Òkú ọ̀rọ̀ tí ìròyìn kan gbé jáde ní orí ẹ̀rọ ayélujára , nípa ọkùnrin Yorùbá kan tí wọ́n ní ó bẹ̀rẹ̀ sí ní mú orí àwọn ìran Ìgbò wú lòdì, nígbà tí ó ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ kan wípé, àwọn Ìgbò ni wọ́n kó ipa tí ó pọ̀ jùlọ nínú ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé gbogbo àgbáyé.
Ọkùnrin náà sọ ìdí tí àwọn ẹbí kan ní Amẹ́ríkà báyìí, fi dárapọ̀ mọ́ àti bá àwọn ìran Ìgbò ṣe àṣepọ̀.
Ó tún sọ síwájú síi wípé, ìbá ti dùn tó, tí Orílẹ̀-èdè akótilétà Nàìjíríà bá lè lo àǹfààní wíwà tí àwọn ìran Ìgbò wà láàrin wọ́n kí wọ́n fí ṣe àyípadà sí rere, kí ìlọsíwájú sì leè wà.
A rí ìròyìn yí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ, ní òtítọ́, àwa Indigenous Yorùbá People, (I.Y.P.), tí jáde kúrò nínú ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà láti ogúnjọ oṣù Bélú, Ẹgbàá ọdún ó-lé-méjì-lélógún, tí a tún tí bẹ̀rẹ̀ ìṣe’jọba ara ẹni tiwa, nígbà tí a ṣe ìbúra tán fún Olórí Adelé wa, bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, ní ọjọ́ Kejìlá Oṣù Igbe, Ẹgbàá ọdún ó-lé-mẹ́rin-lé lógún, síwájú àkókò yìí ,kò yé wa ipa tí ọkùnrin yí wá ń sọ pé wọ́n kò o? ṣé ti àparútu wọn ni, àbí ti ìjínigbé pa’wó tí wọ́n jingíri nínú rẹ̀ ni wọ́n fi ń kó ipa nínú ìdàgbàsókè ni?
Àwa ọmọ Orílẹ̀ èdè Olómìnira Yorùbá Tiwantiwa, (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y.) ẹ jẹ́ kí a máa dúpẹ́ fún Olódùmarè tí ó fi màmá wa, Modúpẹ́ọlá Onítirí-Abíọ́lá, ṣe alágbàkalẹ̀ wa, kúrò láàrin àwọn agbésùnmọ̀mí, tí wọ́n mú wa padà sí orí ilẹ̀ àwọn bàbá wa.
Ọkùnrin tí ó sọ ọ̀rọ̀ tí a gbọ́ lórí fọ́nrán náà, sọ ọ̀rọ̀ aláìlọ́pọlọ; nítorí ó hàn gbangba pé kò ní ìrònú tó jinlẹ̀; tó bá ní ìrònú tó jinlẹ̀ ni, ó yẹ kí ọpọlọ rẹ̀ lè sọ fun pé, gbogbo ohun tí ó ń sọ pé àwọn ìgbò nṣe ní ilẹ̀ Yorùbá, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣeé? Báwo ni wọ́n ṣe dé bẹ̀? Ìwà kí wọ́n máa jẹ gàba lórí ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá, òun ni wọ́n fi ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe! Ṣùgbọ́n, ó ti tán fún’wọn báyi o!
Ìran Ìgbò ti tẹ́ pátápátá ní ilẹ̀ Yorùbá; ìwọ tí o pe ara ẹ ní ọmọ Yorùbá, tí o sọ ọ̀rọ̀ aláìl’ọpọlọ yẹn, a rí ojú rẹ o, a mọ̀ ẹ́.
Kí gbogbo ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ó fi ọkàn wa balẹ̀; lágbára Olódùmarè, a ti dé ibi t’a nlọ ná, inú oríkò-ilé-iṣẹ́ ìjọba wa káàkiri Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùba (D.R.Y) pẹ̀lú ìfọkànbalẹ̀, tí àwọn Ìjọba-Adelé wa máa tẹ̀ síwájú, lójú gbogbo wa, nínú iṣẹ́ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ní oṣù mẹ́rin-ààbọ̀ ó lé báyi; nígbà náà ni irọ́ kàbìtì tí àwọn ènìyàn rádaràda wọ̀nyí ń pa máa hàn sí ìgboro-ayé, tí ojú máa tì wọ́n pátápátá.