Nínú fọ́nrán kan tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni a ti rí arákùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Phillips níbi tó ti ń ṣe àlàyé fún Ààrẹ àná ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà bí àwọn orílẹ̀ èdè China ṣe jẹ́ àgbátẹrù rí ra àwọn ilẹ̀ tó ṣe gbòógì fún ètò ọ̀gbìn yíkáàkiri àwọn ibùdó ọmọ ológun tí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.
Ìbànújẹ́ d’orí àgbà kodò ni ó jẹ́ fún Ààrẹ àná ọ̀hún nígbà tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà.
A mú eléyìí wá sí etíìgbọ́ wa láti leè jẹ́ kí a mọ pàtàkì dídáàbò bo ilẹ̀ wa ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), nítorí àwọn alárìnkiri tí wọ́n ń wá ibi tó tutù láti ba sí yí.
Ní kété tí àwọn adelé wa bá ti wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìjọba ní àwọn ìpínlẹ̀ wa méjèèje láti tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún, gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ni wọn yóò bójútó gidigidi.
Gẹ́gẹ́ bí Olódùmarè ṣe kẹ́ àwa ìran Yorùbá pẹ̀lú oríṣiríṣi àlùmọ́ọ́nì, ti inú ilẹ̀ àti ti inú omi, a gbúdọ̀ rí àwọn nǹkan wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè, kí a má sì ṣe gba àbọ̀dè fún ìran wa.
Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ìrírí tí a ti rí pàápàá pẹ̀lú ìlú agbésùnmọ̀mí tí a ti kúrò, ẹ jẹ́ kí ó kọ́ wa lọ́gbọ́n gidigidi, kí a ṣọ́ra fún àlejò gbígbà nítorí pé, àlejò tí a fi ọwọ́ kan gbà wọlé,ọwọ́ mẹ́wàá kò ní leè lée jáde mọ́.
Ẹ má jẹ̀ẹ́ kí ojú àánú wa kò tún kò bá wa lẹ́ẹ̀kejì, tí kìí bá ṣe Olódùmarè tó ṣàánú fún wa nípasẹ̀ màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla tó rán sí wa láti gba ògo wa padà, níbo ni àwa ìran Yorùbá ìbá wà lónìí? Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a ṣọ́ra.