Sé ní àípẹ́ yi ni a sọ ìdí pàtàkì tí ó fi jẹ́ wípé a kò le gbé irúfẹ́ ìgbé ayé tí ó yẹ k’á gbé gan-gan, láì jẹ́ wípé a gbé ìgbé-ayé wa ní ìbámu pẹ̀lú ìṣẹ̀dá wa, tí èyí sì bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìṣẹ̀dá Yorùbá, ní’wọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ wípé ìṣẹ̀dá Yorùbá ni Olódùmarè dá mọ́’wa l’ara.
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on XBáwo ni a ṣe le mọ ìṣẹ̀dá Yorùbá fún ‘ra rẹ̀, láì jẹ́ wípé a mọ ìtàn Yorùbá?
Ìtàn Yorùbá ṣe pàtàkì fún wa l’ati mọ̀, nítorí wípé, nípa mí mọ ìtàn òtítọ́ ti Yorùbá, kìí ṣe ìtàn tí àwọn òyìnbó gbé lé wa l’ọwọ́ nípa Yorùbá, ṣùgbọ́n ìtàn Yorùbá, gẹ́gẹ́bí ó ṣe wà ní’wá’jú Olódùmarè, fún’Ra’ra rẹ̀, l’aìní àbàwọ́n; tí a bá lè mọ ìtàn yí; ìtàn ìṣẹ̀dá wa n’ìyẹn; ní’gbà náà ni a ó lè mọ ìṣẹ̀dá wa ní òtítọ́ àti ní òdodo.
Ká Ìròyìn: Orúkọ Nílẹ̀ Yorùbá
Olódùmarè mọ ìtàn wa; nít’orí wípé òun ni Atọ́’kùn Ìtàn náà l’ati àtètèkọ́’ṣe wá; bẹ́ẹ̀ náà ní, òun N’ìkan ni ó le ṣí ojú ẹ̀mí wa sí ìtàn náà àti òtítọ́ Ìtàn náà. Tí a bá fi lé èyítí àwọn òyìnbó gbé lé wa l’ọwọ́ wípé òun ni ìtàn wa, irọ́ gbáà l’ó bá dé, nít’orí amúnisìn ni òyìnbó o!
Òyìnbó kìí ṣe olólùfẹ́ wa. Ọ̀tọ̀ ni ìtàn tí wọ́n gbé lé wa l’ọwọ́ wípé ó jẹ́ ìtàn wa, ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ pátápátá gbáà ni bí ìtàn ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá ṣe rí l’orì’lẹ̀ ayé yí. Ìbá ṣe wípé ojú wa là sí òtítọ́ ìtàn wa ni, àwa ìbá mọ̀ wípé òyìnbó kó’ríra wa gbáà.
Ara ọ̀nà tí wọ́n fi r’ayè gbà l’ati kó wa l’ẹrú ni à ti gba Ìtàn Yorùbá kúrò l’ọwọ́ ọmọ Yorùbá.
T’orí wípé ìtàn wa ti sọ nù mọ́ wa l’ọwọ́, kò jẹ́ kí á mọ irúfẹ́ ènìyàn tí Olódùmarè dá wa – a sì ní l’ati mọ ẹ̀dá tí ó dá wa, kí a le rìn nínú ìṣẹ̀dá wa – èyí ni ó fi wá jẹ́ wípé tí a kò bá mọ ìtàn wa, a kò lè mọ ìṣẹ̀dá wa; tí a ò bá dẹ̀ ti mọ ìṣẹ̀da wa, a kò le rìn nínú ìṣẹ̀dá náà; tí a kò bá dẹ̀ ti rìn nínú ìṣẹ̀dá wa, a kò lè ṣe irúfẹ́ àṣeyọ’rí tí Olódùmarè ti kọ mọ́ wa l’ati ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbésí ayé wa wá.
Ohun gbogbo tí a bá máa ṣe ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ó dá l’orí wípé kí á mọ ìṣẹ̀dá wa nínú Olódùmare, èyí ni yíò fún wa ní ìmọ̀ l’ati Ọ̀run wá tí ó jẹ́ wípé a óò wá mọ bí ó ti yẹ kí a rìn nínú ayé yí.
Ẹ má ṣe jẹ́ kí gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kí ó kà wá l’ayà wípé báwo l’a ṣe máa ṣé. Wọ́n ní ìrìn ogún ọdún, ìgbésẹ̀ kan ni a fi máa nbẹ̀rẹ̀ rẹ̀.
Pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀ níwájú Olódùmarè, kí ó ṣí wa ní’yè, a má a bọ́ s’ojú ọ̀nà mí mọ Ìtàn wa.