Ìròyìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ láìpẹ́ yí fihàn wá gbangba pé, ọrọ̀ tí Olódùmarè, Ẹlẹ́dàá Ìran Yorùbá fi sí Ilẹ̀ wa kò lónkà rárá. Ọrọ̀ wọ̀nyí kìí wá ṣe nípa ti ọ̀rọ̀ ajé nìkan, ṣùgbọ́n ọrọ̀ Ẹ̀mí pẹ̀lú.
Ní ìlú Iléṣà, ní agbègbè Ìṣokùn, ni ìròyìn àrà ọ̀tọ̀ yí ti wọlé wá. Odò kan tí a mọ̀ sí ‘Omi Oko,’ ni ibi tí a nsọ yí, bẹ́ẹ̀ náà ni a gbọ́ pé orúkọ omi yí náà ni wọ́n fi npe àdúgbò ọ̀ún.
Ohun àkọ́kọ́ tí ó farahàn ni pé, wọ́n kọ́ ilé sí orí omi yí, wọ́n sì mọ odi ilé náà. Àwọn fèrèsé kéékèèké wá wà ní ìsàlẹ̀ odi ilé yí, tí a lè ṣí, láti leè na’wọ́ fi abọ́ bu omi náà, àti wípé omi yìí kìí rù,bẹ́ẹ̀ ni kìí gbẹ.
A ní láti wólẹ̀ níwájú Elédùmarè, kí á bẹ̀ẹ́ gidi pé, kí ó jọ̀wọ́ nínú àánú rẹ̀, kí ó ṣí ojú àti ọkàn wa sí bí omi yìí ṣe jẹ́ gan-an, bí a ṣe le máa lòó, àti ní pàtàkì, kí gbogbo agbára tí Ẹlẹ́dàá wa fi sí omi yí, kí ó tún le búyọ pátápátá fún Ìran Yorùbá; nítorí a gbọ́ pé, nígbà kan rí, kò sí àìsàn tí ó ńṣe ọmọ Aládé tí omi yí kò ní ṣe ẹ̀rọ̀ fún, àti pé tí aláboyún bá mú omi náà, yóò mú kí ó bí wẹ́rẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni àgàn yóò t’ọwọ́ àlà b’osùn lẹ́yìn tí ó bá mu omi náà.
Ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe kí omi yí ní èèwọ̀ tirẹ̀, nítorí náà, a ò kàn lè dédé rò pé irúfẹ́ ọ̀nà tí òyìnbó amúnisìn máa ń fi ṣe ìwádìí rẹ̀ ni a nílò láti ṣe ìwádi omi yìí.
Nítorí a gbọ́ wí pé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ìyá wa tí wọ́n mọ̀ nípa omi yí àti lílò rẹ̀, ni wọ́n ti lọ ibi àgbà ń rè.
Àbí ẹ ò ríi wípé Olódùmarè kẹ́ àwa ìran Yorùbá gidigidi, bí àwọn nǹkan àlùmọ́ọ́nì ilẹ̀ ṣe wà, bẹ́ẹ̀ náà ni oríṣiríṣi àwọn ohun àmì abáláyé ṣe wà, tí a sì ní láti mọ ìwúlò wọn, gẹ́gẹ́bí ó ṣe rí ní ìgbà ìwásẹ̀.
Nítorí náà, a dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá wa, ẹni tí ó ṣíjú wò wá ní déédè ìgbà yí,àti ní déédé àsìkò yí, pé ká kúrò nínú oko ẹrú, tó sì wá rán ìránṣẹ́ Rẹ̀, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla láti mú wa dé ibi àṣeyọrí wa, èyí tí yóò mú kí ìran Yorùbá leè padà sí bí Olódùmarè ṣe dá wa, nítorí pé, ìyá wa ti sọ fún wa wípé a máa kọ ìtàn òtítọ́ àwa Yorùbá bí a ṣe jẹ́ gan-an, nípa èyí, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nǹkan ni ojú wa máa ṣí sí, tí yóò ṣe ìwúlò fún wa láti leè mú kí orílẹ̀ èdè wa gòkè àgbà.