Òní, ọjọ́ kéjìlá, oṣù ògún, ni àyájọ́ ọjọ́ Àwọn Ọ̀dọ́ káàkiri Àgbáyé; Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá sì kí gbogbo àwọn Ọ̀dọ́ wa, Ọ̀dọ́ Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, ní àkókò yí; a kí wa pé a kú àtẹ̀mọ́ra, àti pé, ìgbà díẹ̀ ló kù o, tí ìjọba wa máa wọlé sí àwọn oríkò ilé-iṣẹ́ Ìjọba wa gbogbo, káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ wa méjèèje ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.
Ẹ jẹ́ kí á rántí ibi tí a ti mbọ̀ o! Àfi bí àná lórí, níjọ́ náà lọ́hun, tí Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá sọ pé kí mílíọ̀nù márun ọmọ Yorùbá fí ọwọ́ sí jíjáde kúrò ní Nàìjíríà. A mà ṣeé nígbà náà, ó mà bọ́ siì.
Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe ìkéde Òmìnira wa ní ogúnjọ́ oṣù bélú ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún; a mà ṣé, ó mà bọ́ si, tó fi jẹ́ pé àjọ àgbáyé pàápàá sọ fún wa kí a wá kópa nínú ìpàdé ọdọọdún àjọ náà ní ó ku díẹ̀ kó pé ọdún kan báyi.
A mà lọ kópa nínú ìpàdé náà, ó mà yẹ́ wá, bẹ́ẹ̀ ni a tún ti ṣe Ìpolongo Ìṣèjọba-Ara-Ẹni Orílẹ̀-Èdè wa ní ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rìnlélógún tí a wà nínú rẹ̀ yí, a dẹ̀ ti ṣe ìbúra-wọlé fún Olórí Ìjọba-Adelé wa, bẹ́ẹ̀ náà ni, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi, orukọ Olórí Ìjọba-Adelé wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọla Ọmọ́kọrẹ́, ti wà níwájú àjọ àgbáyé, pé àwọn ni Olórí Ìjọba Adelé Orílẹ̀-Èdè Yorùbá; a mà nṣeé, nípele, nípele, ó mà nyẹ wá; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀tá ntọ̀ sára, wọ́n sì nṣe oríṣiríṣi láti dúró sórí ilẹ̀ tí kìí ṣe tiwọn, ṣùgbọ́n Olódùmarè tí ó fún wa ní ìṣẹ́gun dé ibi tí a wà lóni, ni ó máa báwa ṣí wọn ní ìdí kúrò lórí ilẹ̀ wa, ní àìpẹ́, àìjìnà, pẹ̀lú gbogbo ìgbésẹ̀ tí Màmá wa ngbé, àti ìjọba wa.
Gẹ́gẹ́bí ọ̀dọ́, ẹ jẹ́ kí a ránti pé Ìránṣẹ́ Olódùmarè sí Ìran Yorùbá ti sọ pé Ọ̀dọ́ máa rí ògo wọn lò ní ilẹ̀ D.R.Y, bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo ọmọ Yorùbá.
Gbogbo ẹni tí ó jẹ́ akẹ́kọ nínú àwọn ọ̀dọ́ wa, tàbí tí ó fẹ́ padà sílé ẹ̀kọ́, ẹ rántí pé kò sí owó tí ẹ máa san o, títí dé ipele àkọ́gboyè kíní ni fásitì.
Njẹ́ a ti fi orúkọ wa sílẹ̀ bí ní ilé-iṣẹ́ ayélujára Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá? Gbogbo ọ̀dọ́, ẹ má ṣe gbẹ́hìn nínú eléyí; kí ẹ sì sọ fún àwọn tí kìí ṣe ọ̀dọ́ pàápàá, nítorí fún gbogbo ọmọ Yorùbá ni.
Gbogbo ọ̀dọ́ tí wọ́n fẹ́ dá iṣẹ́ sílẹ̀, tàbí tí wọ́n ti ní iṣẹ́ tí wọ́n nṣe, tó jẹ́ pé ìlú agbésùnmọ̀mí tí ó fa aìríṣe dáadáa dẹ̀ máa kúrò lórí ilẹ̀ wa ní àìpẹ́ yí, ẹ má gbàgbé láti ṣe àkójọ gbogbo ètò yín fún iṣẹ́ tí ẹ fẹ́ ṣe.
Gbogbo ẹni tí ó máa nílò ìrànlọ́wọ́ ìjọba D.R.Y láti bẹ̀rẹ̀ òwò tàbí ilé-iṣẹ́ wọn, ẹ máṣe gbàgbé láti fi fídíò nípa ìrànlọ́wọ́ tí ẹ fẹ́ ṣọwọ́ sí ibi tí wọ́n ti sọ fún wa kí á fi ṣọwọ́ sí.
Gbogbo ọ̀dọ́, orí-iré yí á kalẹ́ o; kí a má sì ṣe gbàgbé àti máa múra sílẹ̀ fún ajọyọ̀ wa nígbàtí ìjọba wa bá wọlé sí oríkò ilé-iṣẹ́ ìjọba, lẹ́hìn tí a bá ti rẹ́hìn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà.
Àṣèyí-ṣàmọ́dún o.