Ǹjẹ́ ìdààmú kọ́ ni eléyìí fún àwọn ọ̀dọ́ ní orílẹ̀ èdè Ukraine tí ó fi ẹ̀gbẹ́ ti Russia?
Fọ́nrán kan ló fi hàn wá ní ibi tí arábìnrin kan tí ó ńfi ìtara sọ̀rọ̀ pé, kò sí ọ̀dọ́ ní ìgboro ìlú mọ́ o, nítorípé gbogbo wọn ní wọ́n ń fi tipátipá mú lọ sí ojú ogun láti jà nínú ogun tí ó ń lọ lọ́wọ́ láàrín Russia àti Ukraine fún bíi ọdún díẹ̀ sẹ́yìn.
Obìnrin tí ó ń sọ̀rọ̀ yí pàápàá jẹ́ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣófin àgbà, ní ìlú Ukraine. Ó ní ẹnikẹ́ni tí ó bá ti jẹ́ ọ̀dọ́, ó di dandan kí wọ́n wọ lọ sínú iṣẹ́ ológun, eyí tí ó ti mú kí àwọn ọ̀dọ́ tán ní gbogbo abúlé pátá, ọ̀dọ́ tí wọ́n bá kó fìrí rẹ̀ lórí títì tàbì ní ìgboro ìlú tí o bá wà, wọ́n yóò gbé e ní tipátipá sínú ń ọkọ̀ wọn, gẹ́gẹ́ bi ati ri nínú fọ́nrán náà.
Ọ̀pọ̀ ọ̀gá ọmọ ológun tí ó wà nípa kí á máa fí ipá mú ọ̀dọ́ sí iṣẹ́ ológun yìí ti di olówó òjijì, bí obìnrin náà ti sọ. Nítorí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ń san owó láti gba ara wọn sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìdààmú yí.
Màmá wa Olóyè Ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, lẹ́ẹ̀kan si ẹ séún, a rí gbogbo akitiyan tí ẹ̀ ń ṣe lórí ìran yín láti di òmìnira kúrò lọ́wọ́ amúnisìn àti agbésùnmọ̀mí Nàìjíría tí ó mú’lé tì wa,
tí a sì ti kúrò lára wọn láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-méjìlelogun, tí a sì ti bẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba wa ní Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá(Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) bákanàá, ní ọjọ́ kejìlá oṣù Igbe ẹgbàá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún pẹ̀lù olórí adelé wa, bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ àti àwọn adelé yókù ní gbogbo ìpínlẹ̀ méjèje ilẹ̀ Yorùbá láì sí ìtàjẹ̀sílẹ̀ tàbí ogun, iṣẹ́ Olódùmarè ni.
Gẹ́gẹ́ bí màmá wa ṣe má ń sọ wípé ọ̀dọ́ ló ni ìlú , ẹ wo orílẹ̀ èdè Ukraine, ní ibi tí wọ́n ti fi tipátipá mú àwọn ọ̀dọ́ wọn láti dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ ológún, láti dojú ìjà kọ orílẹ̀ èdè Russia. Ẹ̀yin ọ̀dọ́ Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), ẹ jí gìrì láti ṣe ojúṣe yín, ní orílẹ̀ èdè tuntun wa yìí, màmá wa kò pé yín láti ta ẹ̀jẹ̀ yín sílẹ̀ nínú ogun, bíkòṣepé kí ẹ dìde láti lo ògo yín fún ọ̀jọ́ iwájú rere yín àti Orílẹ̀ èdè D.R.Y.
Obìnrin náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Anna Skorokhod, tẹ̀síwájú pé, ogun tí ó ń lọ lọ́wọ́ ní àárín orílẹ̀ èdè méjèjì yìí ti di ogun àwọn tálákà, tí kò sì yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, fún irú ìdí èyí ni màmá wa, Olóyè Ìyá Ààfin Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla, ìyá wa ìrọ̀rùn ló bá dé ṣe má ń sọ pé, ọmọ Yorùbá kò ní jagun, sùngbọ́n a ó dá ààbò bo ilẹ̀ wa àti àwọn ènìyàn wa.