Ọjọ́-burúkú, àṣìtáánì gbomimu, gẹ́gẹ́bí a ṣe máa ngbọ́, ni a lè fi ṣàkàwé ọjọ́ náà, Ọjọ́’Rú, ọjọ́ kéjìdínlógún, oṣù ọ̀pẹ, ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún.
Ṣùgbọ́n ní tiwa, ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ọjọ́ tí Èdùmàrè dá ni-ì, àṣìtáánì kàn ngbógun ni-ì, kò leè borí wa.
Gbogbo wa ni a ti gbọ́ nkan tó ṣẹlẹ̀, tí Màmá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin) sì ti bá wa sọ̀rọ̀ le lórí.
Ọ̀rọ̀ àwọn ọmọdé márun-dín-lógójì tí wọ́n kú níbi ìrọ́gììrì-èrò tí ó ṣẹlẹ̀ ní olú-ìlú Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ni-ì; níbití Naomi, ìyàwó Ẹniìtàn Ògúnwùsì tẹ́lẹ̀ rí (èyí tí ó pe ara rẹ̀ ní àrólé ní Ilé-Ifẹ̀) àti Oríyọmí Hamzat, sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ kan ní Ìlú Ìbàdàn, ti sọ pé àwọn máa fún ẹgbẹ̀rún márun àwọn ọmọdé ní onjẹ-ọ̀fẹ́ àti àwọn ohun míràn.
Àbálọ-àbábọ̀, àwọn ọmọ márun-dínlógójì ṣe alábapàdé ikú.
Ìròyìn kan tí ó wá tẹ̀ wá lọ́wọ́, tí akọ̀ròyìn kan, Festus Adédayọ̀, kọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ni a wá rí o, tí a wá gbé ìròyìn náà wò, ni a bá sọ pé kí á mú àwọn nkankan jáde wá fún ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) láti inú inkan tí akọròyìn náà kọ.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ọ̀nà tí Festus Adédayọ̀ fi gbé ọ̀rọ̀ náà kalẹ̀, ó jẹ́ èyí tí ó ka ilẹ̀ Yorùbá mọ́ ètò-amúnisìn tí wọ́n npè ní nàìjíríà (ìyẹn sì jẹ́ ọ̀ràn-dídá, ṣùgbọ́n ìyẹn tì kọ́ ni ó wà lójú ọpọ́n báyi), ìṣẹ̀lẹ̀ aburú yí, àti àwọn ohun tí Festus Adédayọ̀ kọ lórí rẹ̀, ni a fẹ́ gbé yẹ̀wò níwájú ọmọ Yorùbá, ní àkókò yí.
Gẹ́gẹ́bí akọròyìn náà ṣe sọ, àṣé ọmọ jòjòló tí kòì tíì pé ọ̀sẹ̀-kan láyé tilẹ̀ wà lára àwọn ọmọ tó kú náà!
Kíni ká ti ṣe eléyi sí? Ọmọ ọjọ́-márun péré ni ọmọ náà! Islamic High School, Baṣọ̀run ni àwọn tó pe èrò wá jẹun yí, fi ìpàdé sí. Wọ́n ṣe ìpolówó ètò náà gẹ́gẹ́bí ohun tó máa jẹ́ àgbàyanu.
Àwa ò wá mọ̀ bí ohun tí ó jẹ́ pé ebi tí ó wà ní ìlú ló fàá, bí ó ṣe wá jẹ́ ohun tí a npolówó ẹ̀ bíi pé nṣe ni a fẹ́ ṣí ilé-iṣẹ́ kan.
Ìyá ọmọ-jòlòló yí gbọ́ nípa ètò onjẹ ọ̀fẹ́ yí, ló bá gbéra, ó lọ síbẹ̀ pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.
A gbọ́ pé, ní aago-márun ìdájí pàápàá, ibẹ̀ ti kún fún èrò.
Akọ̀ròyìn Adédayọ̀ sọ pé àwọn kan tilẹ̀ ti nbéèrè, báyi, pé àbí àwọn ẹni ìkà kan ni wọ́n sà sí Naomi àti Hamzat ni?
