Ọrọ̀-Ajé orílẹ̀-èdè dúró lórí àwọn ìpìlẹ̀ àti àwọn òpó kan. Lára àwọn òpó wọ̀nyí ni ìdíyelé owó-ìná orílẹ̀-èdè.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè tí kò ní ìlọsíwájú, lónìí ni ó jẹ́ pe, ọ̀kan gbòógì lára ìṣòro wọn ni àìníye-lórí òwó-ìná wọn. Èyí ni ó máa ń fa ọ̀wọ́n-gógó, nìtorí pé, owó gọbọi ní’ye kò ra ń kan tó pọ̀ lọ títí.
Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítirí-Abíọ́lá wá fi àṣírí kan hàn wá nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá wa sọ, nígbàtí wọ́n sọ̀rọ̀ dé’bi owó-ìná (currency) Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y). Wọ́n ní góòlù ni a máa fi ṣe ìdíwọ̀n owó-ìná D.R.Y
Góòlù jẹ́ ohun kan ní àgbáyé tí ìdíyelé rẹ̀ kìí sábà jás’okè-jásí’sàlẹ̀ bí ọkọ̀ tí ìjánu rẹ̀ ti bàjẹ́; iye tí ìwọ̀n góòlù kan bá jẹ́ lóni, kò níí fi tóbẹ́ẹ̀-jùbẹ́ẹ̀-lọ yàtọ̀ sí iye tí ó máa jẹ́ ní ọ̀la.
Orílẹ̀-èdè tí wọ́n bá ti gbé ìdíwọ̀n owó-ìná wọn lé àpáta tàbí ìpìlẹ̀ iye tí ó jẹ́ ní góòlù, sábà máa nń aní ètò ọ̀rọ̀-ajé tí kìí sí ọ̀wọ́n gógó tó kọjá ìfaradà, nítorí ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí góòlù nìkan náà ló lè ṣẹlẹ̀ sí’rú owó-ìná orílẹ̀-èdè náà.
Èyí yàtọ̀ sí ìrírí àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ pé owó-ìná orílẹ̀-èdè míràn ni owó-ìná orílẹ̀-èdè tiwọn gb’ara lé: tí aburú bá ti bá àwọn t’ọ̀ún, ó ti bá àwọn náà nìyẹn.
Èyí túmọ̀ sí pé, ní orílẹ̀-èdè wa, ìfọkàn-balẹ̀ wa pé, níwọ̀n ìgbàtí àwa gan-an kò bá ya ọ̀lẹ, ohun tí ó bá máa ṣẹlẹ̀ sí ìdíwọ̀n góòlù ní àgbáyé, tí èyí kò sì jẹ́ aburú láti àtẹ̀yìn wá, òun náà ni a le ní ìrètí rẹ̀ lórí ìdíyelé owó-ìná wa.
Màmá tún fi yé wa pé nígbà tí a bá bẹ̀rẹ̀ sí yí èyí tí ó wà lọ́wọ́ báyi, sí owó tiwa, kí á máṣe jẹ́ kí ó yà wá lẹ́nu pé, nínú òǹkà , ení, èjì, ẹ̀ta, òǹkà rẹ̀ kò ní tó ti tẹ́lẹ̀; ìdí èyí ni pé ìdíyelé owó wa ju ti èyí tí a gbé lọ́wọ́ tẹ́lẹ̀.
Wọ́n tilẹ̀ ṣe àpèjúwe kan fún’wa nígbà náà l’ọhún: wọ́n ní tí ohun tí a ní lọ́wọ́ báyi bá jẹ́ mílíọ̀nù kan, kí ó máṣe yà wá lẹ́nu pé pàṣípààrọ̀ rẹ̀ lè fún wa ní ẹgbẹ̀rún l’ọnà igba owó D.R.Y, tí ó túmọ̀ sí ìdámárun mílíọ̀nù èyí tí ó jẹ́ pé, ní òǹkà owó D.R.Y kan yóò ra ohun tí márùn-ún owó tí a gbé dání tẹ́lẹ̀ máa rà. Ó níye lórí ju ti tẹ́lẹ̀ ló ń jẹ́ bẹ́ẹ̀.
Ṣùgbọ́n, tí ó bá jẹ́ pé òǹkà mílíọ̀nù-mílíọ̀nù ní ó wu ẹni yẹn kí ó máa kà, bí mílíọ̀nù ọ̀ún kò tilẹ̀ leè ra’jà púpọ̀, ẹni náà lè lọ kó mílíọ̀nù rẹ̀ sí’bi tí àwọn tó ń ná owó yẹn nílu wọn ń ko sí, kí ó wá bẹ̀rẹ̀ síi ṣe iṣẹ́ tí áá fi lè kó owó D.R.Y tó níye lórí jọ, ní ilẹ̀ D.R.Y.
Gbogbo èyí túmọ̀ sí pé kò sí ìfòyà ní D.R.Y, lórí ìdíyelé tàbí ìwọ̀n owó-ìná orílẹ̀-èdè wa; àá mú ònkà kan lọ́wọ́ báyi, yóò sì jẹ́ owó gidi.