TORONTO VENTURE EXCHANGE ni wọ́n wà o! Orúkọ wọn ni THOR EXPLORATIONS LIMITED, iṣẹ́ wọn ni láti máa wa GÓÒLÙ, káàkiri ìwọ̀-oòrùn Áfríkà! Ìkan nínú àwọn ilé-iṣẹ́ wọn ni, SEGILỌLA RESOURCES OPERATING LIMITED (SROL). Gẹ́gẹ́bí orúkọ wọn ṣe so, àwọn ohun-àmúṣọrọ̀ (Resources) ni wọ́n nwá kiri. 

Àwọn SEGILỌLA RESOURCES OPERATING LIMITED yí, wọ́n sọ pé “Nàìjíríà” ni àwọn wa o! Níbo ni ní “nàìjíríà” o? Ohun tí a rí lórí ayélujára nípa ilé-iṣẹ́ wọn sọ pé, “ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.” Àbí ẹ ò rí ọ̀ràn-dídá? Ẹ jọ̀wọ́, ẹni bá m’ojú wọn, kí ó ṣíra fi tó wọn létí pé, nàìjíríà kò ní ìpínlẹ̀ kankan tó njẹ́ “ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun” o!

Láti ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá-ọdún ó lé méjìlélógún, ni kò ti sí ibikankan ní nàìjíríà tí ó njẹ́ “ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun.” Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y), òun ni ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun wa, ẹ bá wa sọ fún wọn bẹ́ẹ̀.

Wọ́n ní àwọn ni oníṣẹ́ góòlù tí ó làmìlaaka jù ní “Nàìjíríà” – ẹ màṣe gbàgbé àti bá wa sọ fún wọn ò, pé, ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun kìí ṣe ara Nàìjíríà o, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y) ni ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun wa o! Kí wọ́n má sọ pé àwọn ò mọ̀ o!

Wọ́n sọ, fún’ra wọn o, pé góòlù tí àwọn nwà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, ní èyí tí ó sì jẹ́ pé Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ni ó wà, wọ́n ní ìkan lára àwọn góòlù tí ó jẹ́ ojúlówó góòlù jùlọ ní ìwọ̀-oòrùn Áfríkà ni!

Góòlù tí Segilọla nwà, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun (D.R.Y) yí, òun ni àwọn fún’ra wọn sọ pé ó tóbi ju èyíkéyi ní nàìjíríà lọ (ṣé àwa, D.R.Y kúkú ti kúrò nínú nàìjíríà ní ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá-ọdún ó lé méjìlélógún, a sì ti bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso-ara-ẹni wa ní ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe, ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún, ṣùgbọ́n Segilọla ṣì nbu ẹnu ẹ̀tẹ́ lù wá nípa pípe ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, ní “nàìjíríà.”)

Wọ́n ní oṣù ẹrẹ́nà, okòó-lé-lẹ́gbàá ọdún ni àwọn bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ ilé-iṣẹ́ wọn ọ̀ún ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, àti pé wíwa góòlù, gan-an gan bẹ̀rẹ̀ ní oṣù èrèlé okòó-lé-lẹ́gbàá ọdun, ó lé’kan.

SEGILỌLA RESOURCES OPERATING LIMITED (SROL) project after tax economic sensitivity osun state, D.R.Y

Wọ́n ní ó yẹ kí koto-góòlù yí, pẹ̀lú bí wọ́n ṣe nwà-á, kí ó fún wọn ní góòlù fún ọdún mẹ́fà. Èyí túmọ̀ sí pé, ní bí wọ́n ṣe nwà-á yí, wọ́n á ri wà títí okòó-lé-lẹ́gbàá ọdún, ó lé méje. Wọ́n ní, ní àkókò náà, iye góòlù tí àwọn á ti rí kó (yàtọ̀ sí rọ̀bì ara rẹ̀) á ti jẹ́ mẹ́ta-dín-láadọ́rin mílíọ̀nù tọ́ọ̀nù ní wíwúwo! Ẹ jọ̀wọ́, adúrú góòlù tí ó bá tó iye tọ́ọ̀nù yí ní àpapọ̀ wíwúwo rẹ̀, kìí ṣe góòlù kékeré rárá!

