Bí a ṣe ngbọ́ oríṣiríṣi ìròyìn tí ó gba ìkíyèsára fún ọmọ Yorùbá, náà ni a ń mú wọn wá sí etí ìgbọ́ wa.
Èyí tí a gbọ́ nínú fọ́nrán kan ní àìpẹ́ yí ni bí, ọmọbìnrin Yorùbá kan tí ó ngbé ní agbègbè Libya ti sọ ìrírí rẹ̀ pẹ̀lú awakọ̀ oníṣẹ́-ibi kan tó fẹ́ gba ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ọkọ̀-ìrìnnà-ojúpópó tí ó wọ̀. Ọpẹ́lọpẹ́ pé ọwọ́ rẹ̀ ni ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ náà wà, tí kìí ṣe inú àpam’ọ́wọ́ rẹ̀,awakọ̀ náà gba àpam’ọ́wọ́ obìnrin yìí, ṣùgbọ́n kò rí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ gbà.
Arábìnrin yí wá sọ pé kò sí ọmọ Lárúbáwá kankan tí ó dá òun lóhùn nígbàtí òun nkígbe “olè” bíótilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣì lè mú olè náà ní àkókò yẹn, ṣùgbọ́n, ṣe ni wọ́n fi gbígbọ́ s’aláìgbọ́.
Arábìnrin yí wá gba àwọn obìnrin wa tí ó wà ní ìlú Libya níyànjú láti ṣọ́ra tí wọ́n bá lọ mú ọkọ̀ lójú pópó;ó ní ohun tí àwọn awàkọ yẹn ńfẹ́ ni láti bá obìnrin lòpọ̀ tàbí kí wọ́n gba ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀.
Gbogbo ọmọ Yorùbá tí ó wà ní òkè-òkun, ẹ máṣe jẹ́ kí á fi ara wa sí ipò tí ó léwu; kí á sì tún fi eléyi sọ fún àwọn èèyàn wa pé Orílẹ̀-Èdé Yorùbá ti wà ní Òmìnira.
Àsìkò ti tó láti pàdà sílé; Olódùmarè máa ràn wá lọ́wọ́ láti lé ìjọba Nàìjíríà tó njẹgàba lórí ilẹ̀ wa kúrò láìpẹ́. Kí a má ṣe fi ara wa fún ìyà jẹ mọ́ ní ilẹ̀ òkèèrè, a ti ní ìjọba tiwa ní ilẹ̀ Yorùbá, Kété ti a bá sì ti rẹ́yìn àwọn tó ń jẹ gàba lòrí ilẹ̀ wa, ohun dídára gbogbo tí ìjọba Orìlẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) ní fún wa ni a ó máa rí.
A dúpẹ́ lọ́pọ̀lóọpọ̀ lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá Ìran Yorùbá tí Ó fi iṣẹ́ ìtúsílẹ̀ Ìran Yorùbá yí rán màmá wa, Ìyá-Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, pé kí ọmọ Yorùbá máṣe jìyà mọ́.