Àwọn ará-ìlú Burkina Faso ti kó owó jọ o! Wọ́n ni àwọn ò gbára lé ìlé-ìfowó-pamọ́ àgbáyé, àwọn ò sì níí yáwó lọ́wọ́ Àjọ-Ayánilówó Agbáyé!
Ibrahim Traore, olórí ìlú Burkina Faso fún’ra rẹ̀ ni a gbọ́ pé ó ti sọ eléyi tẹ́lẹ̀ nígbà tí ó dé orí aléfà ìlú náà. Bẹ́ẹ̀ ni ó wá gbé ètò ìkówójọ ti ìjọba Burkina Faso kalẹ̀, látàrí èyí tí ìròyìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ lórí YouTube sọ pé, nṣe ni àwọn ará-ìlú Burkina Faso dìde tara-tara láti ra àdéhùn ìjọba wọn náà (government bond), tí ìròyìn sì sọ fún wa pé wọ́n tilẹ̀ kọjá iye owó tí Akọgun Traore tilẹ̀ ní l’ọkàn tẹ́lẹ̀! Ìróyìn náà sọ pé, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi, àwọn ará-ìlú Burkina Faso ti kó owó jọ o! Okòó-lé-ní’gba mílíọ̀nù dọ́là ni wọ́n kójọ, tí ó ti wà nílẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi, kí àwọn iṣẹ́ ìdàgbà-sókè, lóriṣiríṣi, tí Ibrahim Traore ti làkalẹ̀, kí ó máa tẹ̀síwájú, kí ó sì di ṣíṣe!
Lóbátán! Ìròyìn náà sọ pé èyí ti fihàn gbangba pé irọ́ gbáà ni àwọn akọ̀ròyìn aláwọ̀-funfun npa, tí wọ́n sọ pé àwọn ará-ìlú Burkina Faso kò faramọ́ ìjọba wọn: ṣé èèyàn a máa ṣe ìkówó-jọ okòó-lé-nígba dọ́là fún nkan tí kò fárámọ́ bí? L’àṣírí àwọn òpùrọ́ akọ̀ròyìn àwọn aláwọ̀-funfun náà bá tú.
Ìròyìn tí a gbọ́ náà wá sọ pé èyí jẹ́ ìpèníjà fún orílẹ̀-èdè káàkiri ilẹ̀ adúláwọ̀ pé ìlú kan mà ni’yíì, tí wọ́n ní àwọn ò yáwó lọ́wọ́ òyìnbó amúnisìn, ohun tí ó bá máa gbà ni àwọn máa fùn, àwọn ò fẹ́ gbèsè!
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè, pé, láti ìbẹ̀rẹ̀-pẹ̀pẹ̀ ni Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Ònítirí-Abíọ́lá, ti jẹ́ kí ó yé wa pé yíyá owó pẹ̀lú ọ̀nà tí àwọn amúnisìn fi máa nkó àwọn orílẹ̀-èdè s’oko ẹrú; a sì ti mọ̀ pé Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) kò ní lọ sí oko gbèsè, gẹ́gẹ́bí Màmá wa ṣe sọ, àti pé bí okòòwò ni a ṣe máa ṣe iṣẹ́ orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n á wá jẹ́ okòòwò èyí tí kìí lọ s’oko gbèsè! Wọ́n ti fi yé wa pé, a máa fún’ra wa ṣe àwọn nkan tí a bá nílò; inkan tí a bá ṣe yẹn náà sì ni a máa lò!
Njẹ́ ẹnikọ̀ọ̀kan wa ti ngbára-dì ohun tí a fẹ́ ṣe? Ẹ jẹ́ kí á rántí pé owó kọ́ ni ìṣòro o! Orílẹ̀-Èdè D.R.Y ní ètò ìpèsè-owó tí kò ni’ra l’ati san padà – fún àwọn tó bá nílò rẹ̀.
A kí àwọn ará-ìlú Burkina Faso o, kí ara ó tù wọ́n láti ṣe àṣeyọrí ìdáwọ́lé wọn náà.