Àwọn ilé-iṣẹ́-ìkọ́lé kan, èyí tí ó jẹ́ ti orílẹ̀-èdè china, ní ó bá Segilọla kọ́ ilé-iṣẹ́ góòlù wíwà yí sí ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun wa, D.R.Y

Mílíọ̀nù mẹ́rin-dín-láadọ́run dọ́là ni Segilọla ná sí àti gbé ilé-iṣẹ́ wọn ọ̀ún dúró, tí wọ́n nwa góòlù ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, èyí tí kìí ṣe ara nàìjíríà mọ́ láti ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá-ọdún-ó-lé-méjìlélógún. Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ti lé ní ọdún méjì, báyi, tí a ti kéde òmìnira wa, tí a sì tipa bẹ́ẹ̀ ti kúrò lára Nàìjíríà.

Tí àwọn ilé-iṣẹ́ Segilọla tí wọ́n nwa góòlù D.R.Y ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun yí, tí wọ́n bá jẹ́ ilé-iṣẹ́ tí ó nfi ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun ṣe nkan, ó yẹ kí wọ́n ti kàn sí D.R.Y láti gbogbo àkókò yí, pàápàá, bákannáà, láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe, ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún yí, tí ìṣàkóso D.R.Y ti bẹ̀rẹ̀, lábẹ́ Olórí Ìṣàkóso-Adelé wa, Bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́.

Wọ́n ní láarín oṣù agẹmọ sí oṣù ọwẹ́wẹ̀, okòó-lé-lẹ́gbàá ọdún, ó lé kan, ni àwọn kọ́kọ́ mú góòlù-gidi jáde láti inú góòlù ọmọ Yorùbá (D.R.Y) yí, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.

THOR EXPLORATIONS LIMITED, tí Segilọlá jẹ́ ìkan nínú ilé-iṣẹ́ wọn yí, ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Ṣẹ́gun Lawson ni adárí-iṣẹ́-àgbà (CEO) níbẹ̀ o! Wọ́n ní òun gan-an gan ni ó wà ní’di bí àwọn ṣe rí ‘Segilọla Gold Project’ yí.

Wọ́n ní, Ṣẹgun Lawson yí jẹ́ ẹni tí ó ní páálí-ọmọ-onílú ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Lára àwọn olùdarí tó kù, ní ilé-iṣẹ́ THOR, tí ó sì jẹ́ àwọn náà ni ó ni ilé-iṣẹ́ Segilọla yí, ni, Olóyè Káyọ̀dé Adérìnókùn, ẹni tí ó ti fi ìgbà-kan-rí jẹ́ Olùdámọ̀ràn Pàtàkì (Special Adviser) fún ìṣàkóso ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lábẹ́ àwọn amúnisìn aríremáṣe nàìjíríà. Lára àwọn adarí wọn náà tún ni Fọlọ́runṣọ́ Adéoyè, tí òun náà ti fi ìgbà kan jẹ́ Olùdámọ̀ràn-Pàtàkì fún Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lábẹ́ amúnisìn-nàìjíríà!

Ibi tí Segilọla ti nṣe ìfimúfínlẹ̀ fún àlùmọ́nì góòlù ní ìpínlẹ̀-Ọ̀ṣun yí, jẹ́ àkápọ̀ ẹgbẹ̀rún-lé-ní-ọ̀ọ́dúnrún kìlómítà (1,300 sq. kilometers). Eléyi kìí ṣe ilẹ̀-kékeré rárá – tí a bá ṣe-é ní ìró-àti-ìbú tí ó bára mu, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ilẹ̀ tí ìbú rẹ̀ jẹ́ ogójì kìlómítà, tí ìró rẹ̀ náà fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogójì kìlómìtà. Ibi tí Segilọla ti nwa góòlù ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá, èyí tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣùn nìyí o, tí a sì rí ọmọ-ìbílẹ̀-Yorùbá tí ó ngbé ní Ọ̀ṣun tí kò rí jẹ, kò rí mu, títí tí ó fi pa ara rẹ̀!

