Ìròhìn gbígbóná fẹlífẹ́lí kan lu jáde pé láti bíi oṣù díẹ̀ sẹ́hìn tí àwọn orílẹ̀-èdè Niger, Mali ati Burkina Faso ti lé àwọn ọmọ ogun Faransé jáde kúrò l’órílẹ̀-èdè wọ́n ni wọ́n ti ńwá ibi tí wón má fìdí ibùdó àwọn ọmọ ogun wọn kalẹ̀ sí ní Áfríkà. Kò sí ẹnití ó gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ náà mọ́.
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on XLójijì ni ọjọ́ kọkànlá, oṣù Agẹmọ ẹgbẹ̀wáọdúnólémẹ́rìnlélògùn ni Ibrahim Traore tí ó jẹ́ olórí orílẹ̀-èdè Burkina Faso jáde láti pariwo sí àgbáyé pé orílẹ́ èdè Faransé ti dá ibùdó ológun méjì sílẹ̀ ní órílẹ̀-èdè Benin, ẹ̀rí rẹ ni pé òun ni ọkọ òfúrufú aṣatọ́na àṣírí méjì tí ńfojúsí ohun gbogbo tó ń ṣẹlẹ̀ ní ìwọ̀ oòrùn Áfríkà àti gbogbo Áfríkà èyí sì jẹ otitọ. Ìròyìn náà sí ti ńfa ìpòrurù nítorí ó jẹ́ ìyànú ní etí.
Olórí orílẹ̀-èdè Burkina Faso Ibrahim Traore náà kọ́kọ́ fìdí ọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀ pé ní Ivory Coast wọ́n ńṣètò láti dààmú ìlú òun sùgbọ́n àwọn kan kò gbàgbọ́, ó wá tú àsírí míràn pé orílẹ̀-èdè Benin ti gbàbọ̀dè ibùdó àwọn ológun àwọn Faransé méjì ní ìlú Kambi ati ní òpópónà tó ńlọ sí Porga, ó wípé ẹrí tó dájú wà nílẹ̀.
Ó tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé wọ́n ti ṣe ọ̀nà wọnú tó gùn ní ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún mẹ́ta mítà tí ọkọ̀ òfurufú lè balẹ̀ ṣi, wọ́n sì ńkó àwọn ǹkan ìjà ogun fún àwọn ènìyàn, wọ́n sì ńṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ogun fún àwọn ènìyàn níbẹ̀ àti pé àwọ ní ìgbohùn sílè awon ará Faransé tó ńṣiṣẹ́ níbẹ̀ bi adarí ati olùtọ́jú àwọn tí wọ́n ńkọ́ níbẹ̀ tí ó’ wà lọ́wọ́ àwọn.
Ibrahim Traore tẹsiwaju láti sọ fún àwọn ọmọ ìlú Ivory Coast àti Benin pe ilu òun kò bínú wọn o ṣùgbọ̀n ètò ìṣèjọba tí orílẹ-èdè méjèjì yen ńlò yíò ṣe àkóbá fún àwọn ará ìlú nítorí ó tí ṣẹlẹ̀ sí Burkina Faso rí nigbati wọ́n gbà lati jẹ́ ibùdó àwọn aláwọ̀ funfun láti da orílẹ-èdè míràn láàmú, àwọn ńdojúkọ ìjìyà rẹ̀ bayi. Ó wipe ki ara ìlú bá àwọn olórí wọn sọ̀rọ̀ ki wọ́n dẹ́kun ìwà búburú yi.
Ni bayi àwọn ọgá ológun ni Benin ti jáde láti sọ wipe ìjọba ìlú wọn kò ṣe ohun tí Traore sọ rárá, àti pé àwọn ọmọ ogun àwọn ló wà ní ibití ó ún nsọ nípa rẹ̀.
Ṣugbọn ṣé Bẹnin ní ọmọ ogun tí o pọ̀ tó láti kó àwọn kan sínú aṣálẹ̀? Àwọn ìlú tí ó tóbi jù wọ́n tí o sì ní ọmọ ogun púpọ ní Afrika kò tíì ṣe bẹ́ẹ̀, báwo ni Benin yíò ṣe wá kọ́ ibùdó ológun odindi meji sínú aṣálẹ?
Àwọn tí á ńpè ní aláwọ̀ funfun yí kò fẹ́ yọ ọwọ́ ninu ìṣèjọba Áfríkà nítorí ọrọ̀ wà tí wọ́n ńkó, ṣugbọn àwa Indigenous Yorùbá People mọ̀ pé ti wa yàtọ̀ nítorí ayé kó ní sí fún àjèjì níbikíbi láti tọwọ bo orílẹ-èdè D.R.Y. lójú, nitori ọmọ Yorùbá ló ní ilẹ̀ Yorùbá, àjèjì kankan ko ni fí ọwọ́ la’lẹ̀ fún wà lórí ilẹ̀ wa, gẹ́gẹ́bí màmá wa Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla ṣe máa ń sọ pé ní ilẹ̀ Yorùbá, lẹ́hìn Ọlọ́run Yorùbá ni àkọ́kọ́. Kí gbogbo àjèjì tó ń pa ọmọ Yorùbá lára lórí ilẹ̀ Yorùbá tètè palẹ̀ ẹrù wọn mọ́ kí wọ́n kọjá sí orílẹ̀-èdè wọn nítorí ni kété tí adelé wa bá ti wọ sẹkitéríátì kò ní sí àyé ìpalára fún wa mọ́. Orí ètò ìṣèjọba tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀ tí kò nì ṣe dàrú ní àwa gbé orilẹ̀-èdè wa lé.
Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Adelé wa ṣe pàtàkì ni àkókò yí láti ṣi ìdí Naijiria tó ńjẹ gàba kúrò lórí àwọn ohun ìní wa, nitori, ìwà olè àti ọ̀dájú nì wọn kò ṣe fẹ́ ki a lọ pẹlú ìrọ̀rùn. Ṣugbọn, ó dájú pé àwa ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá kò lè padà sí ara Naijiria mọ́ láíláí, nítorí:
Abẹ́rẹ́ wa ti lọ kí ọ̀nà okùn tó di.