Ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ ojúlówó Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá ni ó dà bí ẹni wípé ìrújú àwọn ọjọ́ méjì kan ṣì jẹ́ ìpèní’jà fún, ṣùgbọ́n tí a ní l’ati jẹ́ k’o yé wa dáradára. Àwọn ọjọ́ méjì yí ni ọjọ́ June 12 (tí ó sì jẹ́ ọjọ́ kéjìlá, oṣù kẹ́fà ní ọdún 1993), àti ọjọ́ July 7 (èyíinì, ọjọ́ kéje, oṣù kéje, ní ọdún 1998).
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on XÀwọn ọjọ́ méjì yí ni a níl’ati mọ ìyàtọ̀ wọn àti ohun tí wọ́n jẹ́.
Ọjọ́ June 12, ní ọdún 1993, ni ìlú Nigeria ṣe ìdìbò sí ipò ààrẹ l’ọjọ́ náà l’ọhún, èyí tí bàbá wa MKO Abíọ́lá já’wé olúb’orí ṣùgbọ́n ti àwọn ìjọba ol’ogun Nigeria nígbànáà, l’abẹ́ àkóso Babangida fa’gi lé ìdìbò náà. Èyí ni a ṣe àyájọ́ rẹ̀ ní àìpẹ́ yí. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á mọ èyí, wípé, June 12 ni ìdìbò yẹn wá’yé nígbànáà l’ọhún, tí MKO já’we olúbo’rí ṣùgbọ́n ti al’arékérekè nì, Babangida tí ó fa’gi lé ìdìbò náà, l’átàri wípé ọmọ Yorùbá l’ó já’wé olúborí. Ṣùgbọ́n kìí ṣe ọjọ́ náà ni wọ́n pa MKO.
Ka Ìròyìn: Ọmọ-Alade Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá Ṣe Àlàyé Nípa Ìbò Dídì Ní D.R.Y
L’ẹhìn ìgbàtí Babangida ti da ìbò náà sọ nù, ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ wàhálà l’ó wá’yé, gẹ́gẹ́bí a ti mọ̀; ṣùgbọ́n ní ìgbà t’ó pé ọdún kan (ní 1994) tí oríṣiríṣi wàhálà ṣì nlọ l’orí ọ̀rọ̀ náà, o dé ìkóríta kan tí ìjọba Nigeria wá mú bàbá wa MKO Abíọ́lá, sí ìhámọ́ àtìmọ́lé Nigeria, l’atàri wípé òun ni òun jẹ́ ààrẹ tí a yàn.
Ka Ìròyìn: Pàtàkì Àgbékalẹ̀ (Blueprint) Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá (D.R.Y)
Ní àkókò tí wọ́n fi mú wọn s’atìmọ́’lé yí, Babangida ti sún s’ẹgbẹ́ kan; ó ti fi Sónékàn sí’bẹ̀, tí òun kìí ṣe ol’ogun ní tirẹ̀, ṣùgbọ́n tí àwọn ará ìlú kò fẹ́ ní’wọ̀n ìgbà tí kìí ṣe òun ni wọ́n fi ìbò yàn; ṣùgbọ́n tí Ṣónékàn gan-an kò pẹ́ ní’bẹ̀ nígbatí Abacha ti léè kúrò l’orí oyè; nítorí èyí, Abacha gan-an l’ó mú bàbá wa sí àtìmọ́lé ní ọdún 1994 l’ẹhìn tí Babangida ti hu ìwà àṣìtáánì ti’rẹ̀ ní ọdún 1993 nígbàtí ó da ìbò yẹn nù.
Ka Ìròyìn: Ẹ̀kún Rẹ́rẹ́ Ọ̀rọ̀ Olórí Adelé Ní Àyájọ́ June 12
Èyí ni wípé, ìránṣẹ́ Sàtáánì, Babangídá da ìbò nù ní ọdún 1993 (ìbò tí a ṣe ní June 12 ọdún náà); tí ìránṣẹ́ Sàtáánì kéjì – èyíinì, Abacha – wá mú bàbá wa MKO sí àtìmọ́’lé ní ọdún 1994.
Àtìmọ́lé yí ni bàbá wa MKO wà títí di ọdún 1998 tí Abacha fún’ra rẹ̀ fi kú. Nígbàtí Abácha kú, bàbá wa MKO ṣì wà nínú àtìmọ́’lé yẹn. Àwọn ol’ogun wá fi Abdusalam Abubakar dí’pò Abacha gẹ́gẹ́bí ààrẹ Nigeria. Eyí tú’mọ̀ sí wípé, ní’gbà tí Abdusalam bọ́ sí pò, baba wa MKO ṣì wà ní àtìmọ́’lé; ó ti wá di bí ọdún mẹ́rin tí bàbá wa MKO ti wà ní àtìmọ́lé nígbà yẹ́n. L’abẹ́ àkóso Abdusalam ni wọ́n ti wá pa bàbá wa MKO! Wọ́n pa wọ́n ní July 7 1998.