Tinú ọ̀lẹ lọ̀lẹ ńjẹ; aṣiwèrè èèyàn ni ò mọ èrú tí yó gbà 

Ìròhìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́, pẹ̀lú fọ́nrán rẹ̀ fi yé wa wípé ní Lekki, ní Ìpínlẹ̀ Èkó, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, nṣe ni àwọn ọlọ́pa ìlú Nàijíríà wà ní’bẹ̀ ní rẹpẹtẹ, bí ẹni pé ojú ogun ni! Àti oríṣiríṣi ọkọ̀ ọlọ́pa, àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́pa fún’ra wọn, pẹ̀lú àwọn míràn tí a ò mọ bí ti’wọn ṣe jẹ́, ni wọ́n wà ní ojú pópó, níbẹ̀. Àwọn ọkọ̀ wọ̀nyẹn dúró, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́pa náà nrin, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún sáré jẹ̀lẹ́nkẹ́, tí wọ́n sì nkọrin lọ.

❗PÀJÁWÌRÌ FÚN ÀÀBÒ❗KÁÀKIRI GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ YORÙBÁ TÍTÍ DÉ OLD Ọ̀YỌ́ EMPIRE, Ẹ MÁA YA FỌ́TÒ FÚLÀNÍ, OLỌ́PA, OLÓṢÈLÚ, SÓJÀ, TÍ Ẹ BÁ FURA SÍ ÌRÌN ÀTI ÌṢESÍ WỌN NÍ AGBÈGBÈ YÍN. KÍ Ẹ FI ṢỌWỌ́ SÍ BÀBÁ ÌJÌNLẸ̀ +905367341665 (WHATSAPP). (ÌKÉDE… Pín Sórí Àgbàgbé X (Twitter)

Ìyàlẹ́nu ni ó jẹ́ pé ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà ṣáà fẹ́ tẹ́, wọ́n dẹ̀ máà tẹ́, ó ti wá di dandan báyi! Ọpọlọ wọn kò tilẹ̀ ṣíṣẹ́ rárárá ni.

L’oótọ́ àti ní òdodo, ayíradà gbáà ni Tinubú; ẹni tó bá ṣì rò pé ọmọ Yorùbá ni òpònú Tinubú ọ̀ún, kí ẹni náà tún lọ sùn, kí ó tún jí padà.

ỌLỌ́PA NÀÌJÍRÍÀ SỌ ARA WỌN DI AMÚNIL'ẸRÚ

Kìí ṣe Tinubú nìkan ló máa tẹ́; ẹ̀tẹ́ àwọn ọlọ́pa aláìnírònù rẹ̀, gọbọi báyi ni ẹ̀tẹ́ ti’wọn káàkiri àgbáyé ṣe máa rí, t’orí, nígbà t’ó bá dé’lẹ̀ tán, wọ́n á ní àwọn ìbá mọ̀ ni, ó sàn jù kí àwọn ti kọ iṣẹ́ ibi tí wọ́n rán wọn, ju ìtìjú àti ọ̀ràn dídá tí àwọn wá dá báyi.

Ohun tí kò yé apànìyàn Tinubú ni pé, òpin rẹ̀ ti dé!

Àṣé báyi ni Tinubú ṣe fẹ́ parí ìgbésí ayé rẹ̀! Ó dẹ̀ tọ́ si bẹ́ẹ̀, nítórí òṣùwọ̀n tí a bá fi wọ̀n fún ẹlòmíràn, òun náà ni a ó fi wọ̀n fún’ni padà.

Kí àwọn olùkọ̀tàn bẹ̀rẹ̀ síí kọ ìtàn Tinubú àti ìgbésí ayé rẹ̀: ó dájú pé àkókò ìparun rẹ̀ ti dé.

Wípé wọ́n ti ẹ̀ nṣe ìwọ̀nyí lórí Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, gbogbo ìbínú Olódùmarè, láti òkè Ọ̀run wá, ti wà lórí rẹ o, Tinubú, àti àwọn ọmọ-ogun àti ọlọ́pa Nàìjíríà tí o fi nṣẹrùbà ní ilẹ̀ Yorùbá. Ṣẹ̀rùba tani? Yorùbá ti lọ: ẹ̀sín rẹ ni ayé máa fi bá wa yọ̀:

Nísiìyí, kí gbogbo ogun Ọ̀run ó máa rọ̀jò Ìbínú Olódùmarè sórí rẹ, ìwọ tí o pe ara rẹ ní Bọla Ahmed Tinubú, ayíradà ènìyàn tí kò ní’ran, tí ó nfi orúkọ-olórúkọ bo’jú. Áà kúkú mọ’bi t’ó o ti wá: ọmọ inú igi, tàbí ọmọ inú òkúta; inkankan ṣá ni a ṣáà mọ̀: pé, óò kì nṣe alánfàní ènìyàn: ẹranko ni ẹ́; apànìyàn ni ẹ́, ṣùgbọ́n, fún èyí tí o nṣe lórí ilẹ̀ Yorùbá yí, òpin rẹ ti dé.

Ọmọ Yorùbá, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀, nítorí òpin ogun yí súnmọ́ etílé. Bẹ́ẹ̀ ni, kí gbogbo ìjọ ènìyàn yí le mọ̀ pé Olúwa kìí fi idà tàbí ọ̀kọ̀ gba’ni là; nítorí pé ti Olúwa ni ogun náà, yíò sì fa ìwọ Tinubú lé wa lọ́wọ́!