Tí a bá nsọ̀rọ̀ Olùgbàlà; tí a bá nsọ̀rọ̀ Ìránṣẹ́ Olódùmarè; tí a bá nsọ nípa ẹni tí Ọlọ́run yàn, tí ó fún ní ẹ̀mí àti ogo láti kó Ọmọ Yorùbá kúrò nínú oko ẹrú, a nsọ̀rọ̀ nípa Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá; kí ogo, àánú, ààbò, àti ìmísí Olódùmarè kí ó wà pẹ̀lú wọn títí ayé.
Ní àná òde yí, tí ó jẹ́ àyájọ́ ọjọ́ Àwọn Ọ̀dọ́, ni Màmá tún sọ̀rọ̀ jáde o!
Bí wọ́n ti bá àwọn Íbò onígbéraga wí, ni wọ́n bá àwọn tó pera wọn ní gómìnà, tí ó jẹ́ òfégè ni wọ́n ní ilẹ̀ Yorùbá, tí wọ́n bá wọn wí. Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n pe àkíyèsí wa sí ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí Olódùmarè tí fún Ìran Yorùbá ní ànfààní láti gbé ìpìlẹ̀ kalẹ̀, láti lo ògo wa, àti pé àkókò tiwa yí ni ẹlẹ́ẹ̀kẹ́ta, a ò dẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ó tún ṣubú! KÁ MÁ RI!
Màmá tún wá sọ ohun tí àwọn nfẹ́ kí Ọmọ Yorùbá ó ṣe fún àwọn; wọ́n ní àwọn ò bérè ipò, wọn ò bérè owó, ṣùgbọ́n ohun méjì, péré, ni àwọn béèrè: èkíní, kí àwa Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá ó máa yin Ọlọ́run nígbà gbogbo, títí láí, fún oore kíkó tí Olódùmarè kó wa kúrò ní Oko-Ẹrú; tí Ó bá wa gba ìjẹ́-Òrílẹ̀-Èdè wa padà yí; tí Ó sì bá wa gba ìṣèjọba-ara-wa padà, kí á le gbé ìpìlẹ̀ rere yí kalẹ̀, kí á bọ́ sínú ọlá, àlááfíà àti ògo títí ayérayé. Wọ́n ní, láí, kí á máa yin Olódùmarè fún èyí.
Èkejì, Màmá sọ pé Kí á dáàbò bo agbára ìṣèjọba-ara-ẹni wa yí, títí ayé, wọ́n dẹ̀ sọ pé èyí jẹ́ iṣẹ́ àìgbọdọ̀ má ṣe, fún gbogbo Ọ̀dọ́ I.Y.P; pẹ̀lú dídáàbò bo Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè ti Ọwọ́ wọn gbé kalẹ̀ fún Ìran Yorùbá, titi ayé.
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sọ pé gbogbo ọ̀dọ́, àti àgbà pàápàá, tí wọ́n bá ti ṣe àwárí ara wọn, láti mọ irúfẹ́ ẹ̀bùn tí àwọn ní, tí wọ́n sì dàníyàn láti gbé iṣẹ́ kan tàbí òmíràn kálẹ̀, látàrí irúfẹ́ ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀ ní ti ọrọ̀ ajé, ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá wa yí; pẹ̀lú àtìlẹ́hìn Ọlọ́run, nípasẹ̀ ìrọ̀rùn-ló-bá-dé tí ó jẹ́ àmì D.R.Y, kí wọ́n gbà pé àwọn ti di olówó!
Màmá tún wá lahùn fún wa o! Wọ́n ní, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfẹ́ láarín ọkùnrin àti obìnrin kìí ṣe ohun tí ènìyàn lè fi Àlà sí; wọ́n ní, ṣùgbọ́n, ìbá wu àwọn lọ́pọ̀lọpọ̀, kí ó jẹ́ pé kí I.Y.P ó máa fẹ́ I.Y.P, kí wọ́n lè tipa bẹ́ẹ̀ máa bí ọmọ I.Y.P, kó má ṣe sí àdàlú tí ó tún máa wọlé sáarín wa. Wọ́n tún wá tẹ̀ síwájú, pé, àwọn I.Y.P tó ti fẹ́ I.Y.P, kí wọ́n túbọ̀ bímọ si o! kí wọ́n má ṣe tẹ̀lé àwọn òṣì ìmọ̀ràn tí àwọn kan ngbé káàkiri.
Lórí àwọn ọmọ Íbò tí wọ́n npe Èkó, tàbí ibikíbi ní ilẹ̀ D.R.Y, tí wọ́n npè é ní “Western Region,” tí wọ́n dẹ̀ wá nsọ pé àwọn ni wọ́n ni “Western Region,” torí pé àwọn ti ná owó okòòwò síbẹ̀; Màmá sọ pé, àṣà “Western Region” tí wọ́n dá yẹn, Ẹ̀ṣẹ̀ nlá ló jẹ́ fún Ìran Íbò.
