Àwọn àdúrà tó ṣe kókó tí a máa ń gbà tí a bá fẹ́ kúrò ní ilé lọ sí ibikíbi láàárọ̀ ni pé kí Olúwa pa àlọ àti àbọ̀ wa mọ́,kí a má kan àgbákò.

Fọ́nrán ọmọkùnrin kan ni a rí tò sì ba’ninínújẹ́ púpọ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́kùnrin yìí tọ́ka sí ìṣe pàtàkì ètò ìwòsàn ọ̀fẹ́ ni orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y), tí màmá wa, ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ fún àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P). A gbé òṣùbà fún ìyá wa MOA nítorí inú rere tí wọ́n ní sí ìran Yorùbá. 

Ọ̀dọ́kùnrin yìí ló sọ wípé  òun wọ ọkọ̀ láti Bẹ́gà ní ìlú Èkó, tí òun sì ń lọ Ìpínlẹ̀ ọ̀sun láti lọ ṣiṣẹ́. Ṣùgbọ́n  nígbà tó ku díẹ̀ kí wọ́n dé GuruMaraji ni táyà ọkọ̀ náà fọ́ lójijì. Láìmọ̀ wípé awakọ̀ náà, gbé epo pẹtiró sí ẹ̀yìn ọkọ̀. Lọ́gán,ni ọkọ̀ náà gb’iná  lórí eré tí awakọ̀ kò sì dúró, ọkùnrin yìí bẹ́ jáde kúrò nínú ọkọ̀ náà láti ojú fèrèsé láti dóòlà ẹ̀mí rẹ̀. 

Ohun tó wá burú jù nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni wípé, lẹ́yìn tí ó lo oṣù kan ní ilé ìwòsàn tí wọ́n gbée lọ, wọ́n ní àyàfi kó tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn ti ìjọba. Níbẹ̀ ni àwọn Dókítà ti sọ fún un pé ó nílò iṣẹ́ abẹ. 

Ó wà ṣe ni láàánú pé ọkùnrin yìí kò rí isẹ abẹ ṣe lẹ́yìn oṣù kan tí wọ́n sì ní pé kò má lọ sí ilé rẹ̀ , nítorí òbítíbitì  owó tí wọ́n ní kó san fún iṣẹ́ abẹ náà,nígbà tí kò rí owó san. Tó bá jẹ́ wípé ìjọba agbésùnmọ̀mí nàìjíríà ti kúrò lórí ilẹ̀ D.R.Y, ni, irú ọkùnrin yìí a ti rí ìtọ́jú tó péye gbà lọ́fẹ̀ẹ́. 

Gbogbo àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y), dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè fún Ìyà Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla tó rán sí wa ní déédéé ìgbà yìí àti déédéé àsìkò yìí. Ẹ wo irú ètò ìwòsàn ọ̀fẹ́ tí wọn tí ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ fún ìgbádùn àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I Y. P). Tí bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ àti àwọn Adélé sì ti ń ṣiṣẹ́ lè lórí láti ìgbà tí wọn ti ṣe ìbúra fún wọn ní ọjọ́ kejìlá oṣù Igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rìnlélógún.

Láìpẹ́, ìwòsàn ọ̀fẹ́ yóò kárí Ìpínlẹ̀ méjèèje, fún gbogbo  àwa ọmọ I. Y. P láṣẹ Èdùmàrè. Ẹ jẹ́ ká gbárùkù ti oore tí Olódùmarè ṣe fún wa ní Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y ), nípasẹ̀ màmá wá Modupẹọla Onitiri-Abiọla, ìyá ìrọ̀rùn ló bá dé.

Democratic republic of the Yoruba is no longer part oƒnigeria. Anyone counting the 7 states of the yoruba nation with nigeria is committing a crime. Indigenous yoruba people should be warned!