Ẹ̀yin òbí, ẹ bójútó àwọn ọmọ yín gidigidi o, kí ẹ sì máa kì wọ́n nílọ̀ dáadáa. Ṣèbí òwe Yorùbá kan ní ó sọ pé, ẹní bímọ ọ̀ràn níí pọ̀n-ọ́n.
Ọ̀rọ̀ yí dá lórí ìròyìn kan tí a gbọ́ pé, ọkàn lára àwọn olè tí ó ń fipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa ní ìpínlẹ̀ Ibadan ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá, èyíinì Seyi Makinde ni ó ti fi ìkànnì ẹ̀rọ ayélujára kan lọ́lẹ̀ báyìí ìyẹn WhatsApp láti kó àwọn ènìyàn jọ látàrí èróńgbà rẹ̀ láti díje fún ipò ààrẹ ní ẹgbàáọdún ó lé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n.
Ẹ bá wa béèrè lọ́wọ́ Seyi Makinde pé ààrẹ tibo níbẹ̀? Bóyá ààrẹ àwọn ẹlẹ́wọ̀n ni ṣá.
À bí ẹ ò rí ẹni tí kò ní d’ọ̀la tó ń dá ìparí oṣù, Seyi Makinde, o ṣáà ń fi ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ lójoojúmọ́ ni, díẹ̀ kékeré báyìí ló kù fún gbogbo yin, ọgbọ́n àti túbọ̀ máa tàn àwọn ènìyàn jẹ náà ni, nítorí pé gbogbo yín náà ló mọ̀ pé ó ti tán fún yín, aj’ègbodò ni yín, tó ń w’ẹ́ni kúnra ni.
Nítorí náà, gbogbo ẹ̀yin ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, ẹ kíyèsára gidigidi, tí ẹ bá ti bá ara yín ní orí ìkànnì tí ẹ kò mọ̀, ẹ tètè yọ ara yín kúrò lẹ́yẹ ò sọkà, kí ẹ má sì jẹ́kí wọ́n kó orí burúkú tiwọn báayín rárá, kí ẹ̀yin òbí náà sì túbọ̀ máa fa àwọn ọmọ yín létí nítorí pé èyíkéyìí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá tí ó bá ń tẹ̀lé àwọn olè yí, ajẹ́ pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń ṣe àtakò ìjọba Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá nìyẹn tí oníkálukú yóò sì gba ìdájọ́ tìrẹ nígbà tí ó bá yá.
Fún ìdí èyí, ẹ jẹ́ kí a lọ ní sùúrù, ìgbà díẹ̀ náà lókù fún wa báyìí, a ti dé ibi àṣeyọrí wa tán, ẹ má jẹ́kí a kánjú rárá, kò sí ohun rere kan tí ó wà nínú ìlú àwọn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà.
Àwa ti jáde kúrò lára wọn láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún tí a sì ti ṣebúra fún olórí Adelé wa, Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún.
Nítorí náà, Seyi Makinde, jáde kúrò lórí ilẹ̀ wa, a kò sí lára Nàìjíríà yín mọ́.