Olórí Ìjọba-Adelé, Democratic Republic of the Yoruba, Bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, ti bá àwọn ọ̀dọ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y) sọ̀rọ̀. Ní àná, ọjọ́ kéjìlá, oṣù ògún, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rin-lé-lógún, tí ó jẹ́ Àyájọ́ Ọjọ́ Àwọn Ọ̀dọ́, ni èyí wáyé.
Olórí Adelé fún àwọn ọ̀dọ́ D.R.Y ní ìrètí ògo, pé, níwòyí àmọ́dún tí àyàjọ́ yí á tún wáyé, á lárinrin ju èyí lọ, nítorí, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe sọ, Ìjọba D.R.Y mọ̀ pé ìjọba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tí ó njẹ gàba lóri ilẹ̀ wa, nípa èyí tí ìdíwọ́ àti ìdènà, pẹ̀lú sún-kẹrẹ-fà-kẹrẹ fi wà, òun ni ó ṣe okùnfà bí gbogbo nkan kò ṣe lọ bí wọ́n ṣe yẹ kí wọ́n lọ ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, èyí ni ó wá fa gbogbo ìnira tí ó wà nílu.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ wọn, àwọn ọ̀dọ́ tilẹ̀ nkú ikú àìtọ́jọ́ nítorí pé àwọn kan ti ròó pin pé kò sí ọjọ́-ọ̀la mọ́ fún àwọn, nítorí bí inkan ṣe nlọ, tí kò sì sí ìrètí fún àwọn mọ́.
Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe sọ, gbogbo nkan tí Ìyá-Ààfin Olóyè Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá ti róye rẹ̀ tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ìgbà yí, ni eléyi jẹ́: tí wọ́n ní kí a má ṣe jáfara, nítorí inkan tó mbọ̀ léwu!
Olórí Adelé tún wá sọ, wọ́n ní àwọn olórí àti àwọn ọba tí wọ́n jẹ́ àgbààgbà lórílẹ̀-èdè Yorùbá, tó jẹ́ wípé abẹ́ ìjọba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà ni wọ́n ti njẹ, tí wọ́n nmu, tí wọ́n sì nṣaṣojú lóri ilẹ̀ Yorùbá fún Ìjọba Nàìjíríà, àwọn ni wọ́n ṣe ẹ̀tànjẹ fún ọ̀dọ́ ilẹ̀ Yorùbá, ti gbogbo ìyà yí fi njẹ ọ̀dọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀. Wọ́n ní, ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ti gbé Màmá, MOA dìde láti lè jẹ́ kí ọ̀dọ́ Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá rógo lò, kí a lè gbara wa kúrò lọ́wọ́ àwọn amúnisìn tó njẹgàba lórí ilẹ̀ Yorùbá wa.
Wọ́n ní, nípa àtìlẹhìn Ọlọ́run, Màmá wa MOA ti ṣe àṣeyọrí yí, tí iṣẹ́ sì nlọ láì dáwọ́ dúró. Wọ́n ní àwọn fẹ́ kí gbogbo ọ̀dọ́ I.Y.P máa rò nípa àwọn nkan tí wọ́n fẹ́ gbé ṣe ní ilẹ̀ Yorùbá, kí a lè jọ pawọ́pọ̀, láti lo àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún ọ̀dọ́; kí a jùmọ̀ gbé Orílẹ̀-Èdè Yorùbá ga, kí a sì gbe lé orí ìpilẹ̀ṣẹ̀ rere tó dúró lórí ìfẹ́ Ọlọ́run.
Wọ́n sọ pé Ọlọ́run kẹ́ Ọ̀dọ́ I.Y.P lọ́pọ̀lọpọ̀, pẹ̀lú ọgbọ́n, ìmọ̀, agbára àti òye. Wọ́n sọ pé, ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ọ̀dọ́ ló ngbélu dúró, ọ̀dọ́ sì ló ntupalẹ̀. Tí wọ́n bá nka gbogbo olùgbélu, ọ̀dọ́ ló pọ̀jù. Bẹ́ẹ̀ sì ni, bí wọ́n bá nsọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ndáàbò bo ìlú gẹ́gẹ́bí ológun, ọ̀dọ́ ni wọ́n.
Wọ́n tún ní, òṣìṣẹ́ inú ìlú pàápàá, tó jẹ́ kí ìlú gbòòrò, tó jẹ́ kí ìlú ní Ìdàgbàsókè, ọ̀dọ́ náà ni wọ́n! Wọ́n sọ pé ó dájú pé Ọlọ́run ṣe Ọ̀dọ́ I.Y.P lógo. Nítorí náà, ọ̀dọ́ gan-gan ni Ìlú. Fún ìdí èyí ni ó ṣe jẹ́ ọ̀dọ́ ló njìyà jù lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi.