Àwa lérò pé tó bá jẹ́ pé àwọn tí ó gbé ètò yí kalẹ̀ jẹ́ ẹni tí ó f’ara mọ́ D.R.Y ni, tàbí, bí wọn ò tilẹ̀ fara mọ́ D.R.Y, ṣùgbọ́n tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún ìṣàkóso-ara-ẹni D.R.Y, wọn ìbá mọ̀ pé a npe àwọn ènìyàn láti wá jẹ onjẹ-ọ̀fẹ́ níbikíbi ní D.R.Y, kọ́ ni ó kàn, báyi!
Akọ̀ròyìn náà wá sọ gbólóhùn kan tí ó gbẹ́nu lé pé, tí Naomi àti Hamzat bá jàjà bọ́ ní ọ̀rọ̀ yí.., ṣùgbọ́n àwa ò rí jàjàbọ́ ní ọ̀ràn wọn o, nítorí ní orí ilẹ̀ D.R.Y ni wọ́n ti ṣe ohun tí wọ́n ṣe, tí ó sì wá fa ikú òjì-dín-ní-márun ọmọdé, ní àkókò tí ìṣàkóso-adelé D.R.Y tilẹ̀ ti sọ pé kò sí nkan tó njẹ́ “ẹgbẹ́” ní D.R.Y, torí lábẹ́ ẹgbẹ́ kan, orúkọ ìyówù kó máa jẹ́, ni wọ́n ṣáà ti pète-pèrò inkan tó lọ wá fa ikú àwọn ọmọ wọ̀nyí.
Akọròyìn yí wá sọ ọ̀rọ̀ kan o! Ó ní àwọn èèyàn máa nsọ pé irúfẹ́ ìkó-èrò-jọ báyi, tí ó lọ́wọ́ kí wọ́n kó àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé jọ, ó lọ́wọ́ ẹbọ nínú àti pé ó ní-nkan tí wọ́n fi nṣe!
Akọròyìn yí wá sọ pé BÓYÁ àwọn ọ̀tá Naomi láti ààfin Ilé-Ifẹ̀ (D.R.Y kò ní ọba o!) – ó ní pé bóyá àwọn yẹn, pẹ̀lú àwọn ọ̀tá Hamzat ni wọ́n pàdí àpò pọ̀ láti fa ìsàsí fún àwọn méjèèjì ọ̀ún?!
Ẹ máṣe jẹ́ kí á gbàgbé obìnrin tí ọmọ tirẹ̀ kò tilẹ̀ tíì pé ọ̀sẹ̀ kan o! Akọròyìn yí sọ pé nígbàtí obìnrin náà dé Baṣọ̀run, èrò tí ó bá níbẹ̀ kọjá èyíkéyi tí ó rí rí ní ìgbésí ayé rẹ̀!
Ó ti wá lé ní oṣù mẹ́jọ, báyi o, tí ìṣàkóso-adelé Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) ti wà ní ìkàlẹ̀ o, tí wọ́n sì nbá iṣẹ́ lọ gidi, ṣùgbọ́n tí àwọn agbésùnmọ̀mí ajẹgàba nàìjíríà dúró sínú sẹkitéríátì wa, tí wọn ò jáde, tí àwa sì ntọpasẹ̀ àlááfíà, tí a sì mọ̀ pé Olódùmarè ti fún wa ní ìṣẹ́gun.
Tí àwọn ajẹgàba wọ̀nyí bá ti kúrò ni, kò sí nkan tí ìbá fa kí ẹnìkan sọ pé kí I.Y.P ti D.R.Y ó wá sí ibikan láti wá gba onjẹ ọ̀fẹ́ – èèwọ̀! Obìnrin ọlọ́mọ-jòjòló yí kì bá má ti lọ máa wá ohun àtijẹ fún òun àti ọmọ rẹ̀, lọ sí ibi tí ẹnìkan ti sọ pé òun fẹ́ pín onjẹ! – torí kò sí ẹnikẹ́ni tí ó máa máà ṣe ìtọrẹ kankan fún I.Y.P tí àwọn ìṣàkóso-adelé wa bá ti wọlé sí sẹkitéríátì – ìbáà ṣe ìtọrẹ-àánú tàbí ìtọrẹ-ẹbọ!
Àsẹ̀yìn wá, àsẹ̀yìn-bọ̀, ọmọ jòjòló tí wọn kò tilẹ̀ tíì ṣe ìsọmọlórúkọ̀ rẹ̀ yí, di èrò-ọ̀run látàrí pé wọ́n tẹ̀ẹ́ mọ́lẹ̀ pa níbi tí wọ́n lọ láti lè gba onjẹ ọ̀fẹ́.