Màmá fi yé wọn pé, ORÍLẸ̀-ÈDÈ D.R.Y ni ilẹ̀ Yorùbá, lọ́wọ́ tí a wà yí, àti títí ayé. Wípé wọ́n fi ẹnu wọn sọ ÌSỌKÚSỌ “Western Region” yẹn, lẹ́hìn ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún tí a ti di orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni, ìyẹn jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ gidi fún ìran Íbò. Wọ́n ti ṣẹ Ọmọ Yorùbá. Orílẹ̀-Èdè ni Yorùbá, nísiìyí – orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni.
Màmá wá sọ fún àwọn Ọmọ Íbò, pé ìgbéraga wọn pọ̀. Wọ́n sọ fún wọn pé kí wọn ṣọ́ ara wọn, àti pé wọ́n ti tẹ́ tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n wọn á wá fi ẹ̀tẹ́ tẹ́di gidi báyi. Wọ́n wá sọ fún wọn pé lára wọn ti ya wèrè, pẹ̀lú irú ọ̀rọ̀ rádaràda tí wọ́n nṣọ lẹ́nu yẹn. Wọ́n ní kò sí òwò tí ọmọ Íbò ṣe, tí kìí ṣe pé Yorùbá ló kọ́kọ́ ṣeé.
Wọ́n wá sọ fún gbogbo Ìran Íbò ní ilẹ̀ Yorùbá pé ÀLEJÒ ni wọ́n jẹ́, ìbáà jẹ́ mílíọ́nù ọdún ni wọ́n ti lò ní ilẹ̀ Yorùbá. Wọ́n wá rán wọn létí pé, ní ọgọ́run ọdún ó lé mẹ́ta-lé-lọ́gbọ̀n sẹ́hìn, àkọọ́lè olúgbé-ìlú ní Èkó fi hàn pé kò tilẹ̀ sí ọmọ Íbò kankan ní Èkó nígbà náà rárá.
Wọ́n wá ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Íbò, pé, tí ẹnikẹ́ni nínú wọn bá tún pe Democratic Republic of the Yoruba ní “Western Region,” wọ́n á ríran wò! Màmá sọ fún gbogbo Íbò pé, tí wọn ò bá le tẹ̀lé òfin D.R.Y, wọ́n máa kúrò ní ilẹ̀ Yorùbá ni.
Wọ́n wa pa àṣẹ, báyi, fún gbogbo Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá o, pé, Gbogbo òwò tí àwọn ìran Íbò nṣe ní ilẹ̀ Yorùbá, tí wọ́n wá fi ngbéraga, tí wọ́n fi nsọ̀rọ̀ àlùfànṣá sí ọmọ Yorùbá, Màmá ní kí àwa I.Y.P lọ ṣe ÌWÁDÍ dáadáa nípa àwọn òwò wọ̀nyẹn o; kí gbogbo ọmọ Yorùbá tí ó bá ti ní Ẹ̀bùn láti ṣe irúfẹ́ òwò bẹ́ẹ̀, kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àkojọpọ̀ ètò láti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn òwò wọ̀nyẹn, èyí tí ó túmọ̀ sí pé kò gbọdọ̀ sí òwò kankan ní D.R.Y tí ó jé pé àjèjì ló máa máa ṣé débi tí àjòjì náà á fi máa rí ọmọ Yorùbá fín.
Màmá wá sọ fún Ṣèyí Mákindé pé, inkan kan kò gbọ́dọ̀ ṣe àwọn akọni àti ọmọ D.R.Y tí ó jí gbé ní orí ilẹ̀ D.R.Y o, tí wọ́n dẹ̀ wá tipasẹ̀ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹni-a-mú-lójú-ogun báyi sí ọrùn Mákindé, nítorí ilẹ̀ D.R.Y ni wọ́n wà tí Mákindé ti wá kọ lù wọ́n.
Nípa èyí, Mákindé ni ó wá ṣe àkọlù lórí ilẹ̀ D.R.Y o, èyí tí ó já sí pé Mákindé gbé ogun ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.
Bákan náà ni wọ́n sọ fún gbogbo àwọn gómìnà nàìjíríà ọ́ún, tí wọ́n ṣì npera wọn ní gómìnà ní D.R.Y, pé kí wọ́n mọ̀ o – pé, àwọn gòmìnà-adelé D.R.Y ti wà nípò ní D.R.Y, ati ọkùnrin àti obìnrin wọn.
