Ṣé wọ́n ní ajá tó máa sọnù, kò ní gbọ́ fèrè ọdẹ – òun ni ọ̀rọ̀ Tinubú, ààrẹ wọn ní ìlú tó fẹ̀gbẹ́ tì wá, nàìjíríà, tí wọ́n nfi ipá dúró lórí ilẹ̀ wa báyi, tí ó yí orúkọ Gbọ̀ngàn Ìtàgé ní Surulere, ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, sí Gbọ̀ngàn Àṣà àti Ìṣọwọ́dárà Wọlé Ṣóyínka, láti fi yẹ́ Ṣóyínká sí ní àyájọ́ ọjọ́ ìbí rẹ̀ tí ó pé àádọ́run ọdún ní ọjọ́ kẹ́tàlá oṣù kéje ọdún yí.
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on XA nsọọ́, a tún ntusọ, wípé ìkọjá àyè ni ó jẹ́, kí ìlú nàìjíríà ó máa pàṣẹ lórí ilẹ̀ Yorùbá, tí ó jẹ́ orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni tirẹ̀. Ohun tí Tinubú nfẹ́, ẹ̀tẹ́ tí ó máa dé ba, ó nbọ̀ láìpẹ́.
Ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá kan tún wá ṣe àkíyèsí nípa bí Wọlé Ṣóyínká àti Ọbásanjọ́ ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́, bí wọ́n tilẹ̀ máa nṣe bí ọ̀tá ní gbangba – irọ́ ni o!
Tí a bá mọ ìtàn kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìtàgé ti Surùlérè yí, bí ó ti jẹ́ Gowon ni ó bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n Ọbásanjọ́, ọ̀rẹ́ Ṣóyínká, ni ó parí rẹ̀ ní ọdún 1976. Báyi, wọ́n wá fi orúkọ Wọlé Ṣóyínká si; bẹ́ẹ̀ a mọ̀ wípé Ọbásanjọ́ burú dé ‘bi wípé, á fẹ́ kí ó jẹ́ orúkọ òun ni ó máa wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n orúkọ ọ̀rẹ́ rẹ̀, Ṣóyínka, tẹ́ẹ lọ́rùn kí ó wà ní’bẹ̀ – gbogbo wọn njọ ṣiṣẹ́ papọ̀ ni!
Ká Ìròyìn Síwájú sí:
- Ìyà Tí Ó Njẹ Náìjíríà Kò Ṣ’ẹ̀yìn Àwọn Òyìnbó
- Nigeria Nwá Oríṣiríṣi Ọ̀nà Láti Fa Ọmọ Yorùbá Mọ́ra!
- Bí Àwọn Fúlàní Agbébọn Ṣe Gba Ìlú Ọ̀yọ́ Ilé
- Àṣírí Tú O !!! Àwọn Olórí Ìjọba Àtí Agbaàgbà Ilẹ̀ Áfríkà Ni Ìkà, Olè Àti Akótilétà
- Ó Gbẹnu Tán: Ẹ Wá Wo Bí Wọ́n Ṣe Ń Kó Gbogbo Agbára Sí Ọdọ Ara Wọn Ní Orílè-Èdè Nàìjíríà
Àwọn gbogbo ìgbésẹ̀ wọ̀nyí sì jẹ́ ìtọnà tí Babangida nfún wọn ní ẹnu ijọ́ mẹ́ta yí, ṣùgbọ́n wọ́n ti kùnà o! Yorùbá ti lọ!