Ọmọ Yorùbá kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Ṣèyí Ọ̀jẹ́labí, ní ó ti ṣe ohun ìrìn fún àwọn tí ó ní ìpèníjà ojú o, láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè rìn ní agbègbè wọn láì kọlu ohunkóhun.
Ṣùgbọ́n kìí wá nṣe ọ̀pá igi o, ti irinṣẹ́ ìgbàlódé ni, tí ẹni tí ó nlòó máa mú dání, á sì rọra nàá síwájú; tí ó bá ku díẹ̀ kí ó kọlu nkan, ẹ̀rọ náà á dún, èyí tí ẹni yẹn á fi mọ̀ pé òun ti fẹ́ dé ibi tí òun ti lè kọlu nkan.
Ìnkan ayọ̀ tí ó tún wà níbẹ̀ ni pé, Ọ̀gbẹ́ni Ọ̀jẹ́labí sọ pé èyí tí ó pọ̀jù nínú ohun-èlò tí òun fi ṣe ẹ̀rọ yí, láti àyíká rẹ̀ ni ó ti rí wọn.
Ó ti bẹ̀rẹ̀ náà nìyẹn; ṣebí ohun tí Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá ti nsọ nìyẹn, pé ògo wà lára ọmọ Yorùbá, wọ́n dẹ̀ máa rí ogo náà lò ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.
Orí ẹ̀rọ ayélujára ni a ti rí ìròhìn náà, èyí tí ó mú ìnú ènìyàn dùn, pé, ní àìpẹ́, ní kété tí Olódùmarè bá ti ràn wá lọ́wọ́ tí a tí rí ẹ̀hìn àwọn ajẹgàba lórí ilẹ̀ wa, irúfẹ́ àwọn ọ̀dọ́ bí Ṣèyí Ọ̀jẹ́labí ni yíò pẹ̀lú àwọn tí ó máa gbé ògo ilẹ̀ Yorùbá ga síi.

Ká Ìròyìn Síwájú sí:
- ÀMERICA TI F’ỌWỌ́ SÍ ỌSIN ADÌẸ LÁTI YÀRÁ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ ÌJÌNLẸ̀
- ẸGBẸ̀RÚN MÁRUN NÁÍRÀ NI ÀWỌN ARÁ ÌLÚ NÀÌJÍRÍÀ FI DA’LẸ̀ ARA WỌN !
- ÀNFÀÀNÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ
- ÒFÉGÈ ÌRÀNLỌ́WỌ́: ọmọ Yorùbá, máṣe yà sí’bẹ̀ !
- ỌMỌKÙNRIN KAN ṢE’KÚ PA BÀBÁ TÓ BÍ BÀBÁ RẸ̀ NÍTORÍ OKO
- JAMIU ABÍỌ́LÁ NHU ÌWÀ ỌMỌ ALÈ
- ÌLÙ NÀÌJÍRÍÀ TI FI ŃKÀN ṢE ÀWỌN ÈWE
- ṢÍṢE ARA LÓGE NÍ ILẸ̀ YORÙBÁ