Ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ ìgbà ni a ti gbọ́ l’ati ẹnu Màmá, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, nípa Àgbéka’lẹ̀ (tí a tún le pè ní Àlàka’lẹ̀) fún Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on XẸlòmíràn nínú wa lè máa rò wípé, Èwo tún ni “blueprint”? Nít’orí bóyá a ò gbọ rí wípé nkankan wà t’ó tún njẹ́ “Blueprint” (tàbí, Àlàka’lẹ̀ Ìgbéka’lẹ̀) fún orílẹ̀-èdè. Ní òtítọ́ àti ní òdodo, bóyá ni a ṣe rí orílẹ̀-èdè, tàbí àwọn t’ó pe ‘ra wọn ní orílẹ̀-èdè, bí wọn kò ti’lẹ̀ jẹ́ orílẹ̀-èdè, tí kò ní Blueprint, yálà wọ́n kọọ́ sí’lẹ̀ tàbí wọn ò kọọ́ sí’lẹ̀. Yàlà gbogbo ará ìlú l’ó mà nípa Blueprint náà tàbí kìí ṣe gbogbo wọn.
Ka Ìròyìn: Ọmọ-Alade Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá Ṣe Àlàyé Nípa Ìbò Dídì Ní D.R.Y
Gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ; ìlú tí a ti kúrò l’ara rẹ̀, wọ́n ní blueprint t’ó dúró gìdìgbà, tí wọ́n sì ntẹ̀lé l’ojoojúmọ́! Àgbéka’lẹ̀ Oko-Ẹrú, tàbí Àlàka’lẹ̀ Oko-Ẹrú ni Blueprint tí wọ́n ntẹ̀ lé.
Blueprint (Àgbèka’lẹ̀ tàbí Àlàka’lẹ̀) yí jẹ́ ohun tí a npè ní “Orílẹ̀-Èdè” gan-an gan, tàbí “Ìṣe’jọbá àti Ìṣe’lú” Orílẹ̀-Èdè, tàbí “Ìlànà” tí A Kò Gbọdọ̀ Ya’nà Kúrò Nínú Rẹ̀; bíkòṣe bẹ́ẹ̀, Orílẹ̀-Èdè náà ti dà wó nìyẹn, bí wọ́n ti’lẹ̀ ṣì npe’ra wọn ní Orílẹ̀-Èdè.
Blueprint (Àgbéka’lẹ̀ Àlàka’lẹ̀) jẹ́ ohun àìgbọdọ̀máṣe, ohun tí a kò gbọ́dọ̀ yà kúrò nínú rẹ̀; bì kò ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ wípé gbogbo ohun tí a ti là kọ́já, l’ati ipele dé ipele, gbogbo ewu tí a ti là kọjá, gbogbo àìsùn tí a ti là kọjá, gbogbo inúnibíni tí a ti là kọjá; gbogbo àdúrà tí a ti gbà, àti gbogbo àkókò tí a ti lò, l’orí k’ó lè dáa, titi fi di àkókò náà tí a bá yà kúrò nínú Blueprint náà, á jẹ́ wípé gbogbo ẹ̀ ti di àṣedànù nìyẹn! K’á má ri!
Nít’orí èyí, ègún ni fún ìran náà, ègún ni fún ìlú náà, ègún ni fún orílẹ̀-èdè náà; tí ó bá yà kúrò nínú àgbéka’lẹ̀ àlàka’lẹ̀ tí wọ́n fi ṣe ìpìlẹ̀ orílẹ̀-èdè wọn – pàápàá bí ìran Yorùbá tí ó jẹ́ wípé tààrà l’ati ọ̀dọ̀ Olódùmarè, Ẹl’ẹdá wa, ni Àgbéka’lẹ̀ (Blueprint) yí ti wá!
Ka Ìròyìn: Ẹ̀kún Rẹ́rẹ́ Ọ̀rọ̀ Olórí Adelé Ní Àyájọ́ June 12
Kìí ṣe gbogbo Ìran tàbí Orílẹ̀-Èdè ni ó ní ànfààníi wípé kí ó jẹ́ wípé Olódùmarè fún’Ra ‘Ra ẹ̀ ni ó máa sọ blueprint (àgbéka’lẹ̀) ka’lẹ̀ fún wọn; ṣùgbọ́n a ní irúfẹ́ ànfààní yí gẹ́gẹ́bí ọmọ Yorùbá.
Bẹ́ẹ̀ ni àgbéka’lẹ̀ (blueprint) yí kìí ṣe ohun tí ẹnik’ẹ́ni ní ọjọ́ iwájú le dìde wípé a fẹ́ “modernise” ẹ̀ – èyíinì, wípé a fẹ́ẹ́ ṣeé ni ti “ìgbàl’odé” l’akókò k’akókò l’ọjọ́ ‘wájú! rárá!
Ka Ìròyìn: Ìyàtọ̀ Tí Ó Wà L’aárín June 12 Àti July 7
Blueprint (Àgbékalẹ̀ Ìlànà Fún Ìṣe Rere) jẹ́ ohun tí ó wà Títí Ayé!
A níl’áti mọ̀ wípé, l’ati ọ̀dọ̀ Olódùmarè fún’Ra ‘Ra ẹ̀ ni Blueprint Orílẹ̀-Èdè Yorùbá tí ó ti wá (èyí kò sì tú’mọ̀ sí wípé bóyá gbogbo orílẹ̀-èdè ni Blueprint wọn ti ọwọ́ Olódùmarè wá – Rárá o!), a rí àánú gbà ni!
Bẹ́ẹ̀ ni ẹnik’ẹ́ni kò tún le dìde ní’jọ́ iwàjú wípé òun náà ti gba Blueprint fún ọmọ Yorùbá, tàbí fún Orílẹ̀-Èdè Yorùbá, tí ó yàtọ̀ fún èyí tí Olódùmarè ti gbé fún wa yí! Kò gbọdọ̀ sí àfikún tàbí àyọkúrò tàbí oríṣi ìyípadà kankan rárá. Ohun tí ó jẹ́ wípé, l’ati ìran ìgbà dé ìran ìgbà ni a ó máa mu lé àrọ́’mọ d’ọmọ l’ọwọ́ ni; èyí ni ó tú’mọ̀ sí wípé a jẹ́ olóotọ́ sí Májẹ̀mú tí Olódùmarè bá wa da!
Èyí tú’mọ̀ sí wípé, Blueprint (Àgbéka’lẹ̀ Ìlànà) yí ni Májẹ̀mú tí Olódùmarè bá wa dá!
A nf’ojú s’ọnà de ọjọ́ náà tí Olódùmarè yíó ti ọwọ́ Ìránṣẹ́ Rẹ̀, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá gbé Blueprint (Àlàka’lẹ̀) yí lé wa l’ọwọ́.