Ìròyìn kan ní a rí lórí ayélujára tí o un sọ nípa bí àwọn ọmọ ìgbò ṣe ún kó ara wọn ni ọ̀pọ̀ yanturu wá sí ìpínlẹ̀ Èkó ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùba Democratic Republic of the Yorùba(D.R.Y).
Kíni kí a ti pe irú ìwà àìbìkítà yi? Nítorí ojú wọn kòfọ́ bẹ́ẹ̀ni etí wọn kò di nígbàti a ṣe ìkede orílẹ̀-èdè olómìnira Tiwantiwa Yorùba(D.R.Y) ní ogúnjọ́ oṣù bèlú ẹgbẹ̀wá ọdún-ó-lé-méjìlélógún tí a sì ti bẹ̀rẹ̀ ìjọba wa ní kété tí a búra fún Olórí Adele wa Bàbá wa Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́ ní ọjọ́ kejìlá oṣù igbe ẹgbẹ̀wá ọdún ó-lé-mẹ́rìnlélógún.
Gbogbo ìgbésẹ̀ yí wáyé láti ọwọ́ Ìyá wa ẹni oríṣàdá Modúpẹ́ Onítìrí Abíọ́lá, ẹni tí kòní tẹ́ tí orúkọ rẹ̀ kòní parẹ́ láéláé.
Ẹyin ìgbò ẹ gbọ́ o, Orílẹ̀-èdè ni D.R.Y tí o yàtọ́ pátápátá si ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà kí ẹ ṣọ́ arayín dáradára nítorí, èyítí o bá tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ si èyíkeyí nínú òfin wa ìjọba yóò fi imú ẹni náà dónrinyío fimú dọ́rin.
Ìgbàyí tí yàtọ̀ sí ti àtẹ́hìnwá, ẹ̀yàkẹ́yà tàbí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ṣe àtìpó ní Orílẹ́-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá(D.R.Y) gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí óún bọ̀wọ̀ fún òfin. kí eku ilé kí o gbọ́ kí ó sọ fún toko.