀, ÌGBÓGUN-TINI, TÍ WỌ́N DOJÚKỌ ỌMỌ-ÌBÍLẸ̀-YORÙBÁ, TI ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ

Láìpẹ́, láìjìnnà, orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) yóò di àpéwò káàkiri àgbáyé látàrí àwọn ohun àrà-meèrírí tí yóò máa ṣẹlẹ̀ lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan ní orílẹ̀ èdè wa nípasẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ àti òye tí Olódùmarè fún màmá wá, iya ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, lára àwọn ohun tí màmá wa ti máa ń bá wa sọ náà ni wípé, gbogbo àwa tó jẹ́ ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, IYP) ni yóò ní ilé lórí nítorí pé, ìjọba orílẹ̀ èdè DRY yóò fún ẹni kọ̀ọ̀kan tí ọjọ́ orí rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti ọdún mọ́kànlélógún ní ilẹ̀, wọ́n yóò sì tún ṣe àtìlẹyìn fún wọn láti kọ́ ilé náà.

Bẹ́ẹ̀ sì ni ètò yóò wà fún àwọn àgbègbè tí ó bá yẹ fún ilé gbígbé, ilé iṣẹ́ tàbí fún iṣẹ́ ọ̀gbìn. Ẹnikẹ́ni kò ní leè kọ́ ilé láìgba àṣẹ lọ́dọ̀ ìjọba DRY bẹ́ẹ̀ni, ìjọba ní láti lọ ṣe àbẹ̀wọ̀ sí irú àgbègbè bẹ́ẹ̀ kí wọn leè ríi dájú pé kò ní sí ìjàǹbá kankan fún àwọn olùgbé ilé náà nígbà tí wọ́n bá kọ́ọ tán, tàbí fún àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ń kọ́ ilé ọ̀hún,nítorí pé àwọn akọ́sẹ́mọṣẹ́ tó kún ojú òṣùwọ̀n ni yóò máa kọ́ àwọn ilé wa ní orílẹ̀ èdè DRY. 

Fún ìdí èyí, gbogbo àwa ọmọ IYP ti DRY ìgbé ayé ìrọ̀rùn ti dé fún wa, ìjọba tí yóò fi àwọn ará ìlú ṣe àkọ́kọ́ ní ìjọba Democratic Republic of the Yorùbá, DRY, nítorí pé lẹ́yìn Ọlọ́run, Yorùbá ni!