Olórí-Adelé wa sọ pé kí àwọn Ọ̀dọ́ dìde, nítorí pé, ọ̀dọ́ ló lágbára jù láwùjọ, láti lè gbé iṣẹ́ ilẹ̀ Babanlá wa lárugẹ. Wọn ní a ti débi tá nlọ, díẹ̀ ló sì kù kí ìjọba D.R.Y bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lóní sàn-án sàn-án. Wọ́n sọ pé kí á má ṣe jẹ́ kí a fún ẹnikẹ́ni láàyè láti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa lọ́kàn, tàbí kó ṣì wá ní ìrìn-àjò tí a ti rìn parí yí.
Wọ́n ní kí ọ̀dọ́ I.Y.P má ṣe dá sí gbogbo ìgbésẹ̀ tàbí ohunkóhun tí Ìjọba Nàìjíríà ngbé ṣe lórí ilẹ̀ Yorùbá, nítorí pé wọ́n máa ti ri pé kìí ṣe ti Ìjọba Democratic Republic of the Yoruba.
Olórí Adelé ní àwọn fẹ́ kí gbogbo ọ̀dọ́ lọ fọkàn balè, àti pé Orílẹ̀-Èdè Yorùbá ti dúró. Tí ó bá máa fi di Àjọ̀dún Ọjọ́ Ọ̀dọ́ tó mbọ̀, ìgbésí ayé ọ̀dọ́ máa lárinrin ju ti ọdún yí lọ, nítorí ìjọba D.R.Y ti ṣe àwọn ètò ìgbélé-ayé ìrọ̀rùn sílẹ̀ fún gbogbo ọ̀dọ́ lọ́kùnrin, lóbìnrin, tí oníkálùkù á sì máa rí ògo lò, tí kò sì sí bóyá ẹnikẹ́ni mú wa lẹ́rú ní Orílẹ̀-Èdè Babanlá wa.
Fún ti gbogbo àwọn agbésùnmọ̀mí tó njẹgàba káàkiri lórílẹ̀-èdè wa, wọ́n ní gbogbo wọn máa di ohun ìgbàgbé láìpẹ́ láìjìnà.
Wọ́n ní àwọn fẹ́ kí gbogbo ọ̀dọ́ mọ kiní kan, wípé gbogbo àwa ọmọ Aládé pátápátá, la jẹ́ ọmọ Ológo, tí Ọlọ́run fún ní Ẹ̀bùn, lóríṣiríṣi.
Fún ìdí èyí, gbogbo ohun tí a bá fẹ́ ṣe, kí a lọ máa ronú síi ní kíákíá, nítorí ìjọba D.R.Y ti ṣe àwọn ètò sílẹ̀, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ lórí wọn, tí iṣẹ́ sì nlọ, tí kò dáwọ́ dúró.
Wọ́n ní báyi, “ẹ jẹ́ kí a gbìyànjú, kí a pàdé lórí ayélujára Democratic Republic of the Yoruba, kí ẹ jẹ́ kí a jọ sọ̀rọ̀ lórí gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ gbéṣe, bí àwọn ẹ̀bùn àti talẹ́ntì yín, kí ẹ lè ṣàlàyé gbogbo ohun tí ẹ bá ní lọ́kàn tí ẹ lè gbéṣe lórí ilẹ̀ Yorùbá; kí olúkálùkù wa mọ ibi tí a dàra sí, kí a bẹ̀rẹ̀ sí níí gbé àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí, fún ìtẹ̀síwájú Orílẹ̀-Èdè Democratic Republic of the Yoruba wa.”
Ká Ìròyìn Síwájú: Ọ̀RỌ̀ OLÓGO LÁTI ẸNU ÌYÁ WA, ÌRÁNṢẸ́ OLÓDÙMARÈ, ÌYÁ-ÀÀFIN MODÚPẸ́ ONÍTIRÍ-ABÍỌ́LÁ, NÍ ÀYÁJỌ́ ỌJỌ́ ÀWỌN Ọ̀DỌ́
Wọ́n wá gbé gbólóhùn yí jádé, wọ́n ní “mo fẹ́ kí gbogbo àwa ọ̀dọ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní máa ṣàwárí ara wa, nítorí wípé àkókò àti lo ògo wa nìyí, àti àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa. Nítorí náà, ẹ tújúká, ẹ má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì. Oore-ayọ̀ wa ti dé.
Láìpẹ́, láìjìnà, ìpè máa dún, tí a máa wá ṣàjọyọ̀ fún Orílẹ̀-Èdè Democratic Republic of the Yoruba, ní gbogbo ìpínlẹ̀ wa Méjèèje. Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ìgbáradì fún ayẹyẹ gbòógì tó mbọ̀ lọ́nà yí. Kí Ọlọ́run mọ́jọ́ ró, kí Ó sì bùkún gbogbo àwa ọ̀dọ́ Ilẹ̀ Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y).”