“Mò ń bínú sí ara ìlú” Kí ló gbé ọ̀rọ̀ yi jáde láti ẹnu Rotimi Amaechi, ẹni tó ti jẹ gómìnà àti minisita nìgbà kan rí? Bẹni a ń bi ní, nígbà tí àwọn ǹkan kàyèfi bá ń ṣẹlẹ̀.

Fọ́nrán kan lari lórí ẹ̀rọ ayélujára, nibẹ ni gómìnà yìí tí ń sọ ọkàn rẹ jáde fún àwọn tó bèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ. Òní òún bínú sí ará ìlù, nítorí pé, ṣe ló yẹ kí wọn bínú sí àwọn ọ̀jẹ̀lu, tí wọn pera wọn ní òṣèlú tí òun náà sí jẹ́ ọ̀kan nínú wọn.

Torí wọn rí àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ kan tí ń jà wọn ní olè, tí wọn sọ wọn di òtòṣì, akúsẹ, aláìní, tí wọn kò lè rà àwọn ǹkan tí wọ́n nílò, tí wọn ó lè jẹun, àbí ra àwọn ǹkan tí ó ṣe pàtàkì fún ìlú wọn, bẹni wọn dákẹ.  

Dípò kí wọn faraya, kí wọn sọ pé kò sí ìbò kankan ní Ìpínlẹ̀ yí. Se ni wọn sún un.

Ǹjẹ́ èyí kò bá àwa ọmọ aládé wí bí, nígbà tí a rí àwọn ọ̀jẹ̀lù wọ̀nyí pẹ̀lú ìwà olè jagudà àti jẹgúdújẹrá. lgba náà ni àwọn ọdọ tí ò bìkítà fún ọjọ́ ọ̀la wọn àti àwọn bàbà kan tó fẹ́ jẹ ayé ọmọ mọ́ ti wọn. Wọn wá ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ́ ntò sí ẹyin àwọn onímọ̀ tara ẹni nìkan wọ̀nyí, nítorí ikùn tí wọn nìkan. Ojú wa tìwọ́n ni gbẹ́yìn, nitori ebi tí pá wọ́n lẹ́nu mọ́.

Ṣe màmá MOA ò sọ fún àwa ọmọ Yorùbá ni pé ǹkan tó ún bọ̀ ẹ̀mí wa ò lè gbe? nítorí, inú ìyà mirán ni a tún má kò si. Ebi, ìṣẹ́, òṣì ti dé bá gbogbo ènìyàn báyìí. Àwọn olówò náà tí ni ìmọ̀lára ohun tó wà níta nísìyín. Gbogbo nkan ló ti gbé owó leri kọjá ààlà. Àìgbọràn ló má ń ṣekú pani.

Tó bá jẹ́ wí pé a fọwọ́ so wọ́pọ̀ pẹlu màmá Ìyá Ààfin Modupeọla Onitiri-Abiọla nígbà tí wọ́n gbé olórí Adélé wọlé ní ìlú lbadan ni ọjọ́ kejìlá oṣù igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rìnlélógún ni, a ó bà wà nínú ọ̀pọ̀ báyìí.

Ṣùgbọ́n a dupẹ lọ́wọ́ Olódùmarè pé ó bà nikò baajẹ̀. Ànfààní míràn tún ti ńkan lẹkun lọ́wọ́ bayi. Òun náà ni àjọyọ̀ tí ó ńbọ̀ lọ́nà, èyí tó má gbé àwọn Adélé wọlé sí orikò ilé isẹ ìjọba ni Ìpínlẹ̀ méjèèje tí ó wà ní Orílẹ̀ èdè Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y). Kí wọn sì tẹsiwaju ìṣejọba-ara-ẹni lẹkùnrẹrẹ ni gbogbo orikò ilé iṣẹ́ ìjọba.

Nísíiyí, ṣe ni ká múra gidi láti ṣe àjọyọ̀. Ká sọ fún ará ilé, kí ará ilé sọ fún t’oko nípa àjọyọ̀ Òmìnira Tiwantiwa tí Yorùbá tó ti dé tán. lbukun ni fún Orílẹ̀ èdè àwa ọmọ aládé. Kò sí òṣì àti iṣẹ̀ mọ́ láṣẹ Èdùmàrè.

Gbogbo àwa ọmọ aládé fi ìmore wa hàn fún màmá wa Modupeọla Onitiri-Abiọla tí Ọlọ́run Olódùmarè lò láti ṣe ágbátẹrù Orílẹ̀ èdè wa (D.R.Y).

Yoruba has always been a country; now we've restored our Nationhood by the help of Olódùmarè