Aò ní ríbi nílẹ̀ yí, ó d’òkèèrè! Ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ ni ìlú Ìlarè-Ìjẹ̀ṣà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun o, níbi tí ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kusibẹ ti ṣe’kú pa bàbá-bàbá rẹ̀ látàrí èmi ni mo ni oko, rárá ìwọ kọ́, ti tèmi ni.

❗PÀJÁWÌRÌ FÚN ÀÀBÒ❗KÁÀKIRI GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ YORÙBÁ TÍTÍ DÉ OLD Ọ̀YỌ́ EMPIRE, Ẹ MÁA YA FỌ́TÒ FÚLÀNÍ, OLỌ́PA, OLÓṢÈLÚ, SÓJÀ, TÍ Ẹ BÁ FURA SÍ ÌRÌN ÀTI ÌṢESÍ WỌN NÍ AGBÈGBÈ YÍN. KÍ Ẹ FI ṢỌWỌ́ SÍ BÀBÁ ÌJÌNLẸ̀ +905367341665 (WHATSAPP). (ÌKÉDE… Pín Sórí Àgbàgbé X (Twitter)
The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Bàbá àgbà, ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́rin, ni a gbọ́ wípé, Kusibẹ fọ́ igi mọ́ l’órí tí ẹ̀jẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí ní dà l’ori bàbá náà.

Ìbòsí bàbá yìí ni àwọn ará àdúgbò gbọ́ tí wọ́n sì sáré síi láti dóòlà ẹ̀mí rẹ̀ tí wọ́n sì gbée lọ sí ilé ìwòsàn ti ìjọba ní agbègbè náà. Níbẹ̀ ni wọ́n ti fún bàbá ọ̀ún ní ìtọ́jú ráńpẹ́ tí wọ́n sì sọ pé kí wọ́n gbée lọ sí ilé ìwòsàn mìíràn ní ìlú Iléṣà.

Ṣùgbọ́n àwọn ẹbí bàbá yí kò leè gbée lọ sí ilé ìwòsàn tí wọ́n sọ fún wọn ọ̀ún látàrí wípé, kò sí owó tí àwọn yóò san nígbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀. Èyí ló ṣe okùnfà bí bàbá yìí ṣe gba èkuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọra o, ní ọjọ́ kẹta ìṣẹ̀lẹ̀ náà. 

Ǹjẹ́ àwa ọmọ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ti wá rí ìdí tí màmá wa, Modupẹọla Onitiri-Abiọla, ṣe dìde wípé, ìyà yí ti pọ̀jù fún ìran àwọn. Ojoojúmọ́ ni àwọn ènìyàn ń kú ikú tí kò yẹ kí wọ́n kú nítorí ìwà àìbìkítà àwọn ọlọ́jẹ̀lú tí wọ́n pe ara wọn ní olóṣèlú. Àwọn ìdílé wọn lọ ń gba ìwòsàn ní ilẹ̀ òkèèrè nígbà tí àwọn ọmọ aládé ń kú bí adìyẹ nígbà tí kò sí ìtọ́jú tí ó péye. 

Wọ́n ti gba ìwà rere kúrò lọ́wọ́ àwa ọmọ aládé. Tí kìí bá ṣe bẹ́ẹ̀ ni, kí ni ìbáà ṣẹlẹ̀ tí ó leè mú kí ọmọ fọ́ igi mọ́ bàbá-bàbá rẹ̀ lórí nítorí oko tí kò tó ǹkankan. Ó màse ò! Àwọn ìjọba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà ti ba nǹkan jẹ́ gidigidi o. 

Nítorí náà, ẹ̀yin ọmọ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ẹ jẹ́ kí a dìde àtìlẹ́yìn fún àwọn adelé wa, kí a lè gba ara wa lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n ń fipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa, kí ìwà ìj’ọ́mọlúwàbí sì leè padà bíi ti ìgbà ìwáṣẹ̀. Ìran Yorùbá kìí se apànìyàn rárá, ìran tí ó ní ìbẹ̀rù Ẹlẹ́dàá wa ni a jẹ́. 

Ní kété tí àwọn adelé wa bá sì ti wọlé sí oríko ilé iṣẹ́ ìjọba wa kọ̀ọ̀kan ní ilẹ̀ Yorùbá, àgbékalẹ̀ ètò ìwòsàn tí ó gbámúṣé ti wà nílẹ̀, ọ̀fẹ́ sì ni ìwòsàn fún gbogbo àwọn ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá.