Ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ ìgbà ni a ti gbọ́ l’ati ẹnu Ìránṣẹ́ Olódùmarè, Màmá Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, wípé orílẹ̀-èdè Yorùbá jẹ́ èyí tí kò ní sí òfò tàbí àdánù kankan ní ètò ìṣè’jọba rẹ̀.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Ẹ má ṣe jẹ́ kí èyí kí ó ṣe wá ní kàyéfì rárárárá o! Ara àgbékalẹ̀ fún ìgbáyégbá’dùn ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá nìyẹn.

A níl’ati mọ̀ wípé bí wọ́n ṣe nṣeé ní ìlú ibi tí a ti mbọ̀ kìí ṣe ọ̀nà t’ó dára rárá.
The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Ìjọba kìí ṣe ètò àti kó’wo jẹ! Gbogbo èyí tí wọ́n npè ní “Constituency Allowance” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ní ìlú tí a ti mbọ̀, irọ́ l’ó bá dé! Ohun tí ìjọba bá fẹ́ ṣe fún ará ìlú ni ó yẹ kí wọ́n ṣe tààrà, kìí ṣe kí wọ́n kọ́kọ́ mú owó yẹn sí àpò ẹni kan (private account) ní orúkọ “Constituency Allowance.” Ara ibi tí òfò àti àdánù ti máa nwá’yé n’ìwọ̀nyẹn.

Ka Ìròyìn: Ìba’nújẹ́ L’apá Kan, Ìroyìn Ayọ̀ L’apá Kan!

Gẹ́gé bí ìránṣẹ́ Olódùmarè ṣe máa nsọ fún wa, a máa ṣe ètò ìlú àti ètò ìṣe’jọba Orílẹ̀-Èdè Yorùbá bí ẹni tí ó nṣe okùn-òwò ni. Nítorí wípé, tí a kò bá ṣeé bẹ́ẹ̀, k’amári, orílẹ̀-èdè á kàn wu’lẹ̀ dà wó ni!

Ìṣe’lú àti ìṣe’jọba l’orí àgbéka’lẹ̀ “kò sí Òfò, kò sí Àdánù” yí ṣe pàtàkì l’ọpọ̀l’ọpọ̀, èyí ni ó máa jẹ́ kí ó jẹ́ wípé orílẹ̀-èdè wa yíò wà ní òminira títí ayé!

Yoruba Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá