Bill Gates ni a rí nínú fọ́nrán kan lórí ayélujára X, ìkànnì @wideawake_media, níbi tí wọ́n ti ń fi ọ̀rọ̀ wáa lẹ́nu wò lórí nǹkan tó ní òun ń ṣe nípa àtúnṣe àti àtúntò ojú-ọjọ́, gẹ́gẹ́ bíi èròǹgbà rẹ̀ láti ba ètò ìṣẹ̀dá àsìkò jẹ́.

Ìránṣẹ́-àṣìtááni Bill Gates yí dáhùn pé, ẹni tó bá fi’yèsí igi gbígbìn gẹ́gẹ́bí ìdáhùn sí àtúnṣe ojú ọjọ́, èyí tí Olódùmarè dá láti ìgbà ìṣẹ̀dá, ó ní ẹni nàà ti sọ ọpọlọ rẹ̀ nù.

Aṣójú àṣìtánì gbáà ni Bill Gates yìí, nítorípé, ó ń ṣe lòdì sí iṣẹ́ ọwọ́ Olódùmarè. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn káàkiri àgbáyé sọ pé gbogbo kùrùkẹrẹ Bill Gates láti máa tẹ ọwọ́ bọ ojú sánmọ̀ jẹ́ ìkọjá-àyè, àti pé igi gbígbìn kájú gbogbo nǹkan tí Bill Gates sọ pé ó ń ṣe ojú ọjọ́.

Èyí jẹ́ nkan tí olùfọ̀rọ̀-wá’ni-lẹ́nu-wò náà sọ fún ẹni-ibi Bill Gates, ṣùgbọ́n ṣe ni ìránṣẹ́-àṣìtáánì náà gbé ìgbéraga wọ̀, tó bu ẹnu àtẹ́ lu ẹni  tó bá sọ pé igi gbígbìn kájú nkan tí aṣiwèrè rẹ̀ ń sọ.

Ìránṣẹ́ àṣìtánì tí wọn ń pè ní Bill Gate yìí ṣá fẹ́ pa ènìyàn, pàápàá kí ó pa gbogbo ìran aláwọ̀ dúdú run; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kò ní máa sọ ìsọkúsọ látẹ́nu rẹ̀. Ilẹ̀ adúláwọ̀ náà ló ní oríṣiríṣi igi.

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates 30/09/2024

Gbogbo àlàkalẹ̀ ìṣèjọba àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) kò ní fààyè gba àbá, ìmọ̀ràn tàbí èròǹgbà  ìlú kankan lórí Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y, yàtọ̀ sí èyí tí Olódùmarè ti gbé fún wa nípasẹ̀ ìránṣẹ́ Rẹ̀, Ìyá wa, MOA. Ajíṣe bí Yorùbá làárí, Yorùbá kìí ṣe bí ẹnì kankan. 

Ọpẹ́ ni kí á máa dá lọ́wọ́ Olódùmarè fún Màmá Wa, Ìyá Ìran Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọlá, fún iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ti ṣe, tí wọ́n sì ń ṣe fún ìtẹ̀síwájú Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y).

Látàrí àṣeyọrí Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), ìrètí wà pé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìlú aláwọ̀dúdú yóò kọ́ ẹ̀kọ́ lára wa. 

Nínú fọ́nrán náà, a ríi pé ẹni tó ń bá Bill Gates sọ̀rọ̀ yí, ṣe bí ẹni  tó mọ̀ pàtàkì igi gbígbìn fún ojú ọjọ́.

Kí gbogbo Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), fọwọ́-sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Ìjọba Adelé wa fún ìpìlẹ̀ rere èyí tí a ń tọ̀, tí yóò fihàn gbangba pé àwa mọ rírì àyíká  tó dára. Kí Oluwa kí ó bùkún orílẹ̀-èdè wa, D.R.Y.