ÌKÌLỌ̀ FÚN GBOGBO Ẹ̀YIN ÀGBẸ̀

Ẹ má ṣe gba irúgbìn GMO lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, ọ̀nà míràn láti pa àwa aláwọ̀ dúdú run ni, àìsàn oríṣiríṣi ni irúgbìn yí yóò fà sí àgọ́ ara ẹnití ó bá jẹẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹni náà kò ní leè bí ọmọ mọ́, àti wípé, ilẹ̀ tí wọ́n bá gbin irúgbìn yí sí yóò di aṣálẹ̀ tí kò sì ní leè mú èso jáde mọ́.

Fún ìdí èyí, ẹni tí ọwọ́ ìjọba Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá bá tẹ̀, ẹ̀sùn ìpànìyàn ni ò. Nítorí náà, a rọ gbogbo ẹ̀yin Indigenous Yoruba People (I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) wípé, ibikíbi tí ẹ bá ti rí ẹni tí ó bá gba irúgbìn yí tàbí ẹni tí ó fún wọn, ẹ bá wa ya àwòrán wọn, àti ẹni tí ó fún wọn, àti ẹni tí ó gbáà, apànìyàn ni àwọn méjèèjì. Ẹ tọ́jú àwọn irúgbìn àbáláyé tó wà lọ́wọ́ yín.

Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), kò sí ẹni tí kò ní gbádùn àlàkalẹ̀ ètò ìṣèjọba tí Olódùmarè fún màmá wa, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, pàápàá jù lọ àwọn ọmọdé.

Ètò ti wà nílẹ̀ lorísìírísìí fún ìgbá’yé gbádùn àwọn ọmọdé. Bí wọ́n bá ti ń gbà ìtọ́jú ni ẹ̀ka ti ìlera, bẹ́ẹ̀ náà ni wọn yóò máa gbádùn àwọn ohun am’áyédẹrùn ti ìgbàlódé lọ́kan-ò-jọ̀kan.

Kò sí òbí tí kò ní rí oúnjẹ tó dára fún àwọn ọmọ, nítorí oúnjẹ yóò wà lọ́pọ̀ yanturu ní orílẹ̀ èdè D.R.Y. Àwọn oúnjẹ tó dára, tí yóò mú ọpọlọ ọmọdé jí pépé ni wọn yóò máa jẹ.

Ní ìgbà dé ìgbà ni wọn yóò máa ṣe ayẹwo ni ilé ìwòsàn láti mọ bí wọ́n ṣe ń dàgbà sí àti láti ríi dájú pé àìsàn kankan kò rí ààyè ní àgọ́ ara wọn.

Nítorí náà, a kí àwa ọmọ Aládé pé, a kú oríire, a sì kú ìmúrasílẹ̀ fún àjọyọ̀ Orílẹ̀ èdè wa tó tuntun jùlọ ní àgbáyé.