Yàtọ̀ sí eléyi, àwọn THOR EXPLORATIONS LIMITED tí wọ́n jẹ́ baba-ìsàlẹ̀ Segilọla yí, wọ́n tún ní ibi kan ní Orílẹ̀-Èdè wa, D.R.Y, tí ó ní àlùmọ́nì LITHIUM, ṣùgbọ́n wọn ò dárúkọ ibẹ̀. Ọ̀daràn wọn ṣì npèé ní “southwest nigeria.” “Newstar Minerals Limited” ni orúkọ ilé-iṣẹ́ wọn tí ó nṣe ti Lithium yẹn.

Lithium ni ohun àlùmọ́nì tí a fi nṣe àwọn “rechargeable battery” tí a nlò fún ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, laptop, digital camera, ọkọ̀ tí ó nlo agbára mọ̀nọ̀mọ́nọ́ (electric vehicles), àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ! Ọmọ Yorùbá, lára àwọn ohun àmúṣọrọ̀ tí Olódùmarè jogún fún wa gẹ́gẹ́bí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) ti D.R.Y ni’yí o!

Nígbàtí wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ wíwọlé-òwó ti ibi tí Segilọla ti nwa góòlù ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá yí, ọ̀nà mẹ́rin ni wọ́n ṣe-é sí: èyí tí ó jẹ́ oníye tó kéré jù, ni èyí tí ó jẹ́ pé ní ọdún kan, okòó-lé-ní’gba, ó lé márun mílíọ̀nù dọ́là áá wọlé ($225 million), tí ó sì jẹ́ pé lẹ́yìn ọdún kan àti oṣù mẹ́rin tí wọ́n ti nwa góòlù ọ̀ún, wọ́n á ti pa gbogbo owó tí wọn ná láti gbé iṣẹ́ náà kalẹ̀, wọ́n á ti pá wọlé, ìgbádùn láá wá kù, fún gbogbo àkókò tí wọ́n bá nrí góòlù náà wà.

Èyí tí owó rẹ̀ pọ̀jù ni èyí tí ó jẹ́ pé, láarin ọdún kan, wọ́n á ti rí irínwó ó lé ní mẹ́rin-lé-láadọ́run mílíọ̀nù dọ́là ($494 million), tí ó sì jẹ́ pé lẹ́yìn oṣù-mẹ́jọ-àbọ̀ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, wọ́n á ti pa gbogbo owó tí wọ́n fi gbé iṣẹ́ kalẹ̀, wọ́n á ti pá wọlé!

Ní ọdún tí ó kọjá yí (ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́talélógún), kò dín ní bíi ọgọ́fà mílíọ̀nù dọ́là tí ó wọlé fún Segilọlá – èyíinì ká gbà pé olówó-kékeré góòlù nìkan ni wọ́n wà ní ọdún náà, àti ká gbà pé wọn ò fi gbogbo ara ṣiṣẹ́ lọ títí ni o! ($120 million, ní jẹ̀lẹ́nkẹ́)! Owó ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá (I.YP ti D.R.Y) nìyẹn o! Èyí túmọ̀ sí $10 million jẹ̀lẹ́nkẹ́ lóṣù kan láti ibi ìwakùsà kan ṣoṣo péré ní D.R.Y.

Láarín oṣù mẹ́ta (oṣù agẹmọ sí oṣù ọwẹ́wẹ̀) ní ọdún tí a wà yí (ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún), Segilọla sọ pé iye tí ó wọlé fún àwọn ní oṣù mẹ́ta yí, gẹ́gẹ́bí èrè ni o! – lẹ́yìn tí wọ́n ti yọ gbogbo ìnáwó, wọ́n ní ó jẹ́ ogójì-mílíọ̀nù ó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba dọ́là ($40,200,000) – iye tí wọ́n jẹ́wọ́ ẹ̀ síta nìyẹn o! – láarin oṣù mẹ́ta péré! Sé ẹ mọ̀, I.Y.P, pé, lẹ́yìn tí a ti ṣe ìbúra-wọlé fún ìṣàkóso adelé wa ní D.R.Y nìyẹn o! Ara owó tí à bá ti fi san owó ọ̀sẹ̀-méjì-méjì fún àwọn òṣìṣẹ́ D.R.Y nìyẹn o!

SEGILỌLA RESOURCES OPERATING LIMITED (SROL) project after tax economic sensitivity osun state. D.R.Y

Ẹni tí a ńwò kì í wò’ran