Láìsí àní-àní, orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) ti dúró, Olódùmarè ti fún wa ní òmìnira nípasẹ̀ màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún bẹ́ẹ̀ni a ti ṣe ìbúra wọlé fún olórí adelé wá bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún.
Nítorí náà, orílẹ̀ èdè aṣẹ̀jọba ara ẹni ni wá,aò ní sí lábẹ́ orílẹ̀ èdè kankan tàbí àjọ kankan láti máa dárí wa sí ọ̀nà tí kò tọ́, ìjọba D.R.Y kò sì ní gba ìgbàkugbà tàbí tẹríba fún àwọn tí wọ́n pe’ra wọn ní alágbára àgbáyé láti ṣe lòdì sí àwa ọmọ Yorùbá.
Gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe máa ń sọ fún wa wípé lẹ́yìn Ọlọ́run Olódùmarè, Yorùbá ni àkọ́kọ́.
Nítorí náà, àwọn ìjọba D.R.Y kò ní gbà’bọ̀dè fún ọmọ Yorùbá láti tún dá wa padà sí abẹ́ àwọn amúnisìn.
Ohun gbogbo tí a nílò gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè ni Olódùmarè ti pèsè fún wa, fún ìdí èyí a ò nílò láti gba àṣẹ lọ́wọ́ orílẹ̀ èdè kankan kí a tó leè ṣe ohunkóhun.