Tí irọ́ bá lọ f’ógún ọdún, ọjọ́ kan ṣoṣo ni òtítọ́ yóò bàa. Ṣé ọjọ́ ti pẹ́ tí àwọn amúnisìn ti kó ìran Yorùbá sínú ìdààmú nípa síso irun iwájú pọ̀ mọ́ ti ìpàkọ́ tí wọ́n kó orílẹ̀ èdè Yorùbá papọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀ èdè míràn láti máa pè wọ́n ní Nàìjíríà.
Ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò tó tí Olódùmarè wípé kí ìran Yorùbá padà sílé, Tó sì gbé ìránṣẹ́ rẹ̀ dìde, màmá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla (olóyè ìyá-ààfin) láti yọ wá kúrò nínú ìgbèkùn àwọn amúnisìn. MOA ni Olódùmarè lò láti ṣí wa lójú tí a fi mọ̀ wípé Nàìjíríà kìí ṣe orílẹ̀ èdè, ìgbékalẹ̀ àwọn amúnisìn ni.
Láìpẹ́ yìí tí màmá wa MOA bá gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) sọ̀rọ̀, wọ́n sọ fún wa wípé kí a túbọ̀ máa pariwo láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ́ pé Nàìjíríà kìí ṣe orílẹ̀ èdè, ètò àwọn amúnisìn ni.
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a túbọ̀ tẹ’ra mọ láti máa pariwo rẹ̀ ní ibi gbogbo tí a bá wà, kí a jẹ́ kí gbogbo ènìyàn mọ̀ pé Nàìjíríà kìí ṣe orílẹ̀ èdè, àwọn amúnisìn ló ṣe ètò rẹ̀ láti lè rí ààyè wá máa kó àwọn àlùmọ́ọ́nì ilẹ̀ wa, àti pàápàá láti wá gba ilẹ̀ wa.
Oríṣiríṣi irọ́ ni wọ́n sì ń pa, kí ìyè àwọn ènìyàn má lè ṣí, wọ́n gba àṣà wa, wọ́n gba ìṣe wa, àti àwọn nkan tó pọ̀, kí wọ́n bàá rí àyè jẹ́ gàba lórí ilẹ̀ wa.
Nígbà tí wọ́n ṣe àsopọ̀ ìsọnu yí, nígbà náà, wọ́n wípé lẹ́yìn ọgọ́rùn-ún ọdún, orílẹ̀ èdè tí kò bá nífẹ̀ẹ́ sí àsopọ̀ ọ̀hún mọ́ ní ẹ̀tọ́ láti kúrò lára Nàìjíríà, nítorí wọ́n mọ̀ pé láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún yí, àwọn yóò ti rí ààyè kó wa lẹ́rù dáadáa. Ọgọ́rùn-ún ọdún yí sì ti pé láti ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ wọn ò ṣíwọ́ ìwà ibi wọn.
Olódùmarè tó ní ìfẹ́ ìran Yorùbá, ló gbé màmá wa MOA dìde ní déédéé ìgbà yí àti ní déédéé àsìkò yí láti gbà wa lọ́wọ́ amúnisìn àti lọ́wọ́ ìtànjẹ Nàìjíríà. Ojú wa ti là, àwa ọmọ Aládé ti bọ́!