Ṣébí láìpẹ́ yí ni a gbọ́ bí àwọn ilé-iṣẹ́ ìpoògùn aládàńlá ní àgbáyé (“Big Pharma”) ṣe nfún’ra wọn da àìsàn sí’nú ayé nípa oríṣiríṣi abẹ́rẹ́ àjẹsára tí wọ́n sọ pé wọ́n ń ṣe.
Bákannáà ni a tún gbọ́ ọ̀rọ̀ tó jáde láti ẹnu ọ̀kan nínú àwọn òyìnbó orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà Robert Kennedy Junior, tó sọ pé lóotọ́ ni!
Ọkùnrin náà sọ pé a rí àìsàn tó jẹ́ pé ó ní irúfẹ́ oúnjẹ tí ènìyàn máa jẹ, pẹ̀lú òògùn tó wà l’arọ́wọ́tó, tí àìsàn náà á sì kúrò l’agọ́ ara, ṣùgbọ́n àwọn òṣìṣẹ́ ibi wọ̀nyí kò ní jẹ́ kí ojú àwọn ènìyàn là sí oúnjẹ bẹ́ẹ̀; torí ìyẹn ò ní mú owó-ẹ̀jẹ̀ wá fún wọn!
Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n á ní kí àwọn èèyàn wá gba abẹ́rẹ́-àjẹsára. Ọkùnrin yí wá fi àìsàn ‘’chicken pox’’ ṣe àpẹẹrẹ, ó ní a rí oúnjẹ tí ẹnikẹ́ni le rà tàbí sè nínú ilé, kí ó máa jẹẹ́ dáadáa, kí ó sì mu òògùn “Vitamin A” si, ó tán! ṣùgbọ́n àwọn oníṣẹ́-ibi wọ̀nyí kò ní la ojú àwọn èèyàn sí ọ̀nà àbáyọ náà, wọ́n á ní kí wọ́n wá gba abẹ́rẹ́-àjẹsára: tí abẹ́rẹ́-àjẹsára náà á wá fa àrùn ìtọ̀-ṣúgà sí ẹni náà lára; àrùn yẹn ni ẹni náà á wá máa sìn títí ayé: ìyẹn á mú owó wá fún “Big Pharma.”
Ọkùnrin Robert Kennedy yí sọ pé ní ọdún kan, iye owó tí àwọn ilé-iṣẹ́ ìpoògùn aládáńlá wọ̀nyí npa, lórí títa abẹ́rẹ́-àjẹsára, jẹ́ ọgọ́ta bílíọ̀nù dọ́là; ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí àwọn abẹ́rẹ́-àjẹsárá bá ti ṣe àkóbá fún àwọn ènìyàn tán, àwọn ènìyàn yí á wá bẹ̀rẹ̀ sí ra òògùn lọ́dọ̀ àwọn tó kó àìsàn sí wọn lára (Big Pharma), iye tí àwọn aládanlá ilé-iṣẹ́ ìpoògùn wọ̀nyí á ṣẹ̀ṣẹ̀ tún wá rí, l’ọdún, jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta bílíọ̀nù dọ́là! látàrí títa òògùn fún ẹni tí ó jẹ́ pé àwọn ni ó kó àìsàn ọ̀hún si lára!
Èyí túmọ̀ sí pé, l’ọdọọdún, àgbáyé nfi ọgọ́ta bílíọ̀nù dọ́là ra àìsàn nígbàtí wọ́n bá ra abẹ́rẹ́-àjẹsára.
Nígbàtí abẹ́rẹ́-àjẹsára bá ti fa àìsàn tán, àgbáyé á tún wá ná ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta bílíọ̀nù dọ́là láti ra òògùn fún àìsàn tí wọ́n ti fi ọgọ́ta bílíọ̀nù dọ́là rà tẹ́lẹ̀ sínú àgọ́ ara wọn! Ìyẹn ò sì sọ pé kí àìsàn náà ó kúrò.
Àìsàn tí wọ́n máa máa sìn títí ọjọ́ ayé wọn ní.
Kíni ìwọ̀nyí túmọ̀ sí? ó túmọ̀ sí pé, gẹ́gẹ́bí ọkùnrin yí ṣe sọ, ọdọọdún ni àwọn aládanlá ilé-iṣẹ́ ìpoògùn ní àgbáyé njèrè ọ̀tà-lé-l’ẹẹ́dẹ́gbẹ̀ta bílíọ̀nù dọ́là lórí òwò títa àìsàn fún ọmọ-aráyé. Àwọn apanimáyọdà!
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè, fún ìfẹ́ Rẹ̀ sí àwa ọmọ Rẹ̀, ìran Yorùbá. Ìjọba Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ní ètò tó dára fún ìwòsàn àti aláfíà Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), nípasẹ̀ àlàkalẹ̀ tí Èdùmarè fún wa nípàsẹ̀ màmá wa, Ìyá-Ààfin, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá.
Kí gbogbo àwa I.Y.P yàgò fún ohunkóhun tí àlàkalẹ̀ àti ètò ìjọba D.R.Y bá ti ní ká yàgò fún: kí á máṣe gba ohunkóhun tí a ò mọ ibi tó ti wá kí a má bàa fi ọwọ́ ara wa fa àkóbá fún ara wa.