Ẹjẹ̀ ọmọ jòjòló yí máa lé ìwọ Ṣèyí Mákindé jáde kúrò nínú sẹkitéríátì wa; bẹ́ẹ̀ ni ó máa lé ìwọ Jídé Sanwó-Olú, ìwọ Adémọ́lá Adélékè, Dàpọ̀ Abíọ́dún, Oyèbánjí, Ayédatiwa, Ododo àti AbdulRahman AbdulRazaq. Ìgbóná-ọkàn máa jẹ́ ti yín! Olódùmarè á wo ikú-oró, ikú-ebi, tí àwọn ọmọdé wọ̀nyí kú, á wòó, á fi ṣe ìdájọ́ yín, ẹ sì máa jáde kúrò ni gbogbo ilé-iṣẹ́ ìṣàkóso D.R.Y ní àìpẹ́ yí.
Akọròyìn náa tilẹ̀ sọ pé wọ́n ní ẹnu-‘bodè ilé-ìwé náà ni àwọn kan sùn sí, mọ́’jú, látàrí kí wọ́n le rí onjẹ ọ̀fẹ́! Báyi lẹẹ sọ ọmọ Yorùbá dà!? Ẹ ò ní kúure!
Wọ́n ní àwọn tí ó gbé ètò náà kalẹ̀ nṣe àwáwí pé ẹgbẹ̀rún márun àwọn ọmọdé ni àwọn ní ìrètí pé ó máa wá, ṣùgbọ́n ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bíi ìlọ́po méjì tí ó wá, pẹ̀lú òbí bákan-náà.
Ẹ jọ̀wọ́, ẹ bá wa béèrè lọ́wọ́ òpònú wọn, pé, nígbà tí ẹ ní kí ẹgbẹ̀rún márun ọmọ ó wá, ṣé àwọn ẹgbẹ̀rún márun yẹn mọ ara wọn rí ni, tàbí agbo-ilé kan-náà ní wọn ti mbọ̀, tí wọ́n á fi mọ̀ pé àwọn ti pé ẹgbẹ̀rún márun o, kí ẹnikẹ́ni máṣe tún tẹ̀lé àwọn mọ́? Irúfẹ́ ọ̀rọ̀ rírùn yí láti ẹnu àwọn tí ó gbé ètò náà kalẹ̀, fi hàn gbangba pé wọn ò tilẹ̀ ní ọpọlọ ẹni tí ó yẹ kí ó dáwọ́ lé ohunkóhun tí ó máa kó èrò jọ, bí kò tilẹ̀ ṣe ti elébi dé.
Akọròyìn náà wá sọ pé, tí a bá fàá síbí fàá sọ́hun, Tinubú ni òun rí báwí fún ikú àwọn ọmọdé wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n, ní ti wa, àwa I.Y.P ti D.R.Y, ọ̀nà méjì ni gbólóhùn yẹn, láti ẹnu akọròyìn náà, tí ó pín sí.
Èkíní ni pé, ó npe ilẹ̀ Yorùbá ní ara nàìjíríà, ló fi sọ bẹ́ẹ̀: Festus Adédayọ̀, mọ̀ o, pé ọ̀ràn-dídá, lábẹ́ òfin Democratic Republic of the Yoruba, àti ní àgbáyé pàápàá, ni kí o máa ka ilẹ̀ Yorùbá (D.R.Y) mọ́ ara Nàìjíríà!
Ṣùgbọ́n ní ti àwa I.Y.P ti D.R.Y, tí Tinubú bá ti sọ fún àwọn gómìnà ètò-amúnisìn tó njẹ́ nàìjíríà pé òun ò rán wọn níṣẹ́ o, àti pé kí wọ́n ṣe kíá kúrò lórí ilẹ̀ D.R.Y, ṣé àwọn gómìnà wọ̀nyẹn á ṣì máa ṣe agídí ni?
Látàrí èyí, Tinubú, ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ tí ìjẹgàbá Nàìjíríà sí orí ilẹ̀ D.R.Y yí, tí ó ṣe’kú pa, ẹ̀jẹ̀ wọn wà ní ọrùn ẹ bákannáà, o sì máa ṣègbé ni.