ỌLỌ́RUN OLÓDÙMARÈ, ÀWÁMÁRIDÍ, NÍSIÌYÍ, BA GBOGBO OHUN-IBI JẸ́, PÁTÁPÁTÁ; GBOGBO MÁJẸ̀MÚ ÌRÁNṢẸ́-ẸNI-IBI, ÀṢÌTÁÁNÌ, GBOGBO ÌLÉRÍ, ÈTÒ, ÈTE, ÀTI ÈRÒ TÍ Ó LÒDÌ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ. NÍ AGBÁRA TÍ ỌLỌ́RUN FI NJẸ́ ÈMI-NI, KÍ ÌPARUN NÁÀ ṢẸLẸ̀ SÍ ÀWỌN Ọ̀TÁ YORÙBÁ WỌ̀NYÍ, LỌ́WỌ́LỌ́WỌ́ BÁYI

OLÓDÙMARÈ, ALÁGBÁRA, TÍ Ó NÍ IPÁ; OLÓDÙMARÈ TÍ Ó NÍ IPÁ LÓJÚ OGUN, ỌLỌ́RUN ÀWỌN ỌMỌ-OGUN, ṢE ÌPARUN PÁTÁPÁTÁ, NÍSIÌYÍ, FÚN ÀṢẸ, AGBÁRA ÀTI IPÒ TÍ WỌ́N NLÒ LÁTI JẸGÀBA LÓRÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ.

ṢE ÌPARUN FÚN GBOGBO ÌWÀ ÌDÚKOKÒ, ÌJẸGÀBA, DÍDẸ́RÙBANI, ÌHÀLẸ̀, ÌGBÓGUN-TINI, TÍ WỌ́N DOJÚKỌ ỌMỌ-ÌBÍLẸ̀-YORÙBÁ, TI ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tó kó wa yọ lọ́wọ́ ìnilára àti ìfì’yàjẹni àwọn olóṣèlú ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, ṣé tí ìnira bá ti pọ̀jù kò sí ohun tí ènìyàn kò leè ṣe, èyí ló ṣe okùnfà ìṣẹ̀lẹ̀ búburú kan tí a rí lórí ẹ̀rọ ayélujára níbi tí ọkùnrin kan tí fẹ́ gba èmi ara rẹ̀ lórí afárá kan ní agbègbè Àjáh ní Ìpínlẹ̀ Èkó èyí tí ó jẹ́ ọ̀kan lára ìpínlẹ̀ wa ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y).

Ṣé tí àwọn olójú kòkòrò, olè àti akótilétà olóṣèlú ìlú ajẹgàba Nàìjíríà ti wọn fipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa bá ti kúrò láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún tí a ti bẹ̀rẹ̀ ìsèjọba ara ẹni pẹ̀lú ìbúra wọlé fún olórí adelé wá bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ, gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè D.R.Y ìbá ti máa gbádùn láti ìgbà náà nítorí pé àlàkalẹ̀ ètò ìsèjọba tí Olódùmarè gbé lé màmá wá lọ́wọ́ ìyà ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, ìyá Òmìnira Yorùbá, àlàkalẹ̀ tí yóò gbọn ìyà nù lára ọmọ Yorùbá ni ti kò sì ní sí òtòṣì láàárín ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá mọ́.

Ìlú ajẹgàba Nàìjíríà, ẹ kúrò lórí ilẹ̀ D.R.Y, orílẹ̀ èdè aṣèjọba ara ẹni ni wá, a kìí se ara yín mọ́, ẹ fún àwọn ọ̀dọ́ wa láàyè láti lo ìgbà tiwọn.