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sọ fún Ṣèyí Mákindé pé, D.R.Y ò gba agbẹjọ́rò kankan o, lórí ọ̀rọ̀ àwọn akọni D.R.Y tí Mákindé jí gbé; bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ pé òun ni agbẹjọ́rò àwọn tí Mákindé jí gbé yí, irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ fẹ́ kó bá ara ẹ̀ ni, nítorí ọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè ni eléyí jẹ́; D.R.Y ò dẹ̀ lè rò ẹjọ́ níwájú ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ adájọ́ Nàìjíríà. Adájọ́-kádájọ́, tàbí agbẹjọ́rò tàbí ọlọ́pa Nàìjíríà tí wọ́n bá ndíbọ́n irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀ ti rọ́ràn.
Ìránṣẹ́ Olódùmarè MOA wá sọ fún àwọn àgbẹ̀ tí wọ́n kọ̀ láti sọ, nísiìyí, nípa bí àwọn Fulani ti ṣe aburú sí oko tàbí agbègbè wọn, pé kí wọ́n má ṣe wá bá ìjọba adelé nígbà tí ìjọba bá ti wọlé sí oríkò ilé-iṣẹ́ ìjọba tán, lórí ọ̀rọ̀ náa o, nítorí àkóbá ló máa jẹ́ fún ẹni bẹ́ẹ̀ nígbà yẹn – àkókò tí ẹ ní báyi láti wá fẹjọ́ sùn, ẹ ò wá; a dẹ̀ mọ bó ṣe nlọ!
Wọ́n tún rán àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá létí, pé, àwọn máa nsọ pé a ò níí jagun, ogun ò sì níí jà wá, ṢÙGBỌ́N a máa dáàbò bo ìṣèjọba-ara-ẹni wa, àti pé àwọn ọ̀dọ́ wa ni ìdáàbòbò yí jẹ́ àìgbọdọ̀-má-ṣe fún wọn o. Fún ìdí kan náa, gẹ́gẹ́bí wọ́n ṣe sọ, ni a níláti ríi pé a dáàbò bò Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé fún Ìran Yorùbá – Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.
Wọ́n wá ṣe àlàyé fún wa, gidi, pé kí á má ṣe rò pé jíjẹgàba tí àwọn gómìnà agbésùnmọ̀mí nàìjíríà njè gàba lórí ilẹ̀ wa, túmọ̀ sí pé ìjọba wa kòì tíì bẹ̀rẹ̀, àbí pé bóyá orílẹ̀-èdè wa kòì tíì dúró; Rárá o! Méjèèjì ò papọ̀ rárá! Orílẹ̀-Èdè wa ti dúró, kò sẹ́ni tí ó lè yí yẹn padà mọ́; bẹ́ẹ̀ náà ni ìjọba wa ti bẹ̀rẹ̀: kò sí àní-àní nínú gbogbo ìyẹn. Wípé àwọn kan njẹgàba lórí ilẹ̀ wa – ọ̀tọ̀ nìyẹn, tí Olódùmarè dẹ̀ máa bá wa ṣẹ́gun àwọn yẹn.
Wọ́n wá fi yé wa pé gbígbà tí Ọlọ́run ti bá wa gba ìjẹ́-Orílẹ̀-Èdè wa padà, tí Ó sì tún ti bá wa gba ìṣèjọba-ara-ẹni wa padà, ni ó fi jẹ́ pé, gbogbo èyí tí ó nṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà – gẹ́gẹ́bí gbígbà tí Nàìjíríà gbà kí wọ́n máa mú ẹ̀yà-ara àwọn ọmọ Nàìjíríà láì sí àṣẹ láti ọwọ́ ẹni tó ni ẹ̀ya-ara, kò kan ọmọ D.R.Y rárá! Àra ìgbàlà tí Ọlọ́run ṣe fún wa nìyí.
Ká Ìròyìn Síwájú: OLÓRÍ ÌJỌBA ADELÉ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ, BÀBÁ WA, MỌBỌ́LÁJÍ ỌLÁWÁLÉ AKINỌLÁ ỌMỌ́KỌRẸ́, BÁ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ SỌ̀RỌ̀ NÍ ÀYÁJỌ́ ỌJỌ́ Ọ̀DỌ́
Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá wá sọ pé, Ìdí nìyí, tí ó fi pọn dan-dan kí àwọn ọ̀dọ́ wa, ọ̀dọ́ I.Y.P ó ríi dájú pé àwọn dáàbò bo òmìnira wa yí, nípa fí fi ohun tó bá máa gbà fun, láti dáàbò bo ipò ìṣèjọba-ara-ẹni èyí tí Olódùmarè ti jogún ẹ̀ fún wa yí.
Wọ́n wá tẹ̀ẹ́ mọ́ wa létí pé, ẹlẹ́ẹ̀kẹ́ta nìyí o, tí Olódùmarè máa ran Ìran Yorùbá lọ́wọ́ láti gbé ìpìlẹ̀ rere kalẹ̀ fún orílẹ̀-èdè àti ìran Yorùbá.
