A rí i lójú, a mọ̀ ọ́ lẹ́nu; òòwò oẹ kì í pọ́n-wọ́-lá 

Ṣé kò kúkú sí ànfààní kankan nínú ìlú wọn ọ̀ún tẹ́lẹ̀ – ìlú t’ó f’ẹ̀gbẹ́ tì wá, Nàìjíríà. Nṣe ni a tún wá gbọ́ báyi, pé, nínú ìfẹ̀hónú-hàn tí wọ́n ní àwọn ọ̀dọ́ wọn nṣe, látàrí bí ìgbé-ayé wọn ṣe le koko ní ìlú ọ̀daràn náà, ibẹ̀ ni a tún ti rí àwọn tí ó jẹ́ wípé àwọn náà nṣe ìwọ́de o, wọ́n ní ó tẹ́ àwọn l’ọrùn bí ìlú àwọn ọ̀ún ṣe rí o! Wọ́n ní, ní tiwọn, nṣe ni ohun gbogbo nlọ ní mẹ̀lọ mẹ̀lọ ní nàìjíríà wọn o, tí kò sì sí ìṣòro kankan rárá!

❗PÀJÁWÌRÌ FÚN ÀÀBÒ❗KÁÀKIRI GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ YORÙBÁ TÍTÍ DÉ OLD Ọ̀YỌ́ EMPIRE, Ẹ MÁA YA FỌ́TÒ FÚLÀNÍ, OLỌ́PA, OLÓṢÈLÚ, SÓJÀ, TÍ Ẹ BÁ FURA SÍ ÌRÌN ÀTI ÌṢESÍ WỌN NÍ AGBÈGBÈ YÍN. KÍ Ẹ FI ṢỌWỌ́ SÍ BÀBÁ ÌJÌNLẸ̀ +905367341665 (WHATSAPP). (ÌKÉDE… Pín Sórí Àgbàgbé X (Twitter)
Nigeria government paid people to hijack ongoing protest

Àmọ́ ṣá o, àṣírí wá tú nígbàtí fọ́nrán ‘m’ohùnm’awòrán kan já’dé ní’bi tí wọ́n ti nfún wọn ní ẹgbẹ̀rún márun náírà, ẹnikọ̀ọ̀kan, tí a gbọ́ pé wọ́n fún wọn kí wọ́n le já’de láti gbé ohùn àtakò síta lòdì sí àwọn tí ó nṣe ìfẹ̀hónú-han – wọ́n ní àwọn ò f’ara mọ́ ìfẹ̀hónú-hàn kankan ní ìlú àwọn o, àwọn tako ìfẹ̀hónú-hàn náà – à ṣé ẹgbẹ̀run márun náírà tí wọ́n ti fún wọn ni ó nsọ̀rọ̀!

Obìnrin ará Nàìjíríà kan tí ó gbé ọ̀rọ̀ náà já’de l’orí ayélujá’ra TikTok wá sọ, ó ní, àwọn olórí wọn ní ìlú ajíríyà wọn ọ̀ún ti sọ òṣì àti ìṣẹ́ di ohun-ìjà tí wọ́n fi mbá ará-ìlú wọn l’ọhún jà; ó ní, wọ́n dẹ̀ nmọ̀ọ́-mọ̀ ṣe eléyi ni.

Ṣebí ara nkan tí Màmá wa, MOA, ti nsọ fún wa náà nìyẹn – wọ́n ní àwọn tí ó nṣàkóso ìlú tí àwa ti ṣ’orí iré kíkúrò lára rẹ̀ yí, nṣe ni wọ́n nmọ̀ọ́-mọ̀ fi ìyà jẹ àwọn ará ìlú wọn ọ̀ún.

Àwa ti wá ṣ’orí ire o, a ti jáde kúrò nínú nàìjíríà ọ̀ún láti ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjì-lé-lógún; bẹ́ẹ̀ ni a dẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ìjọba tiwa láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe ẹgbàá ọdún-ó-lé mẹ́rinlél’ogún, èyí tí ó túmọ̀ sí kí  á múra kíá, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olódùmarè, tí ó máa ṣí àwọn agbésùnmọ̀mí nàìjíríà náà kúrò lórí ilẹ̀ Yorùbá ní àìpẹ́ àti àìjìnà.

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Màmá wa, Ìyá Ìràn Yorùbá, Ìránṣẹ́-Olódùmarè, Ìyá- Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, tí Ọlọ́run ràn lọ́wọ́ láti mú wa jáde kúrò nínú ìlú mùjẹ̀-mùjẹ̀ náà.

Gẹ́gẹ́bí ọmọ ìlú Nàìjíríà ọ̀ún tí ó  sọ̀rọ̀ lórí TikTok ṣe sọ, ó ní àwọn olórí wọn ní ìlú náà fi àwọn sínú òṣì, kí àwọn ará-ìlú wọn máṣe lè dójú kọ àwọn ọ̀jẹ̀lú ọ̀ún. Ó wá sọ pé ó ṣe òun láanú, bí àwọn kan láarín wọn ṣe ntìtórí ẹgbẹ̀rún márun náírà ta ọjọ́ ọ̀la wọn.