Dókítà kan tí orúko rẹ ń jé Zelenko, ní orí akéte àìsàn rẹ, ní o ti tú àwọn àṣírí kan nípa Bill Gates.
Arákùnrin náà sọ pé, lọ́wọ́ tí a wà yí, àjọ Alábòójútó Ìlera ní Àgbáyé (WHO) ti wá ń sa agbára tó pọ̀ báyi o, lórí orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni káàkiri àgbáyé, tí èyí sì ṣe kàyéfì fún’ni, nítorí pé ibi tí a bá ti júwe bíi aṣèjọba-ara-ẹni kò tún ní ọ̀gá kankan tó ń pàṣẹ fún ìlú náà.
Ṣùgbọ́n ṣe ni àwọn àjọ alábòójútó ìlera àgbáyé yí ń ṣe bí ẹni pé ọmọ-ọdọ̀ wọn ni àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri àgbáyé jẹ́; bẹ́ẹ̀ sì ni, Bill Gates ni onígbọ̀wọ́ wọn, òun ni olówó tó ń darí WHO pẹ̀lú owó rẹ̀. Ohun tó bá ti sọ fún wọn ni wọ́n máa ṣe.
Tí ó bá sọ pé àrùn kan ń bọ̀, WHO náà á sọ pé àrùn yẹn ń bọ̀! Bill Gates ni ọlọ́run wọn. Agbára owó lẹ ń wò yẹn! Ọ̀nà bí ó ṣe máa pa aláwọ̀dúdú run ni ó ń wá àti láti dín iye ènìyàn tí ó wà lágbayé kù.
Ó ṣe àpèjúwe Bill Gates bí alárùn-ọpọlọ tó kórira àwùjọ ọmọ ènìyàn. Òun ló máa ṣètò bí àrùn ṣe máa dà síta; òun náà ló máa sọ fún WHO kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí da ayé ríborìbo tórí àrùn tí olówó wọn, Bill Gates dà síta.
Arákùnrin náà tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ wípé ní nǹkan bíi oṣù mẹ́fà sẹ́yìn, Bill Gates sọ pé àrùn smallpox ṣì ń fún ayé ní ìpèníjà bẹ́ẹ̀ sì ni, smallpox jẹ́ àrùn tí ayé ti fì sẹ́hìn bí eégún ti ń fi’ṣọ láti okòó-dín-lẹ́gbàá ọdún! Ọjọ́ márun lẹ́yìn tí alárùn-ọpọlọ Bill Gates sọ ọ̀rọ̀ yí, ni wọ́n sọ pé àwọn rí igò tí kòkòrò smallpox wà ní ilé-iṣẹ́ ìwádi kan ní ìlú Philadelphia! Àjẹ́ ké lána, ọmọ kú lóni!
Ó wípé kò ya òun lẹ́nu bí wọ́n tún ṣe ń sọ̀rọ̀ MPOX báyìí . Ó ní ìyẹn ló kàn báyi tí wọ́n á tún fi máa da ayé ríborìbo, tí wọ́n á kó ìpá’yà fún àwọn èèyàn, tí wọn ò níí le dúró pẹ̀lú àwọn ẹni tí wọ́n fẹ́, látàrí kí onílé-gbé’lé, tí wọ́n á tún ní kí wọ́n máa di ìbo’mú òṣì kiri; àti dídá ẹ̀rù ba àwọn ènìyàn ní ibití ẹ̀rù kò sí, nítorípé àrùn àgbé’lérọ ni, bí wọ́n yóò ṣe máa gbé oríṣiríṣi wá nìyẹn, àfi ìgbà ti ọmọ ènìyàn bá pinu láti inú wá, pé, à ò gbà wọ́n láàyè mọ́!
Dókítà náà wípé, èròngbà ti òhun n’ipe, kí àwọn ará ìlú pinu lọkàn wọn, láti máṣe foríbalẹ̀ fún ọlọ́run tí kìí ṣe ọlọ́run – àwọn ọlọ́run bí ọlọ́run sáyẹ́nsì-òyìnbó, ọlọ́run ìmọ̀-èrọ, ọlọ́run-owó, ọlọ́run-ìṣèjọba-jẹgúdújẹrá; ọlọ́run agbára-ayé, ọlọ́run ká-ṣáà-ti-lókìkí! ṣùgbọ́n kí ènìyàn ṣe ohun tí Ẹlẹ́dàá fẹ́.
Orilẹ-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y) kò kúkú ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹni-ibi bíi Bill Gates, kò ní sí àyè fún ẹnikẹ́ni láti dààmú ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) pẹ̀lú òfin amúnisìn kankan, lórí ilẹ̀ Yorùbá!
Orílẹ̀-Èdẹ Aṣèjọba-Ara-Ẹni ni wá! A ò sí lábẹ́ ìjẹgàba WHO, tàbí orílẹ̀ èdè kankan lágbayé! Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítirí-Abíọ́lá, tilẹ̀ ti sọ fún wa pé àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) máa bí’mọ si ni! A ò ní dín. Kí á má sì ṣe gbàgbé, gẹ́gẹ́bí Màmá ṣe sọ fún wa pé, bíó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfẹ́ kò ní àlà; ṣùgbọ́n, síbẹ̀ á wu àwọn kó jẹ́ pé I.Y.P á fẹ́ I.Y.P, kí á lè máa bí ọmọ tó jẹ́ I.Y.P.