Ìgbà àkọ́kọ́, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe sọ, ni àkókò àwọn babanlá wa, èyí tí àwọn òyìnbó amúnisìn fúnra wọn jẹ́ri pé kò sí olè tàbí alágbe kankan ní ilẹ̀ Áfríkà, tí a sì mọ̀ pé ilẹ̀ Yorùbá gan-an ni kókó ọ̀rọ̀ náà. Macaulay ni òyìnbó amúnisìn tí ó sọ̀rọ̀ náà nígbà yẹn.
Ṣùgbọ́n àwọn babanlá wa ṣubú, tí ìpìlẹ̀ náà sì ṣùbú títorí àwọn bàbạ́ wa bẹ̀rẹ̀ sí ta Ìran Yorùbá sí oko ẹrú nígbà náa lọ́hun!
Ànfààní Ìpìlẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì ni ìgbà àwọn Baba wa Awólọ́wọ̀, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ pé ìpìlẹ̀ tìyẹn náà tún wó lulẹ̀ nígbàtí Bàbá wa Awólọ́wọ̀ finú-wénú!
Màmá wá fi yé wa pé ìpìlẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹ́ta ni èyí – tí Ọlọ́run nínú àánú Rẹ̀, bá wa gba ìjẹ́-Orílẹ̀-Èdè wa padà, àti ìṣejọba-ara-ẹni wa; wọ́n wá sọ pé, èyí dẹ̀ ni ànfààní-ìpìlẹ̀ tí ó kẹ́hìn o!
A ò gbọdọ̀ ṣàì ṣeé rere, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ó tún ṣubú – àti pé ọwọ́ àwọn Ọ̀dọ́ wa ló wà, lati ríi pé wọ́n dáàbò bo ìṣèjọba-ara-ẹni D.R.Y, kí wọ́n sì dáàbò bo Àlàkalẹ̀ D.R.Y
Màmá wá kìlọ̀, kí a máṣe gba ẹnikẹ́ni láàyè láti ṣe wá ní ọṣẹ́ kankan, bí àpẹrẹ, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gba ohun tí ó bá jẹ́ GMO. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàá, ẹ̀sùn apànìyàn ni ẹni náà máa dojú kọ.
Wọ́n tún sọ fún gbogbo ọ̀dọ́ àti ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ ṣe òṣèlú, kí wọ́n lọ tún ìwà wọn ṣe.
Ohun tí a níláti ṣe láti ri pé gbogbo nkan lọ ní rere títí ayé, ni pé kí àwọn ọ̀dọ́ wa ri dájú láti ìsiìyí lọ, pé wọ́n dáàbò bo ìṣèjọba-ara-ẹni D.R.Y, kí wọ́n má gba ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni láàyè láti kó wa sínú ìparun.
MOA tẹnu mọ pé, wọ́n fẹ́ pa ìran Yorùbá run ni o, àtòyìnbó àti Ìbò àti Fulani àti alábọ̀dè tí ó pera wọn ní Yorùbá, àtawọn tó nṣe mímú ẹ̀yà-ara èèyàn láì ní àṣẹ ẹni náà, àti gbogbo arékérekè àwọn tí Bill Gates nṣiṣẹ́ fún, wọ́n fẹ́ kó ọmọ Yorùbá kúrò nlẹ̀ ni.
Ọ̀dọ́ Yorúbá, ìjẹ́-Orílẹ̀-Èdè wa tí Olódùmarè ti bá wa gbà padà yí, tí a ò sí lábẹ́ ẹnikẹ́ni mọ́, àtí ìṣèjọba-ara-ẹni tí Ọlọ́run ti bá wa gbà yí, ẹ má ṣe jẹ́ kí ó já bọ́ lọ́wọ́ wa; ẹ̀yin Ọ̀dọ́ Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, ẹ jà láti dáàbò bo ìṣèjọba-ara-ẹni wa yí, kí ẹ sì dáàbò bo Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé fún Ìran Yorùbá; ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, àti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y); èyí jẹ́ oun tí Màmá tẹnu mọ́ gidi.
MOA wá sọ pé, Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ti parun – wọ́n pera wọn lọ́ba ni, wọ́n pera wọn lólóṣèlú Nàìjíríà ni, wọ́n pera wọn lóyìnbó amúnisìn tó nwá ikú àti ìpalára fún ọmọ Yorùbá ní, wọ́n pera wọn ní Íbò tàbí Fúlàní ni, wọ́n pera wọn ní jàndùkú ẹrú-ikú àwọn olóṣèlú nàìjíríà ni – wọn ò rọ́nà gbe gbà láí láí, wọn ò rí bátiṣé láí láí, ojú ti tì wọ́n.